HAVE

 

Have


Do you ever have headache? - Ǹjẹ́ orí ti fọ́ ẹ rí?

Do you have a meeting today – Ṣé ẹ ní ìpàdé lónìí?

Do you have to shout? – Ṣé dandan ni pé kí o pariwo ni?

Does your father have black hair? No, he’s got grey hair – Ṣé irun dúdú ni baba rẹ ní? Rárá, irun funfun ni ó ní.

Everyone thinks he has it in him to produce a good work – Gbogbo ènìyàn ni ó ń rò pé gbogbo ohun tí ènìyàn fi lè ṣe iṣé tí ó dára ni ó ní lára.

Have we got enough food in? – Ṣé a ti ní oúnjẹ tí ó tó nínú ilé?

Have you got the time to call him? – Ṣé o ti ráyè pè é?

He had her in his office – Ó bá a ní ìbálòpọ̀ nínú ọọ́fíìsì rẹ̀.

He had his audience listen attentively – Ó jẹ́ kí àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fetí sílẹ̀ dáadáa.

He had his back to me – Ó kọ ẹ̀yìn sí mi.

He had his bag stolen – Wọ́n jí i ní báàgì.

He had nothing on – Kò wọ aṣọ Kankan sọ́rùn.

He had the strong impression that someone was watching him – Ó ní èrò tí ó ga lọ́kàn pé ẹni kan ń wo òun.

He has his head in his hands – Orí rẹ̀ wà ní ọwọ́ rẹ̀.

He has some friends with her – Àwọn ọ̀rẹ́ kan wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀.

He was had up for armed robbery – Wọ́n fi ẹ̀sùn ìfipájalè kàn án ní ilé-ẹjọ́.

He’ll have an accident one day – Ọjọ́ kan ń bọ̀ tí yóò kó sí inú ìjàǹbá.

He’s always having the builders in to do something or other – Ìgbà gbogbo ni ó máa ń pe àwọn ọ̀mọ̀lé wale láti wáá bá a ṣe nǹkan kan tàbí òmíràn.

He’s got a BA in Yorùbá - Ó ti gba BA nínú Yorùbá.

He’s got three children - Ó ní ọmọ mẹ́ta.

His paintings had a strong influence on me as a student – Àwọn nǹkan tí ó kùn kó ipa tí ó lágbára lórí mi nígbà tí mo jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́.

I am afraid you’ve been had – Kí a sọ òótọ́ kó, wọ́n ti rí ẹ mú.

I can’t see you this week - I’ve a lot on  – N kò lè rí ọ lọ́sẹ̀ yìí - àwọn ohun tí mo fẹ́ẹ́ ṣe pọ̀.

I had a cigarette while I was waiting – Mo mu sìgá kan níbi tí mo ti ń dúró.

I had a letter from my brother this morning – Mo rí lẹ́tà kan gbà láti ọ̀dọ̀ ẹgbọ́n mi ọkùnrin/àbúrò mi ọkùnrin ní àárọ̀ yìí.

I had a swim to cool down – Mo lúwẹ̀ẹ́ kí ara mi lè wálẹ.

I had to have part of my kidney out – Wọ́n ní láti gé apá kan kíndìnrín mi.

I have finished my work – Mo ti pari iṣẹ́ mi.

I have got a lot of homework tonight – Mo ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àṣetiléwá lálẹ́ òní.

I have no objection to your request – N kò ní àtakò kankan sí ohun tí o bèèrè fún.

I need to have it out with him once and for all – Mo ní láti fi ìdí ọ̀rọ̀ èmi rẹ̀ tì síbì kan lójú ọ̀gbagada.

I tried to persuade him to wait but he wasn’t having any – Mo rọ̀ ọ́ láti jẹ́ kí ó dúró ṣùgbọ́n kò fẹ́ẹ́ gbọ́.

I’m not worried - they’ve got nothing on me – Àyà kò fò mí - wọn kò bá nǹkan kan lọ́wọ́ mi.

I’m sorry, I haven’t a clue – Jọ̀wọ́ máà bínú o, n kò ní ojútùú kankan tí mo lè dá lábàá fún ọ̀rọ̀ náà.

I’ve got a headache – Orí ń fọ́ mi.

I’ve got to go – Mo gbọ́dọ̀ máa lọ.

I’ve had it (up to here) with him – he’s done it once too often – Ó ti tì mí dé ibi tí ó ti sú mi – ìgbà gbogbo ní ó máa ń ṣe é.

I’ve had it! I’m going to bed – Ó ti rẹ̀ mí gan-an! Mó ń lọ sùn.

It was no surprise when she left him – everyone knew he had it coming to him – Kò ya ẹnikẹ́ni lẹ́nu nígbà tí ó fi i sílẹ̀ – gbogbo ènìyàn ni ó ti mọ̀ pé ó pẹ́, ó yá, yóò lọ.

Let’s have a meeting – Ẹ jẹ́ kí a ṣe ìpàdé.

Let’s have done with this silly argument – Jẹ́ kí á mú ìjara-ẹni-níyàn tí kò mọ́gbọ́n lọ́wọ́ yìí wá sí òpin.

Rumour has it that we’ll have a new manager soon – Àwọn tí ó ń sọ àríìrísọ ti sọ wí pé à kò níí pẹ́ ní ọ̀gà tuntun.

She has his TV on then – Ó tan iná tẹ́lì rẹ̀ sílẹ̀ ni nígbà yẹn.

She’s is going to have a baby – Ó ti fẹ́ẹ́ bímọ.

The car had had it – Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà ti bàjẹ́ pátápátá.

The society has 50 members - Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà jẹ́ àádọta.

The war has got to end soon – Ogun náà gbọ́dọ̀ parí láìpẹ́.

There is a great division between the haves and the have-nots – Ìpínyà tí ó ga ni ó wà ní ààrin àwọn tí ó ní àti àwọn tí kò ní.

There’s room in the backyard to store chairs and what have you – Àyè wà ní ẹ̀yìnkùlé láti ṣe àga àti àwọn nǹkan mìíràn lọ́jọ̀ sí.

They have a lot of courage - Wọ́n ní ìgboyà tí ó ga.

We can’t have people arriving late all the time – A kò lè máa gba àwọn ènìyàn láyè láti máa pẹ́ẹ́ dé ní ìgbà gbogbo

We had some friends to dinner last night – Àwọn ọ̀rẹ́ wa kan wá bá wa jẹun lálẹ́ àná.

We have a duty to care for the poor – Iṣẹ́ wa ni láti tọ́jú àwọn aláìní.

We have orders coming in from all over the world – Gbogbo ayé ni wọ́n ti ń bèèrè fún nǹkan tí a ń tà.

We haven’t got a television – A kò tíì ní tẹlifísàn.

What have you got against Adé? He’s always been good to you – Kí ni o sọ pé Adé ṣe? Ó sì máa ń hùwà dáadáa sí ẹ nígbà gbogbo.

When the car smashed into him, he thought he’d had it – Nígbà tí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà gbá a, ó rò pé ó ti parí fún òun.

Who can we have as treasurer – Ta ni kí á yàn ní akápò?

You can have your book back after I’ve read it – O lè gba ìwé rẹ padà tí mo bá kà á tán.

You have to get a new job – O gbọ́dọ̀ wá iṣẹ́ tuntun.

You’re not having me on, are you? – Kìí ṣe pé o ń gbé mi ṣeré, àbí o ń gbé mi ṣeré ni?

You’ve got me there. I hadn’t thought of that – O ti rí mi mú níbẹ̀ yẹn. N ò tíì ronú nípa ìyẹn.

You’ve had your hair cut – O ti gé iru rẹ.

Reference

A.S. Hornby (2001), Oxford Advanced Leaner’s Dictionary of Current English, edited by Sally Wehmeir. Oxford: Oxford University Press.

Comments

Popular posts from this blog

YORÙBÁ LITERATURE E-LIBRARY

SYNTAX AND GRAMMATICAL THEORIES E-LIBRARY SECTION

YORÙBÁ GRAMMAR E-LIBRARY SECTION