Ìlò Èdè (Use of Language)
Ìlò Èdè (Use of Language)
Èdè ni a ń lò fún ìbáṣepọ̀ láwùjọ. Kò sí bí
ìbáṣepọ̀ ṣe lè wà láìsí ìlò èdè. Tí kò bá sí èdè, kò sí bí ìbáṣepọ̀ ṣe lè
wà láwùjọ. Ọ̀nà ìgbọ́ra ẹni yé yóò sì ṣòro. Kò sí bí a ṣe lè ṣe àṣeyẹ
kan láìlo èdè. A ó kọrin ni o, a ó sọmọlórúkọ ni o, a ó kéwì ni o, èdè ni a
fi ń
gbé gbogbo wọn jade. Èdè jẹ́ ohun èlò pàtàkì fún ìmú nǹkan ṣe. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú
àwọn ọ̀nà tí a fi ń sọ fún ẹni kan pé kí ó ṣe nǹkan kan. Èdè jẹ́ ohun èlò kan
fún àṣẹ pípa àti ìròyìn ṣíṣe. Èdè máa ń ran èrò wa lọ́wọ́. Ó jẹ́ ọ̀nà
kan tí a fi ń gbé èrò wa jade lọ́nà tí yóò fi yé ènìyàn. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú
àwọn ohun èlò tí a ń lò láti fi gbé tinú wa jade. Ó jẹ́ ọ̀nà kan tí a fi ń
sọ ohun tí ó wà nínú wa fún ènìyàn lọ́nà tí yóò fi mọ̀ ón. Ìdí èyí ni Yorùbá fi máa ń sọ pé ẹni tó bá dákẹ́,
a ò mọ tinú rẹ̀.
Ọ̀nà tí Ọmọdé ń Gbà Kọ́ Èdè (Language Acquisition by Children)
Kì í ṣe pé ọmọdé ń kó gbogbo ọ̀rọ̀ tàbí gbogbo gbólóhùn tí ó wà nínú èdè kan jọ sí ibi kan. Ìdí èyí ni wí pé ọ̀rọ̀ àti gbólóhùn tí ó wà nínú èdè kan kò níye. A ó ṣ e àkíyèsí pé ọmọ máa ń sọ àwọn gbólóhùn kan tí kò tíì gbọ́ rí. Tí èyí bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé kìí ṣe gbólóhùn tí ọmọ gbọ́ ni ó fi ń wé àwọn tí ó ti kó pamọ́ sí ibi kan nínú ọpọlọ rẹ̀. Ohun tí gbogbo eléyìí ń fi hàn ni pé òfin èdè tí ó ń gba ọmọ láyè láti ṣe àtinúdá gbólóhùn tirẹ ni ọmọ máa ń kọ́. Kò sí ẹni tí ó dá ọmọ gúnlẹ̀ tí ó ń kọ́ ọ ní òfin yìí. Níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé púpọ̀ nínú àwọn òbí ọmọ ni kò mọ̀-ón-kọ mọ̀-ọ́n-kà, wọn kò lè dá ọmọ gúnlẹ̀ kí wọ́n máa kọ́ ọ ní òfin yìí. Bí òbí tile jẹ́ ẹni tí ó mọ̀-ón-kọ mọ̀-ọ́n-kà, tí kìí báa ṣe onímọ̀ ẹ̀dá-èdè, ó lè má mọ òfin yìí. Eléyìí wá fi hàn pé ọmọ yìí wá dàbí onímọ̀ ẹ̀dá-èdè tí ó mọ̀ pé òfin gírámà kan wà. Ó dàbí onímọ̀ èdá-èdè tí ó mọ tíọ́rì èdè tí ó sì ń lò ó láti ṣe àtúpalẹ̀ gírámà èdè tí ó gbọ́. Ibi pẹlẹbẹ ni ọmọ yìí sì ti máa ń mú ọ̀ọ̀lẹ̀ jẹ nípa èdè kíkọ́. Fún àpẹẹrẹ, ní ẹ̀ka fonọ́lọ́jì, àfètèpè ni ọmọ kọ́kọ́ ń mọ̀ ṣáájú àfèrìgìpè; àsénupè ni ó kọ́kọ́ ń mọ̀ ṣáájú àfúnupè bẹ́ẹ̀ sì ni, ìró àìránmúpè ni ó kọ́kọ́ ń mọ̀ ṣáájú ìró àránmúpè, abbl.
Èdè Kíkọ́ (Language Acquisition)
Àwọn ẹ̀yà ara kan wà tí a ń pè ní ẹ̀ya ara ìfọ̀. Lóòótọ́, a máa ń lo àwọn ẹ̀yà ara wọ̀nyí láti ṣe nǹkan mìíràn bíi kí a fi ẹ̀dọ̀fóró ti afẹ́fẹ́ tí a fi ń mí jade tàbí kí a fi imú mí tàbí kí a fi ẹnu jẹun, síbẹ̀, a lè pe àwọn ẹ̀yà ara wọ̀nyí ní ẹ̀ya ara ìfọ̀ nítorí (i) ọmọ ń lo àwọn ẹ̀yà ara wọ̀nyí láti ṣe atátántóto kí ó tó di pé ó sọ̀rọ̀ gidi (ii) apá kan ọpọlọ wa tile wà tí ó ń bá àwọn ẹ̀ya ara wọ̀nyí ṣisẹ́ tí ó jẹ́ pé iṣẹ́ rẹ̀ kò ju bí a ṣe ń gbọ́rọ̀ àti bí a ṣe ń sọ ọ́ lọ. Tí ènìyàn bá ń lo ọwọ́ òsì, apá ọ̀tún ọpọlọ ni ibi tí ó ń ṣiṣẹ́ yìí wà. Tí ènìyàn bá ń lo ọwọ́ ọ̀tún, apá òsì ọpọlọ ni ni ibi tí ó ń ṣiṣẹ́ yìí wà. (iii) ènìyàn nìkan ni ó ń lo àwọn ẹ̀yà ara yìí fún ìfọ̀. Ìyẹn ni pé tí a kò bá tile pe àwọn ẹ̀ya ara yìí ní ẹ̀ya ara ìfọ̀ fún ẹranko àti ẹyẹ, a ò jayò pa tí a bá pè wọ́n ní ẹ̀ya ara ìfọ̀ fún ènìyàn.
Comments
Post a Comment