Ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ Àṣetán àti Àsìkò Ọjó-iwájú nínú Ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú àti Olórí Ẹ̀ka-èdè Yorùbá

 

Ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ Àṣetán àti Àsìkò Ọjó-iwájú nínú Ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú àti Olórí Ẹ̀ka-èdè Yorùbá


Atọ́ka[1] ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àṣetán ni ti nínú ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú nígbà tí ó bá bá á tí ó jẹ́ atọ́ka àsìkò ọjọ́-iwájú jẹ yọ. Àpẹẹrẹ tí a lè lò fún ìjẹyọpọ̀ atọ́ka àsìkò ọjọ́-iwájú àti ibá-ìs.ẹ̀lẹ̀ àṣetán ni Títí á ti lọ..

 

Ti ni ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú àti olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá ń lò gẹ́gẹ́ bí atọ́ka fún ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àṣetan. Àwọn méjèèjì náà ni wọ́n ń lo á gẹ́gẹ́ bí atọ́ka fún àsìkò ọjọ́-iwájú ṣùgbọ́n á ti olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá tún ní ẹ̀dà. Ẹ̀dà náà ni máa. Tí a bá lo máa yìí nínú olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá, máa ń ṣáájú máa ni. Àwọn àpẹẹrẹ tí a lò fún ìjẹyọpọ̀ ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àṣetán àti àsìkò ọjọ́-iwájú nínú olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá ni Olú á ti lọ àti Olú ti máa lọ[2].

 

Nínú gbólóhùn àyísódì tí ó ní ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àṣetán àti àsìkò ọj-iwájú nínú, ì ni atọ́ka ìyísódì ninú ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú; níí ni atọ́ka àsìkò ọjọ́-iwájú nígbà tí atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àṣetán jẹ́ mófíìmì òfo. Eléyìí wáyé nínú Títí ì níí lọ. Ẹ̀dà kan fún atọ́ka ìyísódì nínú gbólóhùn tí ó ní ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àṣetán àti àsìkò ọjọ́-iwájú nínú ẹ̀ka-èdè yìí. Tí bá jẹ́ atọ́ka ìyísódì, ẹ̀dà atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àṣetán tí ó máa ń bá rìn ni tíì. Àwọn méjèèjì yìí sí máa ń bá níí rìn gẹ́gẹ́ bí ó ṣe hàn nínú Títí mà tíì níí lọ. Atọ́ká ìyísódì tún ní èdè mìíràn nínú gbólóhùn àyísódì tí ó ni atọ́ka ibá-àṣetán àti àsìkò ọjọ́-iwájú nínú nínú ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú. Atọ́ka yìí ni màà gẹ́gẹ́ bí ó ṣe hàn nínú Títí màà tíì níí lọ.

 

Ní ibi tí ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú ti ń lo ì, mà àti màà fún atọ́ka ìyísódì nínú gbólóhùn tí ìyísódì ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àṣetán àti àsìkò ọjọ́-iwájú ti wáyé, ni olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá ń lò. Nínú irú gbólóhùn yìí ní ibi tí ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú ti ń lo tíì àti mọ́fíìmù òfo fún atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àṣetán, olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá ń lo ì, ìtíì àti tíì. Níí ni àwọn ẹ̀ka-èdè méjèèjì ń lò fún atọ́ka àsìkò ọjọ́-iwájú. Àpẹẹrẹ àwọn gbólóhùn olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá tí ó fi èyí hàn ni Títí kò ì níí lọ, Títí kò ìtíì níí lọ àti Títí kò tíì níí lọ.



[1] Kujore, O.I. ni ó kọ bébà yìí.
[2] Wo A. Bamgboṣe (1990: 170), Fonọ́lọ́jì àti Gírámà Yorùbá. Ibadan, Nigeria: University Press PLC. Ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àṣetán ìparí nìkan ni a yẹ̀ wò nínú iṣẹ́ yìí.

Comments

Popular posts from this blog

YORÙBÁ LITERATURE E-LIBRARY

SYNTAX AND GRAMMATICAL THEORIES E-LIBRARY SECTION

YORÙBÁ GRAMMAR E-LIBRARY SECTION