ÒRÒ ÀPÈJÚWE ASE-KÓKÓ-GBÓLÓHÙN TÀBÍ ÒRÒ-ÌSE AṢÀPÈJÚWE (PREDICATIVE ADJECTIVE)?
Òrò Àpèjúwe Ase-kókó-gbólóhùn tàbí Òrò-ìse Aṣàpèjúwe?
Enu àwon onímò èdè kò kò lórí ìsórí tí à bá pín àwon ọ̀rọ̀ bíi ‘ga, pón pupa, funfun abbl’sí. Lójú ọ̀jọ̀gbọ́n kan, ọ̀rọ̀ àpèjúwe ase-kókó-gbólóhùn (OAAG ni a ó máa pe èyí) ni o yẹ ka máa pè wón. Ó ní ìdí ni pé wón ní ònà tí wón fi jo AJ (òrò-àpèjúwe ni a lo àmì yìí fún) bí ‘dúdú’ inú ‘Aso dúdú yìí’ wón sì ní ònà tí wón fi jo IṢ (òrò-ìṣe nì a lo èyí fún) bí i ‘lọ’ àti ‘gé’. ‘Ga’ jọ ‘gé’ àti ‘lọ’ nípa pé (i) wón lè jeyo nínú GBOL (gbólóhùn nì èyí dúró fún) abódé, ba: ‘ọmọ náà gé igi/ọmọ náà ga/ọmọ náà lọ’(ii) ibá àti àsìkò lè jeyo pèlú won, ba: ọmọ náà ń gé igi/ọmọ náà ń ga/ọmọ náà ń lọ’(iii) a lè so wón dorúko nípa àpètúnpè elébe, ba: ‘gígé ni ọmọ náà gé igi/gíga ni ọmọ náà ga/lílọ ni ọmọ náà lọ’ (iv) a lè yí won sódì, ba: ọmọ náà kò lọ/ọmọ náà kò gé igi/ọmọ náà kò ga’ (v) wón lè jeyo nínú GBOL ìbéèrè, ba: ‘ṣé ọmọ náà gé igi/ṣé ọmọ náà ga/ṣé ọmọ náà lọ?’ (vi) múùdù lè jẹyọ pẹ̀lú wọ́n, ba: ‘ọmọ náà lè lọ/ọmọ náà lè ga/ọmọ náà lè gé igi (vii) sílébù kan ni púpò nínú IṢ jẹ́, sílébù kan ni àwon náà ní (viii) wọ́n lè tẹ̀lé sílébù olóhùn òkè, ba: ‘ọmọ́ ga/ọmọ́ gé igi/ọmọ́ lọ’. Ga yàtọ̀ sí gé àti lo nípa pé (i) kò lè jẹyọ nínú GBOL àṣẹ, ba: ‘Lọ/Gé igi/*Ga’ (ii) kò lè gba àfikún, ba: ‘lọ sí ilé/gé igi/*ga ọmọ’ (iii) a kò lè se àtenumó ìyísódì sí i, ba: ó ṣaláìgé igi/ó ṣaláìlọ/*ó saláìga’ (iv) kò gba IṢ láti fi yán OR, ba: ‘ilé ìgégi/àkókò ìlọ ilé/*oògùn ìga ọmọ. Pèlú gbogbo àlàyé wònyí, ọ̀jọ̀gbọ́n yìí ní ga ní ònà tí ó fi jọ AJ ó sì ní ònà tí ó fi jọ IṢ. Iṣẹ́ kókó-GBOL ni a mọ IṢ mọ́, isé èyán ni a mọ AJ mọ́. Ó ní nítorí ìdí èyí, kí á máa pe àwon ọ̀rọ̀ bíi ga ni OAAG. Ó ní èyí yí o fi ìbásepọ̀ rẹ̀ pèlú IṢ àti AJ hàn àti pé tí a bá se báyìí, ìbásepò tó wà láàrin irú èdè Gèésí àti Yorùbá yóò hàn torí àwon náà ni Predicative Adjective, ba: ‘All things will be cold’ tí àwon omo mìíràn máa ń sì pè ní ‘All things will cold’ nítorí èdè Yorùbá ‘Gbogbo nǹkan yóò tutu’ tí ó ti yi mọ́ wọn lára. Ọ̀jọ̀gbọ́n mìíràn ni ó dá ti akọ́kọ́ lóhùn. Ó ní Òrò-ìse aṣàpèjúwe ni ó yẹ kí á máa pè àwon ọ̀rọ̀ bíi ga. Ó wá bèrè sí níí wo gbogbo ohun tí ọ̀jọ̀gbọ́n àkọ́kọ́ rí tí ó fi so pé kí á máa pe ga àti àwọn òrọ̀ bí irú rẹ̀ ní OA, ó sì ní gbogbo rè ni kò fẹsẹ̀ mulẹ. (i) Ó ní ká wo tì, ní, ń kó àti dà. Ó ní gbogbo won, IṢ ni wón síbè, won kò lè dá jẹ yọ nínú GBOL àṣẹ. Nǹkan tí èyí fi hàn ni pé a kò lè lo ìlànà yìí láti so pé ga kì í ṣe IṢ. (ii) Ǹjé ó yẹ kí a fi ìsodorúkọ alátẹnumọ́ bíi ṣaláìga, ṣaláìlọ tàbí ṣaláìgé igi dá IṢ mọ̀? Ohun tí ó se pàtàkì ni pé kí á fi ‘àì’ so IṢ di OR, a sì lè se èyí sí ga kí ó di ‘àìga’. Èyí ló pọn dandan. Ǹjé òòtọ́ ni pé a kò tilẹ̀ lè sọ pé Ọmọ náà slaáìga?. Lójú ọ̀jọ̀gbọ́n yìí, a lè sọ bẹ́ẹ̀. (iii) Nípa ti ìgbàbọ̀ àti àìgbàbọ̀, ọ̀jọ̀gbọ́n yìí sọ pé ga náà lè gba àbò bó se àbò péékí tí a sèdá lára rè, ba: ‘omo náà ga ìga àgéré’. (iv) kìí se òótó ni pé ga lè jẹ pẹ̀lú òrò-ìse ọ̀bọ̀rọ́ torí alè rí ‘gíga ṣeé ga’. (v) Lóòótó, a lè rí ‘ilé ìgé igi’ àti pé a kò lè rí *ilé ìga gíga’ sùgbón nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀ ni pé kìí se gbogbo IṢ ni a lè se báyìí sí, ba: kò sí ‘*ilé ìlọ lílọ, *ilé ìwà wíwà, abbl’. (vi) ga yóò wo férémù yii - //APOR------- (APOR)// - tí ó jẹ́ férémù tí ó wúlò jù fún dídá IṢ mọ̀, nítorí náà, lójú ọ̀jọ̀gbọ́n kejì yìí, OA ni àwon òrò bíi ga. Èdè Gèésì ti ọ̀jọ̀gbọ́n àkọ́kọ́ fi ń se òdiwọ̀n Yorùbá ni ó je kó pè é ní OAAG.
Comments
Post a Comment