WUNREN "TI" LEDE YORUBA

 TI == Iwe ti Ojo


 Láti ìbẹ̀rè pẹ̀pẹ̀ ni àwon onímò èdè ti gba ti  inú ‘ìwé ti Òjó’ sí ‘possessive marker’ àfi ìgbà tí ọ̀jọ̀gbọ́n kan wò ó dáadáa tí ó sọ pé OR ni. Ó ní nínú ‘iwé ti Òjó’, ‘ti’ jẹ OR nínú APOR, ‘ti Òjó’ àti pé APOR, ‘ti Òjó’, dúró ní àdàpè (apposition) fún ‘ìwé’.  Èyí fi han pé nínú ‘ìwé ti Òjó’, ‘ìwé’ ń  yán ‘ti’. A wá ní OR méta nínú ‘ìwé ti Òjó’. Ìbásepọ̀ ‘ìwé’àti ‘ti Òjó’ wá dàbí ìbáṣepọ̀ tí ó wà láàrin ‘Òjó’ àti ‘àdẹ́mu’ nínú ‘Òjó adẹ́mu ń bò’. Ọ̀jọ̀gbọ́n kejì ni ọ̀rọ̀ kò ri báyìí. Ó ní iṣẹ́ jẹ́nítíìfù (tàbí possessive) ni ‘ti’ ń se nínú ‘ìwé ti Òjó’. Ó ní tí a bá sọ pé ‘tèmi’, nǹkan tí a ní lọ́kàn ni ‘nǹkan kan tèmi’.  Lójú ọ̀jọ̀gbọ́n kẹ́ta, òrò kò rí bí ọ̀jọ̀gbọ́n kejì ti là á sílẹ̀ yẹn. Lójú tirẹ̀, a lè fi ‘ti’ wé ‘oní’ nínú ‘ti aró/ti aṣọ’ àti ‘aláró/aláṣọ’, iṣé kan náà ni wón ń ṣe. ‘Ti aró’ ń tọ́ka sí ohun kan tí a mọ aró mọ́. Ohun yòówù tó lè jẹ, kìí ṣe aró fúnra rẹ̀. Aró wá dàbí ọlọ́kọ̀ọ́ ohun tí a ní lọ́kàn. Ní ti ‘aláró’,  ohun tí a mọ̀ mọ aró ni a ní lọ́kàn. Ohun tí a ní lọ́kàn yìí sì ni ọlọ́kọ̀ọ́ aró. Lọ́rọ̀ kan, gbogbo APOR (ti + OR) jẹ́ òdì APOR (oní + OR). Ó ní a ó rí i pé kò sí ohun tí a lè ṣe sí ikíní tí a kò lè se sí èkejì. (i) Wón lè se olùwà GBOL, ba: Onílé kò lè gbé e lọ sí ọ̀run/Tilé kò lè gbé e lọ sí ọ̀run. (ii) Wọ́n lè ṣe àbọ̀ GBOL, ba: Mo ránṣẹ́ só onílé/Mo ránṣẹ́ sí tilé (iii) A lè yán wọn, ba: onílé gogoro/tilé gogoro (iv) a lè ṣèdá òrò mìíràn lára wọn, ba: olónigbaojúlé/onítilé. (v) a lè fi wón yán ọ̀rọ̀ mìíràn ba: owó onílé/owó tilé. Lójú ọ̀jọ̀gbọ́n kẹta yìí, ìgbà tí a bá lo ‘ti + OR’ ní àkànlò ni ó máa ń dàbí ẹ̀yánrọ̀ lásán. Èyí ni ọ̀jọ̀gbọ́n kejì pè ní ‘marked genitive construction’ (owó ti onílé) tí ó fa àtenumọ́ lọ́wọ́ yàtọ̀ sí ‘unmarked genitive construction’ (owo onílé). Ìdí nì yí tí ọ̀jọ̀gbọ́n kejì fi lè túmọ́ ‘owó tilé’ sí ‘owó kan tí a mọ̀ mọ́ ilé’. Ọ̀jọ̀gbọ́n kẹ́ta túmọ̀ ‘owó tilé’ sí ‘owó tí a mọ̀ mọ́ ohun kan tí a mọ ilé mọ́’ Ojú yòówù kí a fi wò ó, lójú ọ̀jọ̀gbọ́n kẹ́ta, ìsọ̀rí gírámà tí a bá to ‘oní’ sí ló ye kí á to ‘ti’ sí. Níwòn ìgbà tí ‘oní’ ti jé mọ́fíímù àfòmọ́ tí a lè lò láti ṣèdá OR láti ara OR, ‘ti’ náà ní láti jẹ́ àfòmọ́ tí a fi ń ṣèdá OR láti ara OR.

Comments

Popular posts from this blog

YORÙBÁ LITERATURE E-LIBRARY

SYNTAX AND GRAMMATICAL THEORIES E-LIBRARY SECTION

YORÙBÁ GRAMMAR E-LIBRARY SECTION