Gbólóhùn Àsínpò Ìse Yorùbá
Gbólóhùn Àsínpò Ìse Yorùbá
Àbá méta la ó ye wò lórí gbólógùn àsínpò ìse Yorùbá. Ní ti àbá kìíní, gbólóhùn méjì ló máa ń wà ìpìlè gbólóhùn àsínpò ìse. Ìyen ni pé tí a bá rí ‘Mo ra isu tà’, ‘Mo ra isu, Mo ta isu’ ló wà ní ìhun ìpìlè rè. Àbá kejì gbà pé òótó ni a rí gbólóhùn àsínpò ìse tí ó ní gbólóhùn méjì ní ìhun ìpìlè èyí tí a lè pè ní gbólóhùn àsínpò ìse áláso (the co-ordinate type). Àpeere iru èyí ni ‘Mo ra isu tà’, Àbá yìí wòye pé àwon kan wà tí a kò lè topa lo sí gbólóhùn méjì, fún àpeere, ‘Obè dùn tó; tí a kò lè so pé ‘Obè dùn, Obè tó’ ni ìpìlè rè. Irú àpeere yìí ni àbá kejì yìí pè ní ‘the modifying type’. Àbá yìí rò pé isé èyán ni ‘tó’ ń se nínú ‘Obè dùn tó’. Àbá kìíní wòye pé báwo ni ó ṣe ṣeé se pé nínú ‘Obè tó’ ‘tó’ je òrò-ìse kíkún sùgbón nínú ‘Obè dùn tó’, ‘tó’ wá di òrò-ìse èyán. Àbá yìí ní òun kò fara mó on. Àbá kẹta tí ó wà lórí gbólóhùn àsínpò ìse ní tire ní a kò lè topa gbólóhùn àsínpò ìse lo sí ìhun ìpìlè mìíràn. Bíi àpólà ìse inú gbólóhùn abode ni àpólà ìse (APIṢ) rè se máa ń hùwà. Fún àpeere, bákan náa ni a se máa ń yí APIṢ rè àti ti gbólóhùn abode sódì, ba: ‘mo lo/nkò lo, mo ra isu tà/n kò ra isu tà’ kìí se ‘n kò ra isu, n kò ta isu’. Ibá kan náà ni wón jo ń gbà bíi ti gbólóhùn abode, ba: ‘ó ti sùn lo’ kì í se ‘*ó ti sùn, ó ti lo’, òna kan náa ni a fi máa ń se àpètúnpè elébe fún ìsodorúko won bíi ti gbólóhùn abode, ba: ‘lílo ni ó lo’, ‘rírasu ni ó rasu tà/ríra ni ó rasu tà/rírasutà ni ó rasu tà’, kì í se ‘*rírà títà ni ó rasu tà’. Àpapò àwon òrò ìse méjèèjì ni o m;aa ń yan olùwà àti àbò bí ti IṢ inú gbólóhùn abode. Fún àpeere, ‘mú’ tàbí ‘wá’ kò lè gba ‘òrò’ (ìyen òrò tí a so jáde lénu) ní olùwà won nítorí ìdí èyí ni a kò se lè so pé ‘*òrò wá’ ‘*òrò mú un’, sùgbón apapò ‘mú’àti ‘wá’ lè yan ‘òrò’ ní olùwà nínú gbólóhùn àsínpò ìse, ba: ‘òrò náà mú mi wálé’. Bákan náa, àwon IṢ méèjèèjì inú àsínpò ìse ni ó máa ń yan àbò won. Fún àpeere, ‘rò’ tàbí ‘pin’ kò lè dá yan ‘wá’gégé bí àbò, èyí ni a kò se lè rí ‘*wón rò wá’ tàbí ‘*wón pin wá’ sùgbón, a lè rí ‘wón rò wá pin’ níbi tí àwon IṢ méjèèjì ti jo yan ‘wá’ ní àbọ̀ won. Bí a ṣe ń ṣe ìtẹnumọ́ IṢ nínú gbólóhùn abọde náà ni a ń se ìtẹnumọ́ ÌṢ wọn, ba: bí a se lè sọ pé ‘esín ta ta ta (ó kú)’ béè náà ni a lè so pé ‘ó raṣu ta, raṣu tà, raṣu ta (kò jèrè)’. Àwon IṢ méjèèjì ni a fi máa ń dáhùn ìbéèrè, ba: tí a bá so pé ‘ó mumi yó’, tí eni kan bá bèèrè pé kí ló se?’, a ó ní ‘ó mumi yó’, a kò níí so pé ‘*ó mumi, ó yó’. Àwon IṢ méjèèjì la máa ń yán papò kì í se eyo kan nínú won, ba: ó mumi yó ní àárọ̀. Nítorí gbogbo ìdí wònyí, àbá kẹta yìí so pé a kò nílò láti topa ìpìlè gbólóhùn àsínpò ìse lo síbì kankan. Bí àpólà ise inú gbólóhùn abódé se máa ń hùwà ni àpólà ise tirè náa se máa ń hùwà.
Comments
Post a Comment