ÌṢẸ̀DÁLẸ̀ YORÙBÁ

 

ÌṢẸ̀DÁLẸ̀ YORÙBÁ

Òǹkọ̀wé:                     E. Alademọmi Kẹnyọ[1]
Ibi Ìtẹ̀wétà:                 Lagos
Atẹ̀wétà:                     The Yorùbá Historical Research Company
Déètì Ìtẹ̀wétà:             1953

ÌSỌNÍSÓKÍ ÌWÉ ÌṢẸ̀DÁLẸ̀ YORÙBÁ
Òǹkọ̀wé E. Alademọmi Kẹnyọ jẹ́ elétí ọmọ Ìkálẹ̀, òun ni Olùdásílẹ̀ àti alábójútó ẹgbẹ́ iṣẹ́ pàtàkì tí à ń pè ní Yorùbá “Historical Research Company ní Èkó.” A tẹ ìwé ìṣẹ̀dálẹ̀ Yorùbá jáde ní ọdún 1953. Ìwé náà dale orí ìtàn àwọn Yorùbá, ó sì sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́ àti irọ́ tí àwọn òpìtàn mìíràn ti sọ nípa ìṣẹ̀dálẹ̀ Yorùbá.
Ní orí kì-í-ní àti orí kejì ìwé yìí, ohun tí òǹkọ̀wé ń gbìyànjú àtisọ ni orísirísi ìtàn tí ó wà nípa ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn Yorùbá pé àwọn òpìtàn kan sọ pé ilẹ̀ Íjíbítì (Egypt) ni a gbé ti ṣẹ̀, tí àwọn kan sì sọ pé ilẹ̀ Arábíà (Arab) tí à ń pè ní ilẹ̀ Mẹ́ka (Mecca) ni, àmọ́ àwọn àgbà Ilé-Ifẹ́ ta kò gbogbo èyí. Wọ́n ní ìsálú ọ̀run ni Odùduwà ti wá tẹ Ilé-Ifẹ̀ dó.
Ní orí kejì, Kẹnyọ gbà pé ilẹ̀ Íjíbítì (Egypt) ni Odùduwà ti kúrò nítorí ogun burúkú tí o ṣẹlẹ̀ tí àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn fi tẹ̀ lé e láti Íjíbítì (Egypt) wá sí Ilé-Ifẹ̀; ó fi ẹ̀rí gbè e pé tí a bá ṣe àkíyési ìwà, ìhùwàsí, ìṣesí, ọgbọ́n àwọn ara Íjíbítì àti Ilé-Ifẹ̀ pe bákan náà ni.
Síwájú sí i ní orí kẹta ìwé náà, ó ṣàlàyé Ifá ti ilẹ̀ Yorùbá àti (Oracle) ọ́rákù tí ilẹ̀ Íjíbítì (Egypt) bí wọn ṣe jọra pé ohun tí wọn ń fi Ifá ṣe ni ilẹ̀ Yorùbá náà ní wọn ń fi Ọrákù (Oracle) ṣe ní ilẹ Íjíbítì (Egypt), ó tún fi ẹsẹ Ifá gbè é lẹ́sẹ̣̀
Èké ṣíṣe ni ń pa elékèé
Ilẹ̀ dídà ní ń pa ọdàlẹ̀
Òtítọ́ nìkan ṣoṣo ní ń mú
Ní hewú orí nẹne,
O dà fún Fámúrewa-Ajikósùn…
Ní orí kẹrin, Kẹnyọ ń gbìyànjú àti fi Ifá wé ẹ̀sìn mímọ́ Krístì. Ó sọ pé kí àwọn Onígbàgbọ́ Krìstẹ́nì àti ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí tó dé ni Ifá tí ń sọ́ fún àwọn ènìyàn nípa Wòólí Mímọ́ náà tí à ń pè ni Jésù. Ó tún tẹ̀ síwájú láti sọ gbogbo iṣẹ́ rere tí Jésù ṣe tí a sì tọ́ka sí nínú Bíbélì. Kẹ́nyọ̀ tún sọ pé Jésù yìí ni àwọn Mùsùlùmí mọ̀ sí Yísá, àmọ́ wọn kò gbà pé ọmọ Ọlọ́run ni í ṣe, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbà pé a kàn án mọ́ àgbélébù àmọ́ wọ́n gbà pé ó tún ń padà bọ̀ ní ẹ̀ẹ̀kejì.
Nínú àlàyé ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sọ pé Jésù tí àwọn Mùsùlùmí pè ní Yísá náà ni Ifá pè ni Ẹ̀là. Gbogbo iṣẹ́ tí Jésù ṣe náà ni Ẹla ṣe; ó tún fi ẹsẹ Ifá gbè é lẹ́sẹ̀.
Ẹ̀lá sogbó ṣogbó
Ẹ̀lá satọ́ ṣatọ́
Ó fọdúndún sobá ewé
Ó firòsùn ṣọsọrun rẹ̀
Ó fokùn sỌba omi…
Ní àkótán, Kẹnyọ gbà pé ipò kan náà tí “Oracle” wà ní ilẹ̀ Íjíbítì (Egypt) àti ni Greece ni Ifá ti wà ní ilẹ̀ Yorùbá nígbà kan rí, kí àwọn ẹlẹ́sìn Krìstẹ́nì àti ẹlẹ́sín Mùsùlùmí tóó dé.
Láfikún, Kẹ́nyọ̀, ní orí kàrún, ń sọ nípa ìmọ̀ tí àwọn Yorùbá ìgbàanì láti fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí ìlú òkèrè nípa lílo àròkò bíi owó ẹyọ mẹ́fà, ẹgbọrọ ẹfun nínú igbá adẹ́mu, aṣọ funfun àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Irú àṣà bàyìí kò sì tíì parẹ́ ní ilẹ̀ Áfríkà, pé àṣà yìí ṣì wà ní ilẹ̀ Íjíbítì (Egypt); bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àgbà òpìtàn kò gbà pé láti ilẹ̀ Íjíbítì ni Yorùbá ti gbe pẹka.
Síwájú sí i, ó sọ ìtàn ìjáde lọ Ọba Olówu kìn-ín-ní; orúkọ bàbá tó bi Olówu kìíní, pé òun náà sì ni Ọba Asunkúngbadé pé orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Ọlawùní tí íṣe àrẹ̀mọ obìnrin Ọlọ́fin.
Ní orí kẹjọ ni ó ti sọ nípa ìsalú ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ̀dálẹ̀ Yorùbá, ìtumọ̀ “Ọlọ́fin” àti ìtumọ̀ “Odùduwà.” Èyí sì ni ìgbàgbọ́ àwọn Yorùbá pé ọjọ́ kan, Olodumare ran ọkùnrin ọlọ́lá àti amòyè kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọlọ́fin tí wọ́n tún mọ̀ sí Ọlọ́fin ayé wá sí ayé. Olodumare yan àwọn ìjòyè mẹ́rìndínlógún láti bá a wá. Nínú àwọn ìjòyè yìí, ẹni tí ìmọ̀ rẹ̀ ga jù ni Ojùmú tí Ọlọ́run fi ẹyẹ abàmi kan lé lọ́wọ́ pẹ̀lú ètò bi yóò ṣe máa lò ó. Olúkúlùkù ìjòyè náà ni a fún ni adé aláràbarà. Lẹ́yìn èyí ni a rọ ìyẹ̀pẹ̀ ilẹ̀ kún ohun èlò tí wọn yóò lò. ̣yìn èyí ni Ọba ọ̀run pàṣ̣ẹ fún olúkúlùkù ìjòyè náà láti sọkàlẹ̀ lọ
Ojùmú, tí a mọ̀ sí ọlọ́bà akáiyédò, náà bú ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀pẹ̀, ó dà á sórí òkun ayé ní ìsàlẹ̀. Lẹ́yìn náà ni ó pàṣẹ fún ẹyẹ abàmì kí ó fò tẹ̀lé ìyẹ̀pẹ̀ náà láti lọ tàn án sorí òkun ayé. Ẹyẹ náà sì ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn gbogbo isẹ́ àwámáàrídìí yìí ni Ojùmú tó wá fi ẹ̀wọ̀n rọ̀ lọ sórí ilé ayé titun náà. Ọlọ́bà bẹ̀rẹ̀ ètùtù ilẹ̀ náà ni síṣe. Lẹ́yìn tí ó ṣe èyí tán ni ó tó wáá pé Ọlọ́fin ayé láti máa bá ẹ̀wọ̀n rọ bọ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè tó kù. Lẹ́yìn tí gbogbo wọn ti rọ tán ni Ọlọ́bà mú gbogbo wọn kiri orílẹ̀ ilẹ̀ náà tí ó sì sọ gbogbo ètùtù tí Ọlọ́fin ayé yóò máa ṣe lórí ilẹ̀ náà. Ó tún sọ fún ọlọ́fin ayé bí yóò ti di àràbà lórí ilẹ̀ náà, tí àwọn Oọba aládé mẹ́rìndìnlógún yóò jáde láti irú ọmọ rẹ̀. Ibi tí Ọlọ́fin ayé kọ́kọ́ fi ẹ̀sẹ̀ rẹ̀ tẹ̀ lórí ilẹ̀ náà ni à ń pè ní “Mọ̀rẹ̀”. Ibẹ̀ ni ó sì ti kúrò lọ sí ibi tí ààfin Ọba Ìfẹ gbé wà títí di òní olóòní yìí.
Kẹ́nyọ̀ tún gbìyànjú láti jẹ́ kí á mọ̀ ìtumọ̀ Ọlọ́fin àti ìtumọ̀ Odùduwà pé Ọlọ́fin ni ẹni tí ó ní agbára tàbí aṣẹ láti ṣe ohunkóhun tí ọgbọ́n àti ìmọ̀ rẹ̀ tayọ tí ẹnikẹ́ni ní ìgun mẹ́rẹ̀rin ilé ayé. Ìtumọ̀ Odùduwà ni pé lẹ́yìn ìgbà tí Ọlọ́fin pilẹ̀sẹ̀ ayé tan, tí wọ́n sí mọ̀ pé ènìyàn mẹ́rìndìnlógún ni wọ́n fi pilẹ̀sẹ̀ rẹ̀ láti ọwọ́ Ọlọ́fin, wọ́n wá bẹrẹ̀ sì níí pè é ní odù, pé òun ni ẹni tí ó fi ènìyàn mẹ́rìndìnlógún pilẹ̀sẹ̀ orílẹ̀-èdè. Nígbà tí àwọn ènìyàn rí i pé ó di ẹni ńlá bamùtàtà, tí ìlu tí ó fi ènìyàn mẹ́rìndìnlógún pilẹ̀sẹ̀ rẹ̀ tóbi púpọ̀ tí wọn kò sì ní ọba mìíràn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí i níí pè é ní Odù tí ó dá wa tí wọ́n mọ̀ sí Odùduwà.
Ní orí kẹsàn-án, ìwé náà ń tọ́ka sí ọba Ọlọ́bà àti ètùtù ilé ayé; bí ó ti máa ń ṣe orò nipa ilẹ̀. Díẹ̀ lára àwọn orò náà nìyí:
                                i.            Bí ọmọ bá jábọ sílẹ̀ lẹ́yìn ìyá rẹ̀
                              ii.            Bí a bá tẹ́ òkú sílẹ̀ tí ìjàlọ̀ sí ṣùrù bò ó mọ́lẹ̀
                            iii.            Bí ọkunrin kan bá lọ hu ìwà èérí pẹ̀lú obìnrin lórí ilẹ̀ láìtẹ́ ẹní.
                            iv.            Bí ògiri bá ya lu ènìyàn abẹ̀mí mọ́lẹ̀ tí ó sì pa á kú sọ́run
                              v.            Bí ọkùnrin kan bá lọ jarunpá lọ́nà ẹ̀gbin lu ìyá tí ó bí i lọ́mọ, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ,
Àwọn àgbà náà gbà pé ibi tí èyí bá ti sẹlẹ̀ pé ilẹ̀ ibẹ̀ bàjẹ́; kò sì níí ìfọkànbalẹ̀ fún àwọn àgbà náà títí tí wọn yóò fi ṣètùtù.
Ó tún tọ́ka sí i pé ni orí karùn-ún àràgbayábú ìwé rẹ̀ tí ó pé ní “History of the Yorubas”, Olóògbé Samuel Johnson sọ ọ́ pé Yorùbá kò bá Mẹ́kà tan rárá, pé àwọn àṣà orílẹ̀-èdè mejeeji náà kò fi okùn ìbátàn ni àárín ara wọn hàn.
Síwájú sí i, ní orí kọkànla àti orí kejìlá, ó sọ nipa àwọn aládé mẹ́rìndìnlógún tí òwúrọ̀ kùtù àti àwọn ilẹ̀ tí wọ́n jẹ́ mọ́ Yorùbá. Àwọn aládé mẹ́rìndìnlógún náà ni: Ajerò, Aláàfin, Aláké, Alákétu, Alárá, Arìngbájọ́, Awùjalẹ̀, Èwí, Ẹlẹ́kọ̀lé, Oníbìní, Olówu, Onísábẹ, Òrè, Òsémàwé, Ọ̀ràngún àti Ọwá. Àwọn ilẹ̀ tí ó sì jẹ mọ́ Yorùbá ni Adó, Àkókó, Àpọì, Àwórì, Èkìtì, Ẹ̀gbá, Ẹ̀gbádò, Ifẹ̀, Ìfònyìn, Ìgbómìnà, Ìjẹ̀bú, Ìjẹ̀ṣà, Ìjúmù, Ìkálẹ̀, Ìlàjẹ, Ìlọ̀rin, Ìpókíá, Ìtṣèkíri, Ìyàgbà, Kétu, Kùkùrúkù, Oǹdó, Ọ̀wọ̀, Ọ̀yọ́, Rẹ́mọ, Sábẹ, “Colony”, “Èkó.”
Ni orí kẹrìnlá ni Kẹ́nyọ̀ ti mẹ́nu ba ilẹ̀ Òwu àti ìṣubú rẹ̀ pé ilẹ̀ Òwu jẹ́ ilẹ̀ kan tí o ni ọjọ́ lórí púpọ̀. Wọn pọ̀ ni ìmọ̀ ogun jíjà ní ọjọ wọ̀n-ọn-nì tó bẹ́ẹ̀ tí púpọ̀ nínú àwọn Yorùbá yòókù fi ń bẹ̀rù rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a tí sọ ìtàn rẹ̀ síwájú pé Ọláwùmí ni ìyá rẹ̀ tí Ọbàtálá sì jẹ́ bàbá rẹ̀. Bàbá ọmọ náà sọ ọ́ ní Oláwùmí tí ìyà rẹ̀ sọ ọ́ ní Ajiíbọ́sìn. Ọláwùmí gbé ọmọ rẹ̀ lọ kí baba rẹ̀ ni ọjọ kan. Inú Ọba Ọlọ́fin dùn láti ri i. Ó bun ọmọ ọwọ́ náà ní àwọn nǹkan mèremère gbogbo ó sì súre fun ọmọ ọwọ́ náà. Nígbà tí ó tó àkókó kí Ọláwùmí padà lọ sí ilé rẹ̀, ọmọ ọwọ́ naà bẹ̀rẹ̀ si níí sunkún. Ọlọ́fìn gbé adé lé ọmọ náà lọ́wọ́, ọmọ náà sì dákẹ́ ẹkún sísun. Nígbà tí a tún gba adé yìí lọ́wọ́ rẹ̀, ó tun bẹ̀rẹ̀ sí níí sunkún. Ọba Ọlọ́fin ṣe àkíyèsí pé ọmọ náà fẹ́ adé ni, nítorí náà, ó jọ̀wọ́ adé mèremère náà fún un. Ìdí rẹ̀ nìyí tí a fí ń pé ọpọ òwu ni ọmọ asunkún-gbadé. Nígbà tí ọmọ Ọba Ajíbọ́sìn di ọmọkùnrin tan, Ọlọ́fin rí i pé ó tó ẹni tí ó ń mú ìlú dání, ó bùkún un, ó sì pàṣe pé kí ó jáde kurò ní Ilé-Ifẹ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ amọ́ kò gbọdò jìnnà sí ọdọ òun nítorí òun fẹ́ máa gbọ́ nípa rẹ̀ nígbà gbogbo; kò sì gbọ̀dọ̀ tàkànràngbọ́n sí ohun tí Ifá bá sọ.
Ọba Olówu pọ̀ ni agbára àti ọlá tó fi jẹ́ pé àwọn olórí ilẹ̀ Yorùbá ẹgbẹ́ rẹ̀ tó kù bẹ̀rẹ̀ sí níí wa ọ̀nà tí àwọn yó gbà pa iná agbára rẹ̀.
Ní àkótán, ní orí kẹ́dògún, tíí ṣe ìparí, a mẹ́nu bà ìtàn ọmọ Ọba Sábẹ tí ó padà di olórí ìlú kan ní ilẹ̀ Ọ̀yọ́, bí wọn ṣe lé e kùró ní Ìgànná àti àwọn Sábigànná.
Ní ayé àtijọ́ Ọba Onísábẹ wàjà. Lẹ́yin ìgbà tí wọn ti ṣe ìsìnkú rẹ̀ tán, àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji bẹ̀rẹ̀ sí níí ja du oyè. Àwọn afọbajẹ fohùn ṣọ̀kan lati fi ẹ̀gbọ́n jẹ ọba. Gẹ́gẹ́ bí àṣà wọn pé nígbà tí wọ́n bá ń jà dú oyè, ẹni tí oyè kò bá já sí lọ́wọ́ ni láti fi ìlú náà sílẹ̀ ni. Wọ́n gbà pé ọ̀tá ọba kì í báa gbé orí ilẹ̀ kan ṣoṣo. Bàlàkó fí ojú tín-ín-rín àṣà náà. Ibi tí ó ń tí gbé ń pàlẹ̀mọ́ pẹ̀lú àwọn ẹbí rẹ̀ ní àwọn àgbà àgbà ìlú dé pẹ̀lú ohun ìjà lọ́wọ́. Bàlàkọ́ fo odi ìlú náà rékọjá sí ìhà kejì. Lẹ́yìn ìrìn-àjò rẹ̀ díẹ̀, ó pàgọ́ sí ibi kan ní ilè Sábẹ tí a mọ̀ sí Ìgànná Ọ̀ṣinsìn. Níhín-ín ni a gbé mọ ọmọ ọba náà sí Sábigànná ìtumọ̀ èyí ni Sábí ti ó fo ìgànná.
Lẹ́yìn ìgbà tí Sábigànná ti lo àkókò gígùn ni ìlú rẹ̀ tí à ń pè ní Ìgànná Ọ̀ṣìnṣìn yìí, ìròyìn dé ọ̀dọ̀ Onísábẹ ni ilẹ́ Sábẹ pé ọmọ Ọba ti a lé kúrò ní Sábẹ ti lọ pàgọ́ sí ibi tí orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Ìgànná Ọ̀sìnṣìn pé àwọn ènìyàn Sábẹ sì ń fi Sábẹ sílẹ̀, wọ́n sì ń tọ ọmọ ọba náà lọ. Nígbà tí Onisábẹ gbọ́ èyí, inú bíì ó sì gbé àwọn ìránṣé dìde láti lè ọmọ ọba náà kúrò ní orí ilẹ̀ náà. Nígbà tí Bàlàkọ́ gbọ́ èyí, ẹsẹkẹsẹ̀ ni ó fi ilẹ̀ náà sílẹ̀, ó sì fori le ọna ibòmíràn.
Bàlàkọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ rìn kiri lorí pápá fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Lẹ́yìn náà ni ó wá yọ sórí ilẹ̀ Ọ̀yọ́. Ó bèrè olórí ilẹ̀ náà wọ́n sì sọ fún un pé Ọba Aláàfin ni. Bàlàkọ́ lọọ gba àṣẹ láti tẹ ìlú dó sóri ilẹ̀ Ọ̀yọ́. Lẹ́yìn ìgbà tí Ọba Aláàfin ti fi gẹ́gẹ́ bí àwọn ìlú tó ń bẹ lábẹ́ rẹ̀ ti máa ń ṣe fún un, ó fi tọkàntọkàn gbà láti lọ tẹ ìlú dó sóri ilẹ̀ ibi tí ó wà. Nígbà tí Sábigànná tẹ ìlú rẹ̀ yìí tán nítòòtọ́, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Ìgànná. Ìlú náà jẹ́ èyí tí ó tóbi púpọ̀ tí ó sì lágbára púpọ̀.Òkìkí ìlú náà dé Sábẹ sùgbọ́n nígbà tí Ọba Sábẹ rí i pé kì í ṣe orí ilẹ̀ òun ní ó tẹ ìlú náà si, kò rí ipá kan sà mọ́.
Ní ìkádìí, àwọn Sábigànná nìyí:
                             i.                           Sábi Bàlàkó
                           ii.                           Aìbìo
                         iii.                           Amósùngangan
                         iv.                           Sata
                           v.                           Adéọ̀ṣun
                         vi.                           Ajíbúlù
                       vii.                           Olúpàtẹ
                     viii.                           Adégbọ́lá
                         ix.                           Etin-ẹlu
                           x.                           Àṣàmú
                         xi.                           Lábíyì
                       xii.                           Ẹdun
                     xiii.                           Òjó
                     xiv.                           Ládòkun
                       xv.                           Òjó II
                     xvi.                           Oyèlẹ́yẹ
                   xvii.                           Láwọyin
                 xviii.                           Lábísí
Ìwé Ìtọ́kasí
Alademọmi, E. Kẹnyọ (1953), Ìṣẹ̀dálẹ̀ Yorùbá. Lagos, Nigeria: The Yorùbá Historical Research Company.



[1] Adegboyega Olufunmilayo Adenike ni ó kọ bébà yìí.

Comments

Popular posts from this blog

YORÙBÁ LITERATURE E-LIBRARY

SYNTAX AND GRAMMATICAL THEORIES E-LIBRARY SECTION

YORÙBÁ GRAMMAR E-LIBRARY SECTION