IBÁ-ISELE ATẸRẸRẸ ÈDÈ YORÙBÁ
IBÁ-ISELE ATẸRẸRẸ ÈDÈ YORÙBÁ
Credit: Prof L. O. Adewole
Yoruba for academic purpose
1. ÌFÁÁRÀ
(1) Imperfective tí a lè pín sí habitual àti continuous tí a tún lè tún continuous
yìí pín sí non-progressive àti progressive
(2) Imperfective tí a lè pín si habitual àti progressive nìkan.
2.1 IBÁ ATẸ́RẸRẸ
Lójú
Freed (1979: 14) àti Dahl (1985: 91), ọ̀nà tí ibá atẹ́rẹrẹ máa ń
gbé ìṣẹ̀lẹ̀ jáde kì í ṣe ọ̀nà ti pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà gba àkókò nìkan
(durative and continuous) bí kò ṣe pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà ń lọ lọ́wọ́
(ongoing). Tí a bá fi ojú àbùdá tí àwọn méjì yìí ṣe àkíyèsí nípa ibá
yìí wò ó, a lè sọ pé ọ̀rọ̀ gírámà ti ó ń ṣe irú iṣẹ́ yìí ní èdè
Yorùbá ni n. Ọ̀rọ̀ yìí ní àdàpè máa tí a máa ń lò dípò rẹ̀
lẹ́yìn ọ̀rọ̀ tí ó ń fi múùdù han (modal verbs) àti nínú gbólóhùn àṣẹ
(imperative constructions). Àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ méjèèjì yìí nínú
gbólóhùn nì yí:
(3) (a) Mo ń na Adé
(b) Máa lọ báyìí
(d) Mo lè máa na Adé báyìí
Yàtọ̀ sí àwọn àpẹẹrẹ (3), Oyèláran (1982: 45), tún ṣe àlàyé pé ẹ̀dà ibá atẹ́rẹrẹ yìí kan máa ń wáyé sáájú n kan nínú gbólóhùn tó bá ní ọ̀rọ̀ tó ń fi múùdù hàn nínú (occurs “before (a certain n) in a modal construction”). Níwọ̀n ìgbà tí Oyèláran kò ti fún wa ní àpẹẹre. Kankan, ohun tí a rò ni pé àpapọ̀ máa àti n tí ó wà nínú gbólóhùn bí i ó máa ń jẹ ọ̀gẹ̀dẹ̀
ni ó ní láti ní lọ́kàn. Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, a ò rò pé a lè gba àbá yìí
wọlé. Ibi tí a fì sí yìí bá ti Ọ̀kẹ́ (1969: 440-449) mu Ọ̀kẹ́ ṣe àlàyé
púpọ̀ lórí ìdí tí ó fi yẹ kí á gba máa ń gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí ó ń fi ibá àṣeès.etán hàn nínú èdè Yorùbá.
Ọpọlọpọ òǹkọ̀wé ni kò gba ohun tí Ọ̀kẹ́ sọ yìí wọlé. Àlàyé tí wọ́n ń ṣe ni pé tí ó bá jẹ́ pé máa ń
ni ó dúró fún ibá àṣeèṣetán, kí ni ó dé tí ibá atẹ́rẹrẹ máa ń gba
iṣẹ́ rẹ̀ ṣe ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà? Fún àpẹẹrẹ, tí a bá sọ pé ó ń lọ,
a lè túmọ̀ rẹ̀ sí lílọ tí ó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ báìí tàbí ìlọ kan
tó máa ń wáyé. torí pé a lè lo ibá atẹ́rẹrẹ àti às.eès.etán sí ọ̀kan
náà2.
Ó
ṣòro fún wa láti fara mọ́ irú àlàyé tí àwọn òǹkọ̀wé yìí ṣe yìí. Ìdí
ni pé nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè ni ìlò ibá às.eès.etán àti ibá atẹ́rẹrẹ ti
máa ń wọnú ara ní ààyè kant àbí òmíran2 tí a kì í sì í torí èyí sọ
pé a ó pa ìsọ̀rí írámà méjèèjì yìí pọ̀ nínú àwọn èdè yìí. Mufwene
(1984: 41) pe irú ìlò ibá àṣeès.etán báyìí ní “the habituative
extension of the progressive”.
Àkíyèsí tí a tún ṣe ni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbólóhùn ni ó wà ní èdè Yorùbá nínú èyí tí ibá atẹ́re.rẹ àti biá àṣeèṣetán ti ta ko ara wọn. Fún àpẹẹrẹ, gbólóhùn (4a) yàtọ̀ sí (4b). Ìtumọ̀ wọn náà yàtọ̀ sí ara, a kò sì lè gbé ọ̀kan fún èkejì.
(4) (a) Kòkó ń gbẹ
(b) Kòkó máa ń gbẹ
Ọ̀pọ̀lọpọ̀
àpẹẹrẹ tó jọ irú èyí ni Ọ̀kẹ́ (1969: 440-448) tọ́ka sí. Ó ní àwọn
ọ̀rọ̀-ìṣe kan tilẹ̀ wà tí ó jẹ́ pé ọ̀kan nínú àwọn ìsò.rí gírámà
méjèèjì yìí ni wọ́n lè bá ṣe pọ̀. Díẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀-ìṣe tí ó tọ́ka
sí ni wá àti wà tí ibá atẹ́rẹrẹ kò lè saájú. Àwọn mìíràn ni bọ̀ àti bẹ tí a kò lè lo ibá àṣeèṣeán mọ́.
(5) (a) Ó máa ń wá
(b) Ó máa ń wà (ní ibẹ̀)
(d) Ó ń wá3
(e) Ó ń wà
(6) (a) Ó máa ń bọ̀
(b) Ó máa ń bẹ
(d) Ó ń bọ̀
(e) Ó ń bẹ
A ó ṣe àkíyèsí pé ohun tí ó jẹ ibá atẹ́rẹrẹ lógún
ni wí pé ìṣẹ̀lẹ̀ tí ọ̀rọ̀-ìṣe dúró fún ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ (ongoing)
Freed 1979: 14 àti Dahl 1985: 91). Ọ̀pọ̀ òǹkọ̀wé Yorùbá ni kò kọ ibi
ara sí àbùdá kan pàtàkì tí ó jẹ ibá atẹ́rẹrẹ lógún yìí. Ohun tí àwọn
òǹkọ̀wé yìí máa ń tẹnpẹlẹ mọ́ jù ni bí ìṣẹ̀lẹ̀ tí ọ̀rọ̀-ìṣe tí ó
tẹ̀lé ibá atẹ́rẹrẹ yìí ń tọ́ka sí ṣe pẹ́ to (durativity). Torí irú
èrò yìí ni Dahl (1985: 91) ṣe
ṣe àlàyé pé “The label ‘durative’ for PROG... is misleading in that it
gives the impression that PROG is used in contexts where duration of a
process is stressed”. Tí a bá sì wò ó náà, a ó rí i pé ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò
gba àsìkò lọ rẹ rẹ rẹ (punctual temproal reference) ni a máa ń fi
ibá atẹ́rẹrẹ tọ́ka sí. Fún àpẹẹrẹ, a lè lo ibá atẹ́rẹrẹ nínú
gbólóhùn bí i (7a) ṣùgbọ́n a kì í sábàá lò ó ní (7b). Dípò (7b), (7d)
ní a máa ń gbọ́. A sì tún lè gbọ́ (7e) náà.
(7) (a) Ní ìwòyí àná, ó sì ń na Olú
(b) Ó ń kọrun fún wákàtí mẹ́ta3
(d) Ó kọrin fún wákàtí mẹ́ta
(e) Ó máa ń kọrin fún wákàtí mẹ́ta.
A ó ṣe àkíyèsí pé ẹ̀yánrọ̀-ìṣe, wákàtí mẹ́ta,
tí ó wà nínú gbólóhùn (7b) ni ibá atẹ́rẹrẹ kò lè bá ṣe pọ̀ tí a kì í
fi í sábàá sọ irú ìpèdè yẹn. Àìlè bá irú ẹ̀yánrọ̀-is.e yìí ṣe pọ̀
yẹ kí ó jẹ́ ìdí pàtàkì mìíràn
tí ó fi yẹ kí á ya ìsọ̀rí gírámà ibá atẹ́rẹrẹ sọ́tọ̀ sí ibá
àṣeès.etán nítorí ibá atẹ́rẹrẹ tí ẹ̀yánrọ̀-ìṣe kan kò lè bá ṣe pọ̀
ni (7b) ni ibá àṣeès.etán bá ṣe pọ̀ ní (7e).
Tí
a bá wo gbogbo àlàyé tí a ṣe sókè yìí, ìbéèrè tí yóò wá sí wa lọ́kàn
ni pé kí ni ó fà á tí ẹnu òǹkọ̀wé Yorùbá kò fi kò lórí wí pé ó yẹ kí
ibá àṣeèṣetán tí ó yàtọ̀ sí ibá atẹ́rẹrẹ wà ní èdè Yorùbá. Nǹkan
tí a rò pé ó fa àìkò ẹnu yìí ni ẹ̀dà kan náà tí àwọn ìsọ̀rí gírámà
méjèèjì yìí máa ń sábàá ní. Fún àpẹẹrẹ, tí a ba wo gbólóhùn (8), a
lè sọ pé ó níí ṣe pẹ̀lú ibá atẹ́re.rẹ àti ibá aṣeès.etán ṣùgbọ́n tí
a bá wo ìyisódì rẹ̀ níbi tí (9a) ti jẹ́ ìyísódì fún ibá atẹ́rẹrẹ tí
(9b) sì jẹ́ ìyísódì fún ibá às.eès.etán ni a ó rí i pé àmì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni
a lò fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn.
(8) Máa ṣe é
(9) (a) Má ṣe é
(b) Má máa ṣe é
Ọ̀pọ̀lọpọ̀
òǹkọ̀wé tí kò ṣe àkíyèsí àwọn àpẹẹrẹ tí a tọ́ka sí lókè yìí ni ó
máa ń sọ pé ẹ̀dà n tí ó dúró fún ibá atẹ́rẹrẹ ni maa n. A lérò pé
àlàyé tí a ṣe sókè yìí yóò jẹ́ kí a gbà pé èdè Yorùbá nílò ibá
àṣeèṣetán tí ó yàtọ̀ sí ibá atẹ́rẹrẹ.
2.2 ÌYÍPADÀ ÀÌYÍPADÀ4 (DYNAMIC- STATIVE)
Àbùdá kan tí a tún máa ń
tọ́ka sí nípa ibá atẹ́rẹrẹ ni àbùdá tí a lè pè ní ìyípadà
(non-stativity feature). Ohun tí èyí fi yé wa ni pé ìlò ibá atẹ́rẹrẹ
nínú gbólóhùn máa ń dá lé irú ọ̀rọ̀-ìṣe tí a fẹ́ lò ó mọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀
àbá náà ló ti wà nílẹ̀ lórí ìlò ọ̀rọ̀-ìṣe mọ ibá atẹ́rẹrẹ báyìí.
Lójú púpọ̀ nínú àwọn òǹkọ̀wé Yorùbá, ọ̀rọ̀-ìṣe bá lè yí padà (dynamic
verb) nìkan ni ibá atẹ́rẹrẹ máa ń bá ṣe. Àbá Ajéígbé (1979: 16)
nìkan ni ó fẹ́rẹ̀ yàtọ̀ díẹ̀. Lójú rẹ̀ gbogbo àmì tó dúró fún àsìkò
(tense) nínú èdè Yorùbá ni ó lè bá àwọn ọ̀rọ̀-ìṣe tí kì í yí padà
(stative verb) ṣe. Àpẹẹrẹ tí ó fúnw à níwọ̀nyí.
(10) (a) Adé ti burú ṣùgbọ́n kò burú mọ́
(b) Òjó yóò ga tó Adé ní ọdún yí.
Níwọ̀n
ìgbà tí Ajéígbé kò ti ṣàlàyé bóyá ara àwọn ìsọ̀rí gírámà tí ó tò mọ́
àsìkò ni ibá atẹ́rẹrẹ wà, ibi tí ó fi sí nípa àjọ-ṣe-pọ̀ ibá yìí àti
ọ̀rọ̀-ìṣe kò yé wa.
Lójú
Oyèláran (1982: 37), kò sí tàbí ṣùgbọ́n, ohun tí ó fara mọ́ ni pé ibá
atẹ́rẹrẹ kò lè bá ọ̀rọ̀-ìṣe tí kì í yí padà ṣe pọ̀. Tí a bá rí ibá
atẹ́rẹrẹ ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀rọ̀-ìṣe tí kì í yí padà nínú gbólóhùn, ohun tí
Oyèláran (1982: 37) sọ nípa rẹ̀ ni pé “the only permissible reading is
iteration, since reference to situation-internal time would be
nonsensical”.
Lákọ̀ọ́kọ́
ná, níwọ̀n ìgbà tí Oyèláran kò ti fún wa lápẹrẹ ohun tí ó pè ní
“iteration” àti “situation-internal time”, ó yẹ kí á tọ́ka sí irú
àpẹẹrẹ yìí bí ó s.e yé wa sí. Ohun tí ó ya (11a) sọ́tọ̀ sí (11b) ni
pé a ṣe “iteration” ìyẹn àtẹ̀mọ́ ní (11a) tí a sì tọ́ka sí ohun tí ó
ń sẹlẹ̀ lọ́wọ́ (situation-internal time”) ni (11b).
(11) (a) Ó lọ lọ lọ (kò dé)
(b) Ó ń lọ
Lóòótọ́,
a gba ohun tí Oyèláran sọ pé ibá atẹ́rẹrẹ lè wà pẹ̀lú ọ̀rọ̀-ìṣe tí
kì í yí padà nínú gbólóhùn kí a sì fún ọ̀rọ̀-ìṣe náà ní ìtumọ̀ àtẹ̀mọ́
bí i ti (11a) ṣùgbọ́n a tún ṣe àkíyèsí pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni a lè tọ́ka sí
ohun tí ń sẹlẹ̀ lọ́wọ́ bí i ti (11b). Tí a bá wo gbólóhùn (12), yàtọ̀
sí pé a lè fún ọ̀rọ̀-ìṣe inú wọn ní ìtumọ̀ àtẹ̀mọ́, a ó ṣe àkíyèsí pé
a tún ń fọkàn sí àbùdá tàbí àdámọ́ àwọn ọ̀rọ̀-ìṣe yìí tí ó jọ ti ọ̀rọ̀-ìṣe tí ó ń yá padà.
(12) (a) Mo ń gbọ́n sí i
(b) Mo ń gbọ́ Yoùbá sí i
(d) Ó ń jọ bàbá rẹ̀ sí i lójoojúmọ́
Gbogbo
ọ̀rọ̀-ìṣe yìí ni a ń ṣe àkíyèsí pé wọ́n ń yí padà. ti pé a ń rí
àyípadà ìṣẹ̀lẹ̀ nìkan kọ́, a ń rí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí gan an bí ó ṣe ń yí
padà ni síṣẹ̀-n-tẹ̀lé. Ọ̀rọ̀-ìṣe gbọn, gbọ́ àti jọ wá di ohun tí a rí ti ó ń yí padà láti ipò kan sí ipò mìíràn.
Àlàyé
tí Mufwene (1984: 35) ṣe nípa ibá atẹ́rẹrẹ bá àkíyèsí tí a ṣe sókè
yìí mu. Ó pe ibá atẹ́rẹrẹ ní oríṣìí ẹ̀yán kan tí ó máa ń ṣe iṣẹ́
wọ̀nyí:
(13) (a) converts events expected to be punctual into longer-lasting, even if trasient, stats of affaris.
(b) conversely
converts those states of affairs expected to last long “lexical
statives) to shorter-lasting/transient states of affairs.
(c) simply
presents those verbs whose denotations are neutal with regards to
duration as in process/in (transient) duration, though duration is
expected of statives.
Àkíyèsí tí a ṣe lókè yìí ni ó jẹ́ kí á gbà pé lóòótọ́, ọ̀rọ̀-ìṣe tó bá
ń yí padà ni ó rọ ibá atẹ́rẹrẹ lọ́run lati bá ṣe pọ̀, èyí kò sọ
pé kì í bá èyí tí kì í yí padà náà ṣe. Tí àjọṣepọ̀ bá wà láàrin ibá
atẹ́rẹrẹ àti ọ̀rọ̀-ìṣe tí kì í yí padà, ipò ọ̀rọ̀-ìṣe tí ó ń yí
padà ni a ó to àwọn ọ̀rọ̀-ìṣe yìí sí.
2.3 IBÁ ATẸ́RẸRẸ NÍNÚ GBÓLÓHÙN ÀṢẸ
Ó
yẹ kí á mẹ́nu ba ìhùwàsí ibá atẹ́rẹrẹ nínú gbólóhùn àṣẹ. Yàtọ̀ sí
ìtumọ̀ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ tí a máa ń fún gbólóhùn àṣẹ, ìtumọ̀ tó jẹ
mọ́ ibá atẹ́rẹrẹ nìkan ni ó tún kù tí a lè fún gbólóhùn yìí. Ìyẹn ni
pé tí a bá pe ìpèdè yìí Lọ wò ọ́ ohun tí yóò yé
wa sí ni pé a ní kí ẹni tí a ń bá sọ̀rọ̀ lọ wo ẹnì kan báyìí tàbí
kí ó lọ wò ó lẹ́hìn ìgbà tí a sọ̀rọ̀ yẹn. Ìtumọ̀ tó jẹ mọ́ ibá
atẹ́rẹrẹ tí a máa ń fún gbólóhùn àṣẹ yìí ni kì i sábàá jẹ́ kí á lo
ibá atẹ́rẹrẹ nínú gbólóhùn àṣẹ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè. Èdè Yorùbá
yàtọ̀ sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè mìíràn nípa ìlò ibá atẹ́rẹrẹ nínú gbólóhùn
àṣẹ. Ẹ jẹ́ kí a wo àwọn gbólóhùn àṣẹ tí kò ní ibá atẹ́rẹrẹ yìí
àti ẹgbẹ́ wọn tí ó ní in:
(14) (a) Lọ
(b) Máa lọ
(15) (a) Jẹun
(b) Máa jẹun
(16) (a) Sùn
(b) Máa sùn
Gbogbo
gbólóhùn àṣẹ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí kò ní ibá atẹ́rẹrẹ nínú ni a rí ẹgbẹ́
wọn tí ó ní ibá atẹ́rẹrẹ. Ọ̀nà méjì ni a lè gbà sàlàyé wíwọ́pọ̀ tí
ibá atẹ́rẹrẹ wọ́pọ̀ nínú gbólóhùn àṣẹ èdè Yorùbá. Lọ́nà kìíní, àwọn
ọ̀rọ̀-ìṣe kan wà tí a kò l2 lò wọ́n láìjẹ́ pé a lo ibá atẹrẹrẹ mọ́
wọn. Ìyẹn ni pé inú gbólóhùn kí gbólóhùn tí a bá ti lo àwọn ọ̀rọ̀-ìṣe wọ̀nyí yálà gbólohùn àlàyé ni o tàbí ti àṣẹ tàbí ti ìbéèrè,ibá arẹ́rẹrẹ àti ọ̀rọ̀-ìṣe wọ̀nyí gbọ́dọ̀ jọ wà pọ̀ ni.
(17) ÀLÀYÉ
(a) Mo ń bọ̀
(b) Mo bọ̀
(18) ÌBÉÈRÈ
(a) Ṣé o ń bọ̀?
(b) Ṣé o bọ̀
(19) ÀṢẸ
(a) Máa bọ̀
(b) bọ̀
Ìdí
pàtàkì kejì ni pé gẹ́gẹ́ bí ìhùwàsí ibá atẹ́rẹrẹ nínú gbólóhùn àlàyé,
nínú gbólóhùn àṣẹ náà, ó máa ń tọ́ka sí pé kí ìṣẹ̀lẹ̀ ti máa lọ
lọ́wọ́ ní àkókò kan.
(20) (a) Sọ ọ́ kí n tó dé
(b) Máa sọ ọ́ kí n tó dé
Irú ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń sẹlẹ̀ lọ́wọ́ tí a ṣe àkíyèsí ní (20b) kò sí ní (20a).
2.4 ÌYÍSÓDÌ IBÁ ATẸ́RẸRẸ
Ibá
atẹ́rẹrẹ ṣòro lati yí sodì ní èdè Yorùbá. Ìyẹn ni pé tí a bá rí
gbólóhùn bú (21a) tí a lè fi èdè lójíìkì (formal language) kọ ní (21b),
ọ̀nà ìyísódì tó wà fún wa ni pé kí á yí ẹni tó ń fò yẹn sódì wí pé
kò fò tàbí kí á yí ìfò yẹn gan an sódì pé kì í ṣe ìfò ló ń fò, nǹkan
mìíràn ni ó ń ṣe. Tí a bá ní kí á yí ibá atẹ́rẹrẹ inú gbólóhùn yìí sódì, ọ̀nà tí a lè lò ni (21d).
(21) (a) Ó ń fò
(b) Ibá Atẹ́rẹrẹ (Fò (òun)5
(d) Kì í ṣe pé ó ń fò lọ́wọ́ báyìí ṣùgbọ́n ó ti parí ìfò fífò6
Ọ̀nà
kan tí Moravcsik (1982: 96-99) ṣe àkíyèsí pé a fi lè yọ nínú irú
wàhálà àwítúnwí (awkward circumlocution) tí a ṣe ni (21d), ni pé kí á
fi ojú àpólà gbólóhùn wo ìyísódì tí a fẹ́ ṣe kí á sì yí ibá atẹ́rẹrẹ
sódì pẹ̀lú àpólà ìṣe tí ó tẹ̀ lé e7. Tí a bá fi ojú èyí wò ó, ìyísódì (21a) ni (22a) tí èdè lọjíìkì (formal language) rẹ̀ kì í ṣe (21b) ṣùgbọ́n (22d).
(22) (a) Kò fò
(b) -Ex (x ń lọ lọ́wọ́, àti pé x kì í ṣe ìfò tí ó ń fò)8
(d) Ex (x ń lọ lọ́wọ́, àti pé x kọ́ nì ìfò tí Ó ń fò)9
Tí
(22d) bá jẹ́ èdè lọ́jíìkì (formal language) ìyísódì (21a), a jẹ pé a
lè sọ pé (21a) jẹ́ òótọ́ tí ó bá jẹ́ pé ní àkókò tí a ní lọ́kàn, ń ṣe
ni e.ni tí a ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ń ṣe nǹkan mìíràn lọ́wọ́, kò fò10.
A ṣe àkíyèsí pé kò sí ìyàtọ̀ kankan láàrin ìyísódì ibá às.etán (perfective) àti ibá atẹ́rẹrẹ. Wo (23).
(23) (a) Ó fò
(b) Kò fò
Ohun tí ó fa èyí ni àkíyèsí tí given (1978: 97)11 ṣe pé àmì tí ó ń fi ibá àti àsìkò hàn máa ń pọ̀ ní gbólóhùn àlàyé ju gbólóhùn ẹ̀kọ̀ lọ.
3. ÌSỌNÍSÓKÍ
Nínú
àròkọ yìí, a gbìyànjú láit fi hàn pé ó yẹ kí á ní ìsọ̀rí gírámà ibá
atẹ́rẹrẹ àti ibá àṣeèṣetán ní èdè Yorùbá. A tún ṣàlàyé iṣẹ́ tí ibá
atẹ́re.rẹ ń ṣe tí òun àti ọ̀rọ̀-ìṣe tí kì í yí padà bá jọ wà nínú
gbólóhùn. a wá sọ ìdí tí ibá atẹ́rẹrẹ fi wọ́pọ̀ ní èdè Yorùbá kí a tó
fi ìyísódì ibá atẹ́rẹrẹ kádìí ọ̀rọ̀ wa.
ÌTỌSẸ̀ Ọ̀RỌ̀
1. Àwa la fún ibá yìí ní orúkọ yìí.
2. Wo Awóùlúyì (1967: 263-264) àti Awóyalé (1974: 18) fún àpẹẹre.
3. A lè gba gbólóhùn yìí wọlé tí a bá wo n tí ó wá nínú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àdàpè fún máa n, ibá àṣeèṣetán.
4. Àwa la túmọ̀ Gẹ̀ẹ́sì méjì yìí sí Yorùbá
5. Ní Gẹ̀ẹ́sì, ó jẹ́ “PROG (Jump (He)”.
6. Ní Gẹ̀ẹ́sì, ó jẹ́ “It is not the case that he is jumping now, but that he has completed jumping”.
7. Ní
Gẹ̀ẹ́sì, ó jẹ́ “To interpret negation with aspect on the subsential
level and apply negation inside the PROG operator, directly to the VP”.
8. Ní Gẹ̀ẹ́sì, -Ex (x is in progress, and x is a jump by Him).
9. Ní Gẹ̀ẹ́sì, Ex (x is in progress, and x is not a jump by Him).
10. Ní Gẹ̀ẹ́sì: “If and only if at the point or interval of evalaution, the agent is not jumping but doing something else”.
11. Ohun
tí ó sọ gan an: “tense-aspect in affirmative is almost always alrger –
but never smaller – than in the negative. Thus languages tend to
innovate more tense-aspectual elaboration in the affirmative, and only
slowly do these innovation spread into the negative”.
Comments
Post a Comment