Ìfi-Àfòmọ́wájú Ṣẹ̀dá Ọ̀rọ̀-orúkọ nínú Èdè Yorùbá (Deriving Nouns in Yorùbá with the Use of Prefix)
Ìfi Àfòmọ́wájú Ṣẹ̀dá Ọ̀rọ̀-orúkọ nínú Èdè Yorùbá (Deriving Nouns in Yorùbá with the Use of Prefix)
Credit: Prof L. O. Adewole
Yoruba for academic purpose
Àbùdá
Ọ̀rọ̀ àti Àpínpẹ̀kun
Kí àlàyé wa lórí ìfiàfòmọ́wájú
ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ lè kún tó bí ó ti yẹ, a nílò láti wo àbá tí Cann
(1984) dá lórí abùdá ọ̀rọ̀ àti àpínpẹ̀kun[1].
Lójú Cann (1984), a lè pín ìsọ̀ri sí oríṣi mẹ́rin. Èkíní ni
ìsọrí tí ó jẹ àpínpẹ̀kun tí ó sì tún jẹ́ àpólà. A ó máa pe
eléyìí ní APX[2].
Èkejì ni ìsọ̀rí tí kì í ṣe ọ̀rọ̀ tí kì í sì i ṣe àpólà;
ìyẹn ni pé ó ju ọ̀rọ̀ lọ kò sì tó àpólà. Ìsọrí yìí kìí ṣe
àpínpẹ̀kun, kìí ṣe ọ̀rọ̀ kì í sì i ṣe àpólà. A ó máa pe
eléyìí ní XB. Ìkẹ́ta ni ìsọ̀rí tí kìí ṣe àpínpẹ̀kun tí ó sì
jẹ́ ọ̀rọ̀. A ó pe èyí ní XD. Ìkẹ́rin ni ìsọ̀rí tí ó jẹ́
àpínpẹ̀kun tí ó sì tún jẹ́ ọ̀rọ̀. Eléyìí ni XC. Bí àwọn ìpín
mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ṣe rí nì yí:
(1) (i) {<APÍNPẸ̀KUN, +>
<WÚNRẸN, ->} APX (ìsọ̀rí tí ó jẹ́ àpínpẹ̀kun ṣùgbọ́n tí
kìí ṣe wúnrẹ̀n kan soso, b.a. ‘bàtà Olú’).
(ii) {<APÍNPẸ̀KUN, -> <
WÚNRẸN, ->} XB (ìsọ̀rí tí kì i
ṣe àpínpẹ̀kun tí kìí ṣe
wúnrẹ̀n kan soso, b.a. ‘e Déle’ nínú ‘Ilée Délé’).
(iii) {<APÍNPẸ̀KUN, -> <
WÚNRẸN, +>} XD (ìsọ̀rí tí kì i ṣe àpínpẹ̀kun tí ó sì jẹ́
wúnrẹ̀n kan soso, b.a. ‘Dele’ nínú ‘Ilée Délé’).
(iv) {<APÍNPẸ̀KUN, +> <
WÚNRẸN, +>} XC (ìsọ̀rí tí ó jẹ́ àpínpẹ̀kun tí ó sì jẹ́ wúnrẹ̀n kan soso, b.a. ‘Olú’ nínú ‘Olú
lọ’).
Yàtọ̀ sí òfin ìsọ̀rí, Cann (1984)
tún dábàá òfin fún àwọn ọ̀rọ̀.
Òfin yìí ni ó wà ní (15):
(2) (i) [+Ọ̀RỌ̀, +ÌPÌLẸ̀] (Èyí ni
ọ̀rọ̀ tí a kò ṣẹ̀dá, bí àpẹẹrẹ, ‘lọ’) [+Ọ, +I][3]
(ii) [-Ọ̀RỌ̀, +ÌPÌLẸ̀] (Èyí ni
àfòmọ́, bí àpẹẹrẹ, ‘i’ nínú ‘ijó’) [-Ọ, +I]
(iii) [+Ọ̀RỌ̀, -ÌPÌLẸ̀] (Èyí ni
ọ̀rọ̀ tí a ṣẹ̀dá, bí àpẹẹrẹ, ‘ijó’) [+Ọ, -I]
(iv) [-Ọ̀RỌ̀, -ÌPÌLẸ̀] (Èyí ni
àtamọ́, bí àpẹẹre, SOO) [-Ọ, -I]
Ìtúpalẹ̀
Ijó
[OR[+Ọ, -I][OR[-Ọ, +I]
i][IṢC[IṢ[+Ọ, +I]
jó]]]
Àìlọ
(a) [OR[+Ọ, -I][OR[-Ọ,
+I] àì][ISC[IṢ[+Ọ,
+I] lọ]]] (bi) [OR[+Ọ, -I][OR[-Ọ,
+I] ì][ISC[IṢ[+Ọ,
+I] lọ]]] (bii) [OR[+Ọ,
-I][OR[-Ọ, +I] à] [OR[+Ọ,
-I][OR[-Ọ, +I] ì][ISC[IṢ[+Ọ,
+I] lọ]]]]
Àtilọ
(a) [OR[+Ọ, -I][OR[-Ọ,
+I] àti][ISC[IṢ[+Ọ,
+I] lọ]]] (b) [OR[+Ọ, -I][OR[-Ọ, +I]
à][ISX[WỌ[+Ọ, +I] ti][IṢ[+Ọ, +I] lọ]]]
Àboyún
(ai) [OR[+Ọ, -I][OR[-Ọ,
+I] o][IṢC[IṢ[+Ọ,
+I] yún]]]
(aii) [OR[+Ọ, -I][OR[-Ọ,
+I] àbi] [OR[+Ọ, -I][OR[-Ọ,
+I] o][IṢC[IṢ[+Ọ,
+I] yún]]]
(bi) [OR[+Ọ, -I][OR[-Ọ,
+I] o][IṢC[IṢ[+Ọ,
+I] yún]]]
(bii) [OR[+Ọ, -I][OR[-Ọ,
+I] à][ISX [IṢ[+Ọ,
+I] bi] [ORC[OR[+Ọ,
-I][OR[-Ọ, +I] o][IṢ[+Ọ,
+I] yún]]]]
Olóyún
(ai) [OR[+Ọ, -I][OR[-Ọ,
+I] o][IṢC[IṢ[+Ọ,
+I] yún]]]
(aii) [OR[+Ọ, -I][OR[-Ọ,
+I] oní] [OR[+Ọ, -I][OR[-Ọ,
+I] o][IṢC[IṢ[+Ọ,
+I] yún]]]
(bi) [OR[+Ọ, -I][OR[-Ọ,
+I] o][IṢC[IṢ[+Ọ,
+I] yún]]]
(bii) [OR[+Ọ, -I][OR[-Ọ,
+I] o][IṢX [IṢ[+Ọ,
+I] ní] [ORC[[OR[-Ọ,
+I] o][IṢ[+Ọ, +I] yún]]]]
Ońdè
(a) [OR[+Ọ, -I][OR[-Ọ,
+I] oń][ISC[IṢ[+Ọ,
+I] dè]]]
Onílé
[OR[+Ọ, -I][OR[-Ọ, +I]
oní][OR[+Ọ, +I] ilé]] (b) [OR[+Ọ, +I] o] [IṢX[IṢ[+Ọ, +I] ni][ORC[OR[+Ọ, +I] ilé]]]]
Alàgbà
[OR[+Ọ, -I][OR[-Ọ, +I]
oni][OR[+Ọ, +I] àgbà]] (b) [OR[+Ọ, +I][OR[-Ọ,
+I] o][IṢX[IṢ[+Ọ,
+I] ni][ORC[OR[+Ọ,
+I] àgbà]]]]
Àkójọpọ̀
Orúkọ Ìwé
Bamgbose, A. (1990), Fonoloji ati Girama Yoruba. Ibadan: UPL
Cann, R. (1984), ‘Heads without Bars: A
Theory of Phrase Structure’, An Unpublished Paper.
Cann, R. (1986), ‘The Structure of
Words’, Work in Progress 19: 107-121.
Edinburgh: Department of Linguistics, University of Edinburgh.
Owolabi, D.K.O. (1976), ‘Noun-Noun
Construction in Yoruba: A Syntactic and Semantic Analysis.’, PhD Dissertation,
University of Ibadan, Ibadan, Nigeria.
Owolabi, Kọla (1995), ‘More on Yorùbá Prefixing
Morphology’, in Language in Nigeria:
Essays in Honour of Ayọ Bamgboṣe edited by Kọla Owolabi, pp. 92-112.
Ibadan, Nigeria: Group Publishers.
Oyelaran, O.O. (1987) ‘Ọ̀nà Kan Ò
Wọjà: Mọfọ́lọ́jì Yorùbá’, Yoruba
1: 25-44.
Oyelaran, O.O. (1992), ‘The Category AUX
in the Yoruba Phrase Structure’, Research
in Yoruba Language and Literature 3: 59-86.
[1] Cann 1984. pe
eléyìí ní ‘lexical and maximal features’.
[2] ‘X’ dúró fún
ìsọ̀rí ọ̀rọ̀, bí àpẹẹrẹ, OR, IṢ, àbbl.
Comments
Post a Comment