OYELARAN(1982) Ìsọ̀rí Gírámà

 

Ìsọ̀rí Gírámà

O.O. Oyelaran[1]

Credit: Prof L. O. Adewole
Yoruba for academic purpose


I. Kí a tó lè mọ ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ nínú èdè, ó yẹ kí ènìyàn kọ́ bèèrè àwọn ìlànà tí ó wúlò, tí àwọn tí èdè náà jẹ abínibí fún fi ń mọ ọ̀rọ̀ kan sí èkejì. Ẹ̀yin tí gírámà àtijọ́ kò ṣe àjèjì fún, ẹ ó rántí pé ìtumọ̀ jẹ́ atọ́kùn kan pàtàkì tí wọ́n fi í júwe ọ̀rọ̀. Ìdí nì yí tí wọ́n fi í pe ọ̀rọ̀-orúkọ ní ‘orúkọ ènìyàn, orúkọ ibi kan, tàbí orúkọ nǹkan kan’, tí wọ́n sì ní dandan gbọ̀n ọ̀rọ̀-ìṣe máa ń tọ́ka sí ìṣẹ̀lẹ̀, tí ẹ̀yánrọ̀ sì jẹ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó bá lè ṣe àpèjúwe nǹkan. Ẹ ó tún ṣe àkíyèsí pé àwọn ìwé gírámà àtijọ́ máa ń ṣe bí ẹni pé ìlànà tí a lè tẹ̀ lé nínú èdè kan ni a lè tẹ̀ lé nínú èdè mìíràn láti pín ọ̀rọ̀ sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Bí a bá yẹ èdè Yorùbá wò dáadáa, kò dájú pé ọ̀rọ̀ rí bí wọ́n ti wí yìí.
II. Àwọn ìlànà tí kò wúlò fún àtimọ ìsọ̀rí-ọ̀rọ̀ ní èdè Yorùbá
(1) Ìtumọ̀: Kò dájú pé ìtumọ̀ wúlò tó láti pín ọ̀rọ̀ sí ìsọ̀rí ní èdè Yorùbá. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹni tí ó pe ọ̀rọ̀-orúkọ ní ọ̀rọ̀ tí ó ń dárúkọ ènìyàn, ibi kan, tàbí nǹkan kan, ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ wo ni ẹni náà yóò pín ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí: ọ̀pọ̀, ọ̀wọ́n, ìyà, wàhálà? Bẹ́ẹ̀ sì ni ó ṣòro fún èmi láti fi ìtumọ̀ ya àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sọ́tọ̀: ọ̀pọ̀/pọ̀, ọ̀wọ́n/wọ́n, aré/họ, ọ̀bùn/dọ̀tí.
(2) Ìlànà Fonọ́lọ́jì
Ní èdè Yorùbá, a kò lè fi iye ìró tàbí irú ìró tí ọ̀rọ̀ kan ní ya á sọ́tọ̀ sí òmíràn. Bóyá ẹ ti rí i kà ní ibi kan pé ọ̀rọ̀-ìṣe Yorùbá kìí sábà ní ju ìró méjì lọ. Èyí kò rí bẹ́ẹ̀. Bí a ti rí ọ̀rọ̀ bíi wá, ṣe, gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ bí àwọn wọ̀nyí náà wà: gẹlẹtẹ, gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀, kẹ̀rẹ̀, wàhálà, gàrí, wo-n-koko. Lóòótọ́ ni sá pé ọ̀rò-ìṣe Yorùbá kìí ní fáwẹ̀lì bí àkọ́kọ́. Ṣùgbọ́n ẹ ṣàkíyèsí pé irú ìlànà báyìí pàápàá kò wúlò, nítorí pé kìí ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ tí fáwẹ̀lì kò bẹ̀rẹ̀ wọn ni ọ̀rò.-ìṣe. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kìí ṣe ọ̀rọ̀-ìṣe: kìnìún, bàrà, jàkùnmà, sarè, gbóńgbó, kí, káà. Bẹ́ẹ̀ ni a kò lè sọ pé gbogbo ọ̀rọ̀ tí fáwẹ̀lì bá bẹ̀rẹ̀ wọn ni ọ̀rọ̀-orúkọ, àfi bí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí náà bá ń dárúkọ nǹkan kan: àfi, àmá, àti, àrí.
(3) Mọfọ́lọ́jì
Mọfọ́lójì ni ìmọ̀ tí ó jẹ mọ́ ẹ̀hun ọ̀rọ̀ nínú èdè. Ó kún àlàyé nípa ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ tàbí àtúpalẹ̀ ọ̀rọ̀ sí ègé onítimọ̀. Ó sì kan àdàpè ọ̀rọ̀ tí ó lè tọ́ka ìlò nínú gbólóhùn. Ní èdè Yorùbá, bó bá yẹ̀ ní bí a  bá fẹ́ẹ́ ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ kan láti ara ọ̀rọ̀ mìíràn, kò dájú pé ọ̀rọ̀ Yorùbá ní àdàpè kan dan-indan-in bí ó ti wù kí a lò ó nínú gbólóhù. Oríṣìí ọ̀rọ̀ kan náà tí ó jẹ́ àfi àkíyèsí yìí ni arọ́pò-orúkọ tí ó ní àdàpè tí ó ní láti bá ìlò rẹ̀ nínú gbólóhùn mu. Ṣùgbọ́n ìwọ̀nba ni a lè wo-n-koko mọ́ èyí náa mọ. Àìsí àdàpè ìlò yìi ní ó sì fà á tí kò fi sí ìsọ̀rí-gírámà wọ̀nyí nínú èdè Yorùbá: iye, jẹ́ńdà, ìlò orúkọ (case), ìlò ìṣe (mood), àfiwé, àsìkò. Bí a bá sọ pé ìlò kò jẹ mọ́ ìsọ̀rí gírámà (grammatical category), ìyẹn ni pé, ní èdè Yorùbá, kò sí àmì kan, bíi mọ́fíìmù tàbí ìró tí a pè mọ́ ọ̀rọ̀ kan, tí ó jẹ́ pé túláàsì ni kí a yan ọ̀kan tàbí òmíràn nínú àwọn àmì yìí tí yóò fi ìlò tí a lo ọ̀rọ̀ náà hàn. Bí àpẹẹrẹ kò sí irú àmì béẹ̀ tí ó lè fi hàn lára ọ̀rọ̀-ìṣe bóyá ẹni kan ni ó ní ọwọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ń tọ́ka sí ni tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àpẹẹrẹ: Sopé parọ́/Sopé àti Délé parọ́/Sopé àti Délé parọ́ lánàá/Jọ̀wọ́ parọ́. Kí ẹ má sì mí gbọ́, n kò sọ pé Yorùbá kò mọ ìyàtọ̀ láàrin ẹyọ nǹkan kan àti ọ̀pọ̀ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni n kò sọ pé Yorùbá kò mọ bí nǹkan bá dára ju òmíràn lọ. Ohun tí mo n wí ni pé Yorùbá kò ní ọ̀nà tí a lè dá ọ̀rọ̀ kan soso pè tí yóò fi àwọn ìlò wọ̀nyí hàn.
Jẹ́ńdà: Bí àpẹẹrẹ, ìsọ̀rí-gírámà jẹ́ńdà kò kan ọ̀rọ̀ ‘ó ṣakọ, ó ṣabo’. Jẹ́ńdà jẹ mọ́ oríṣi ọ̀nà tí èdè lè pín gbogbo ọ̀rò-orúkọ rẹ̀ sí, lọ́nà tí ó jẹ́ pé ìpín kọ̀ọ̀kan ní àmì titẹ, tí ó si jẹ́ pé; gbogbo ìgbà tí a bá lo ọ̀rò-orúkọ kan nínú gbólóhùn, a níláti pe àmì ìpín tirẹ mọ́ ọ̀rọ̀ yẹn àti gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó bá yán ọ̀rọ̀ náà. Nínú èdè mìíràn ẹ̀wẹ̀, bí ọ̀rọ̀-orúkọ bá jẹ́ olùwà nínú gbólóhùn, ó di kàn-án-ń-pá kí ọ̀rọ̀-ìṣe inú gbólóhùn yẹn ní àmì ìpín ti ọ̀rò-orúkọ náà. Ẹ ṣàkíyèsí pé ohun tí àwọn elédè bá gbà bíi akọ tàbí abo lè ṣaláìwà nínú ìpín kan náà. Àwọn Yorùbá kò ṣaláìmọ obìnrìn yàtọ̀ sí ọkùnrìn. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì mọ ewúrẹ́ àti àgbébọ̀ yàtọ̀ sí òbúkọ àti àkùkọ. Ṣùgbọ́n Yorùbá kò fi èyí ṣe ọ̀rọ̀ jẹ́ńdà. Nínú àwọn èdè tí ó ní jẹ́ńdà pàápàá, kìí ṣe ọ̀rọ̀ akọ-n-bábo.
III. Ìlò nínú Gbólóhùn
Ọ̀nà tí ó wúlò jù lọ tí a fi lè pín ọ̀rọ̀ Yorùbá sí ìsọ̀rí ni bí àwọn elédè ṣe ń lò ó nínú gbólóhùn. Bí ìlànà mìíràn bá wà, a jẹ́ pé yóò máa gbe èyí lẹ́sẹ̀ ni.
1. Òrọ̀-gírámà
Bí àpẹẹrẹ, àwọn oríṣi ọ̀rọ̀ kan wà tí ẹnikan kìí ṣẹ̀dá. Ìyẹn ni pé wọ́n lóǹkà. Bí wọ́n sì ti ní iye yẹn ni a kò lè tọ́ka sí ìtumọ̀ kan dan-indain-in fún wọn yàtọ̀ sí ìlò tí ènìyàn ń lò wọ́n nínú gbólóhùn. Ìyẹn ni pé àwọn ọ̀rọ̀ báwọ̀nyí kò ní ju ìtumọ̀ gírámà lọ. Lójú tèmi, irú àwọn ọ̀rọ̀ báyìí ni:
(i) Àmì Gbólóhùn: ǹjẹ́, tí, ṣé.
(ii) Asopọ̀: ṣùgbọ́n, àti, sì, yálà, tàbí.
(iii) Àmì Ibá-ìṣẹ̀lè: ti, ń, yóò.
(iv) Àmì Ẹ̀kọ̀: kò, máà.
(v) Atọ́kùn: ti (ti Èkó dé), ní, sí.
(vi) Àmì gbólóhùn Àfibọ̀: tí (Ẹni a fẹ́), kí (Ó yẹ a lọ).
Kò sì dájú pé irú ọ̀rọ̀ bíi kuku, tile, ṣẹ̀ṣẹ̀, kàn-àn kìí ṣe ara irú ìsọ̀rí tí mo ń ṣàpejúwe yìí. Irú ọ̀rọ̀ yìí ni a máa ń pè ní ọ̀rọ̀-gírámà fún ìdí àlàyé tí mo ti ń ṣe bọ̀ yẹn. Gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ yòókù nínú èdè Yorùbá yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀-gírámà ní ti pé wọn kò lóǹkà. Ìdí sì ni pé a lè ṣẹ̀dá irú wọn yálà láti ara ọ̀rọ̀ bíi wọn tàbí láti ara ọ̀rọ̀ ìsọ̀rí mìíràn. Ohun kan pàtàkì tí ó ya ìsọ̀rí àwọn ọ̀rọ̀ yìí nípá ni bí a ṣe í lò wọ́n nínú gbólóhùn. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni a máa ń lo àpólà gbólóhùn (phrase) tàbí odidi gbólóhùn (sentence/clause) bí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.
 2. Ọ̀rọ̀-orúkọ: Ìlò nínú gbólóhùn.
Olùwà: Gírámà le, Èkó tóbi, Iṣẹ́ parí, Ọmọ borí owó, Tèmí sunwọ̀n.
Orí-ọ̀rọ̀/àbọ̀ ọ̀rò-ìṣe: Mo rí ayọ̀, A dé Èkó, Wọ́n ra ọkọ̀.
Yíyán pẹ̀lu (i) rẹ̀ (Orí rẹ̀ dára) (ii) gbólóhùn - ((1)Èmí ò jata, ẹ̀mí yẹpẹrẹ (2) Tèmi mo fún ọ ni mò ń bèèrè) (iii) ọ̀rọ̀-orúkọ mìíràn (Àǹkárá Ghana wù mí).
Àbọ sí, ní àti ti: A ó ríra ní Ọ̀la; A pe ìpàdé sí Kánò; Ó ti Èkó lọ sí Kánò.
Ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀-orúkọ pẹ̀lú oní-, ti: Onígbàjámọ̀ kò fá orí mi dáadáa; Ti ìkà ló ṣòro.
3. Ọ̀rọ̀-ìṣe: (i) Ilò nínú gbólóhùn ẹlẹ́yọ ọ̀rọ̀-ìṣe tí kò ní ẹ̀yán kan kan: (olùwà) – (àbọ̀). Àpẹẹrẹ: (1) Ẹ /Ẹ dúró (2) Òjó rọ̀/ Ọmọ́ dára (3) tirẹ/Ka ìwé (4) Ọdẹ pa ẹtu/Ọlọ́pàá olè. (ii) Ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀-orúkọ: Ara àpólà ìṣe nìkan ni a ti í fi àwọn àfòmọ́ wọ̀nyí ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀-orúkọ: (1) àì: àìní/àìṣe (2) àpètúnpè kọ́ńsónáǹtì àkọ́kọ́: kíkọ yàtọ̀ sí sisọ.
4. Ọ̀rọ̀-ẹ̀yán:
Gbogbo ọ̀rọ̀ tí a bá lè lò láti fi ya ọ̀rọ̀ kan, yálà ọ̀rọ̀-orúkọ ni o, tàbí ọ̀rò-ìṣe, tí a fi lè ya ọ̀rọ̀ kan sọ́tọ̀ sí òmíràn, ìyẹn ni ọ̀rọ̀ tí ó jẹ́ pé kókó àbùdá kan soso ni ìtumọ̀ rẹ̀ tí ó sì jẹ́ pé a kò lè lò ó pẹ̀lú ọ̀rọ̀ mìíràn tí àbùdá yẹn kò kún ìtumọ̀ rẹ̀, irú ọ̀rọ̀ báyìí ni a lè pè ní ọ̀rò-ẹ̀yán. Nínú èdè Yorùbá, kò sí ìyàtọ̀ fonọ́lọ́jì tàbí ti mọfọ́lójì tí a lè fi dá ọ̀rọ̀ tí a lè fi yán ọ̀rò-orúkọ mọ̀ sọ́tọ̀ sí èyí tí a lè fi yán ọ̀rọ̀-ìṣe. Ìdí nì yí tí kò fi gbogbo ara wúlò kí á pín ọ̀rọ̀-ẹ̀yán yẹ́leyẹ̀lẹ, kí a máa pe ọ̀kan ní ‘adjective’, òmíràn ní ‘adverb’. Ọ̀rọ̀ tí a bá lò láti yán ọ̀rọ̀-orúkọ nínú gbólóhùn ni a ó máa pè ní ẹ̣̀yánrúkọ[2], ti ọ̀rọ̀-ìṣe ni ẹ̀yánrọ̀-ìṣe[3].
(i) Ẹ̀yánrúko: (1)  Ọmọ dúdú wù mí (2) Ilé gíga  pọ̀ ní Yunifásítì Ifẹ̀ (3) Ẹgbẹ́ ẹni ni a ń gún iyán wùrà  pè.
(ii) Ẹ̀yánrọ̀-ìse (1) Ìrẹ̀ náà han gooro (2) Ojú ti olè náà; ó kó tìọ̀ (3) Wíwọlé tí jagunlabí wọlé; àyà mi sì lọ fée.
5. Arọ́pò-orúkọ: Àwọn òrọ̀ wọ̀nyí ni ó wà ní ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ tí a ń pè ní arọ́pò-orúkọ: Mo/mi/n, o, ó, ẹ, wọ́n. Àwọn àkíyèsí yìí ṣe pàtàkì nípa wọn: (i) wọ́n níye nítorí pé a ò lè ṣẹ̀dá irú wọn mìíràn (ii) a ò lè ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ mìíràn lára wọn (iii) ìtumọ̀ wọn kò ju iṣé wọn nínú gbólóhùn lọ; ìyen ni láti tọka iye àti ẹni tí a bá fi ojú ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ wo gbólóhùn (iv) àǹkóò fáwẹ̀lì máa ń ràn wọ̀n (v) àwọn nìkan ni wọ́n ní àdàpè nínú ìsọ̀rí-ọ̀rọ̀ yòókù.
6. Bí mo ṣe menu bà á  fẹ́rẹ́ lẹ́ẹ̀kan, Yorùbá a máa ṣábà lo àpòlá àti gbólóhùn bíi ẹyọ ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan. Ìyẹn ni pé bí a ti lè rí ọ̀rò-orúkọ, ọ̀rò-ìṣe, ọ̀rò-ẹ̀yan, bẹ́ẹ̀ ni a lè rí àpólà àti gbólóhùn tí a lè lò bí ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan yìí. Apẹẹrẹ:

(i) Ọ̀rọ̀-orúko: Pé gírámà kò yé yín bà mí nínú jẹ́ (ii) Ọ̀rọ̀-ìṣe: Ó ta téru nípàá  (iii) Ọ̀rọ̀-ẹ̀yán (1) Ẹ̀yánrúkọ: (i) Ẹni bí ahun níí rí ahun he (ii) Ẹni tí a fi orí rẹ̀ fọ́ àgbọn kìí jẹ níbẹ̀. (2) Ẹ̀yànrọ̀-ìṣe: (a) N ó rí ọ lọ́la (b) Bá mi nílé (d) Da omi síwájú bí o bá fẹ́ẹ́ tẹ ilẹ̀ tutu (e) Ó ṣe mí bí ọṣẹ ṣe í ṣe ojú (ẹ) Mo rí ọ bí o ṣe ń wọlé (f) Wọn ó mú wa bí a bá rú òfin (iv) Ọ̀rọ̀-gírámà Mo bá a níwájú ilé wa.
Oríṣìí ọ̀nà ni a lè gba wo àpólà níwájú ilé wa. (a) ní (iwájú ilé wa) (b) (níwájú) ilé wa. Ọ̀nà àkọ́kọ́ ni èmi fara mọ́.



[1] This paper was titled O.O. Oyelaran (1982), ‘Ìwé Ìléwọ́ lórí Ìsọ̀rí Gírámà’, Department of African Languages and Literatures, University of Ifẹ, Ilé-Ifẹ̀, Nigeria.
[2] Eláyìí ni a ń pè ní ọ̣̀-àpèjúwe báyìí.
[3] Eléyìí ni a ń pè ní ọ̣̀-àpọ́nlé báyìí.

Comments

Popular posts from this blog

YORÙBÁ LITERATURE E-LIBRARY

SYNTAX AND GRAMMATICAL THEORIES E-LIBRARY SECTION

YORÙBÁ GRAMMAR E-LIBRARY SECTION