Ẹ̀yán Aṣàfihàn nínú Ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀
Ẹ̀yán Aṣàfihàn nínú Ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀
Credit: Prof L. O. Adewole
Yoruba for academic purpose
Ìfáárà
Awoyale (1995) ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé
nípa àwọn ìsọ̀rí gírámà tí ó wà nínú èdè Yorùbá. Lára àwọn ìsọ̀rí tí ó yẹ̀ wò
ni èyí tí ó pè ní ‘determiner’ tí ó sì pín àwọn wúnrẹ̀n yìí, yẹn, kan àti náà sí
abẹ́ rẹ̀. ‘Determiner’ yii ni Bamgboṣe (1990: 124-125) pín sí abẹ́ ìsòrí
mẹ́ta. Abẹ́ ẹ̀yán aṣòǹkà ni Bamgboṣe (ib.) pín kan sí; ó pín yìí àti yẹn sí abẹ́ ẹ̀yán-aṣàfihàn ó sì pín náà sí abẹ́ èyán-atọ́ka aṣàfihàn.
Gbogbo àwọn wúnrẹ̀n mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ni Awobuluyi (2013: 63) pín sí abẹ́ ẹ̀yán
aṣàfihàn. Nínú iṣẹ́ yìí, àwọn wúnrẹ̀n wọ̀nyí ni a fẹ́ yẹ̀ wò nínú ẹ̀ka-èdè
Ifẹ̀.
Yìí
Nínú ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀, ghìn-ín ni wọ́n ń lò dípò yìí
gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ yọ ní (1).
(1) Ọmọ ghìn-ín ‘Ọmọ yìí’
Lójú Bamgboṣe (1990: 126), láti ara èyí ni a ti ṣẹ̀dá yìí. Ó pe èyí ní
ọ̀rò-orúkọ. Lójú rẹ̀, a ṣẹ̀dá yìí
láti ara èyí nípa mímú ìgbésẹ̀
fonọ́lọ́jì fáwẹ̀lì pípajẹ lò. A pa fáwẹ̀lì tí ó ṣáájú èyí jẹ; àbájáde rẹ̀ sì ni yìí.
Ó fi ìyàtọ̀ wọn hàn nínú Bamgbose (ib.) báyìí:
(2) (a) aṣọ èyí (aṣọ ẹni tí a tọ́ka
sí)
(b) aṣọ yìí (aṣọ tí a tọ́ka
sí).
Irú àlàyé ìṣẹ̀dá lọ́nà yìí kò ṣeé ṣe
nínú ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀. Ìdí ni pé, gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ghìn-ín ni wọ́n ń lò nínú ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ dípò yìí tí wọ́n sì ń lo yèé fún èyí
tí wọ́n ń lò nínú olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá. Àpẹẹrẹ ìlò àwọn wúnrẹ̀n wọ̀nyí
nínú ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ ni ó wà ní (3).
(3) (a) asọ yèé (aṣọ ẹni tí a tọ́ka sí)
(b) aṣọ ghìn-ín (aṣọ tí a tọ́ka sí)
Èyí fìhàn pé kò sí ọ̀nà tí a fi lè
ṣẹ̀dá ghìn-ín láti ara yèé nípa
ìró fáwẹ̀lì pípajẹ.
Bamgboṣe (1990: 214) tún mẹ́nu ba
oríṣi yìí kan tí ó pè ní wúnrẹ̀n
àtẹnumọ́. Ó fi ìyàtọ̀ tí ó wà láàrin wúnrẹ̀n yìí àti yìí ẹ̀yán-aṣàfihàn hàn báyìí:
(4) (a) Bàbá yìí ni ó ń lọ (ẹ̀yán)
(b) Bàbá ni ó ń lọ yìí (wúnrẹ̀n atẹnumọ́).
A tilẹ̀ lè lo àwọn méjèèjì pọ̀ nínú
gbólóhùn kan ṣoṣo gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ yọ nínú (5).
(5) Bàbá yìí1 ni ó ń lọ yìí2
Ní (5), yìí1 jẹ́ ẹ̀yán aṣàfihàn nígbà tí yìí2 sì jẹ́
wúnrẹ̀n àtẹnumọ́. Nínú ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀, a lè lo ghìn-ín báyìí náà. Ẹ wo àpẹẹrẹ (6).
(6) (a) Bàbá ghìn-ín lọ́ ń lọ (ẹ̀yán)
(b) Bàbá lọ́ ń lọ ghìn-ín (wúnrẹ̀n
àtẹnumọ́)
(d) Bàbá ghìn-ín1 lọ́ ń lọ ghìn-ín2
Níbí náà, bí o ṣe wà ní (5), ghìn-ín1 jẹ́ èyán aṣàfihàn nígbà
tí ghìn-ín2 jẹ́ wúnrẹ̀n
àtẹnumọ́.
Awobuluyi (2013: 63) kò ya ìlò èyí
àti yìí sọ́tọ̀ sí ara wọn. Ọ̀kan náà
ni ó kà wọ́n sí. Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀yán aṣàfihàn ní Awobuluyi (ib.),
àpẹẹrẹ tí ó fún wa ni a kọ sí (7).
(7) Bàbá kan wà ní Èkó, bàbá … àyí lówó ju ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀
Tí a bá tilẹ̀ wo Awobuluyi (2008) níbí
tí ó ti ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀-orúkọ, kò mẹ́nu ba ìṣẹ̀dá yìí láti ara èyí.
Awobuluyi (2013: 36) tún menu ba yìí/èyí kan tí ó pè ní arọ́pò-orúkọ
atọ́ka-ohun. Ibi ni ó sọ pé yìí/èyí
yìí máa ń tọ́ka. Àpẹẹrẹ tí ó fún wa ni a kọ sí (8).
(8) (a) Kí ni èyí/yìí?
(b) Ta ni èyí/yìí?
Ẹka-èdè Ifẹ̀ kìí lo ghìn-ín tí wọ́n máa ń ló dípò yìí ẹ̀yán-aṣàfihàn báyìí. Dípò (8a) àti
(8b), gbólóhùn tí wọ́n máa ń lò ní ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ ni (9a) àt (9b) ní
sísẹ̀-n-tẹ̀lé.
(9) (a) Kí rèé?
(b) Yè sí rèé?
Ohun tí eléyìí fi hàn ni pé ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀
ya ìlò yìí gẹ́gẹ́ bí èyán-aṣàfihàn
sọ́tọ̀ sí ìlò wúnrẹ̀n mìíràn tí ó wà fún arọ́pò-orúkọ atọ́ka-ohun.
Yẹn
Ìsọ̀rí tí Bamgboṣe (1990: 125) pín yìí sí náà ni ó pín yẹn sí. Ẹ̀yán-aṣàfihàn ni ó pe méjèèjì. Nì ni wọ́n máa ń lò nínú ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ dípò yẹn tí wọ́n máa ń lò nínú olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá. Ìyẹn ni pé dípò
(10a), (10b) ni wọ́n máa ń sọ nínú ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀.
(10) (a) ọmọ yẹn
(b) ọmọ nì
Ara ìyẹn
ni Bamgboṣe (1990: 126) ti sọ pé a ṣẹ̀dá yẹn
nípa ìgbésẹ̀ fonólójì tí a ń pè ní fáwẹ̀lì pípajẹ. Lóòótọ́, kò fún wa ní
àpẹẹrẹ ìlò ní gbólóhùn fún ìyẹn
ṣùgbọ́n ohun tí a rò pé ó mú un ṣe eléyìí ni pé àpẹẹrẹ tí ó lò fún èyí yóò ṣisẹ́ fún ìyẹn. Ẹ wo (11).
(11) (a) asọ ìyẹn (aṣọ ẹni tí
a tọ́ka sí)
(b) aṣọ yẹn (aṣọ tí a tọ́ka sí)
Ohun tí wọn yóò sọ dípò (11) ní
ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ fi hàn pé ó dàbí ìgbà pé a lè sọ pé a ṣẹ̀dá wúnrẹn tí ẹ̀ka-èdè
yìí ń lò fún yẹn láti ara èyí tí
wọ́n ń lò fún ìyẹn nípa ìró fáwẹ̀lì
pípajẹ. Ẹ wo (12).
(12) (a) asọ yèé nì (aṣọ ìyẹn)
(b) aṣọ nì (aṣọ yẹn)
Ẹni tí ó bá fẹ́ mú àbá yìí lò lè sọ pé
a pa yèé jẹ láti ara yèé nì tí ó dúró fún ìyẹn tí wọ́n ń lò ní olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá
ni a fi rí ni tí ó dúró fún yẹn tí wọ́n ń lò ní olórí ẹ̀ka-èdè
Yorùbá. N ìdàkejì ẹ̀wẹ̀, a tún lè sọ pé a ṣẹ̀dá wúnrẹ̀n tí ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ ń
lò dípò èyí tí wọ́n ń lò nínú olórí
ẹ̀ka-èdè Yorùbá nípa ìró pípajẹ náà. Ẹ wo (13).
(13) (a) aṣọ yèé nì (= aṣọ ìyẹn)
(b) aṣọ yèé (= aṣọ
èyí)
Ẹni tí ó bá fẹ́ mú àbá yìí wá lè sọ pé
a pa nì jẹ láti ara yèé nì ni a fi ṣẹ̀dá yèé.
Bamgboṣe (1990: 214) kò mẹnu ba ìlò yẹn gẹ́gẹ́ bíi wúnrẹ̀n àtẹnumọ́ ṣùgbọ́n
níwọ̀n ìgbà tí a ti lè fi yẹn ní
(14b) rọ́pò yìí nínú àpẹẹrẹ tí ó
fún wa tí a tún kọ sí (14a), a lérò pé a lè pe yẹn (14b) náà ní wúnrẹ̀n àtẹnumọ́.
(14) (a) Bàbá ni ó ń bọ̀ yìí
(b) Bàbá ni ó ń bọ̀ yẹn
Bí èyí bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé nì ni ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ máa ń lò bíi
wúnrẹ̀n àtẹnumọ́ dípò yẹn. Ẹ wo
(15).
(15) Bàbá lọ́ mí bọ̀ọ nì
A ó ṣe àkíyèsí pé ọ kán ṣáájú nì tí kò
ṣáájú yẹn. A lè lo àbá tí Abraham
(1958: 441) dá pé ‘when the noun preceding nì
ends in mid-tone, it becomes mid-low falling tone’ láti ṣe àlàyé ohun tí ó ń
ṣẹlẹ̀ ní bí. Lóòótọ́, bọ̀ tí ó
ṣááajú nì kìí ṣe ọ̀rò-orúko, a lè
fi ojú àbá Abraham (ib.) wo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀. Ní ìdà kejì ẹ̀wẹ̀, ó sì lè
jẹ́ pé ohun tí Awobuluyi (2013) sọ pé fáwèlì ni ó máa ń ṣaájú àwọn ọ̀rọ̀
kan èyí tí ó fi ń kọ yìí ní àyí (Awobuluyi (2013: 63) ni ó ń sẹlẹ̀
sí nì. Tí a bá lo àbá yìí, ohun tí a
ó sọ ni pé ìpìlẹ̀ Bàbá lọ́ mí bọ̀ inì
ni gbólóhùn náà ní ìpìlẹ̀. Àránmọ́ ni ó
wá sọ ọ́ di Bàbá lọ́ mí bọ̀ọ nì.
Àlàyé tí Awobuluyi (2013: 63) ṣe nípa yẹn ni pé a lè lò ó gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yán
aṣàfihàn. Ẹ wo (16).
(16) Bàbá … àyẹn sónú ju àjẹ́
Nínú ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀, nì ni wọn yóò lò dípò àyẹn.
Ẹ wo (17).
(17) Bàbá … nì sónú jàjẹ́
Àpẹẹrẹ mìíràn tí Awobuluyi (2013: 36)
ni ibi tí ó ti lo ìyẹn gẹ́gẹ́ bí arọ́pò-orúkọ atọ́ka-ohun. Ẹ wo
(18).
(18) Èwo ni ìyẹn?
Rèé
nì
ni wọn yóò lò dípò ìyẹn tí ó wà ní
(18) ní ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀.
(19) Èwo rèé nì
Tí ó bá jẹ́ pé Èwo ni èyí? ni, Èwo rèé
ni wọn yóò lò ní ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀.
Kan
Ní abẹ́ ẹ̀yán aṣòǹkà ni Bamgboṣe
(1990: 124) to kan sí ṣùgbọ́n ní
ibẹ̀, ó kà á sí kòbẹ́gbẹ́mu nítorí pé kò hùwà bí àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ ṣe ń hùwà.
Ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yàn aṣàfìhàn ni Awobuluiyi (2013: 63) ka kan kún. Àpẹẹrẹ tí ó fún wa ni (20).
(20) Mo rí ìwé kan níbẹ̀
Kàn ni wọ́n máa ń
lò dípò kan nínú ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀.
(21) Mo ríwèe kàn ńbẹ̀
Abraham (1958: 513) ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́
àlàyé nípa ìhùwàsí kan. Ó ní:
When the noun
preceding kọn has high tone or
mid-high rising tone, then these change to high-mid falling-tone: ọwọ́ọ̄ kan ‘one hand’.
Òfin yìí kò ṣíṣẹ́ nínú ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀
nítorí pé dípò àpẹẹrẹ tí Awobuluyi (ib.) fún wa, (22) ni wọn yóò sọ nínú
ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀.
(22) Ọwọ́ọ̀ kàn
Abraham (ib.) tún sọ pé
When the noun
before kọn has two or more
mid-tones, then the syllable immediately before kọn falls from mid to mid-low: abẹ̄ẹͮ
kan ‘one razor’
Òfin yìí náà kò ṣiṣẹ́ fún kàn nínú ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ nitorí pé dípò
àpẹẹrẹ tí Abraham (i.m.) fún wa, (23) ni wọn yóò sọ ní ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ ní
ibi tí ó jẹ́ pé ohùn ìsàlẹ̀ ni ó ṣáájú kàn.
Abẹẹ̀ kàn
Òfin tí Abraham (i.m.) fi kádìí àlàyé
rẹ̀ nípa kọn ṣisẹ́ fún kàn nínú ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀. Ó ní:
But the words ohun, ẹni, and ibi form
an exception to 4a.iii as they become respectively ohùn, ẹnì and ibì before
kọn: ẹnì kọn ‘one person’.
(24) ni wọn yóò sọ ní ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀
náà ní ibi tí ẹni ti yí padà di ẹnì.
Ẹnì kàn
Ohun tí èyí ń fihàn ni pé dípò òfin
mẹ́ta tí Abraham mú lò fún olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá fún ìyípadà ohùn ṣáájú kan, ẹyọ kan ni ó ṣiṣẹ́ fún ẹ̀ka-èdè
Ifẹ̀.
Náà
Ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yán-atọ́ka aṣàfihàn
ni Bamgboṣe (1990: 125) ka náà sí gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ yọ ní (25).
(25) ilú náà
Abẹ́ ẹ̀yán aṣàfihàn náà ni Awobuluyi
(2013: 62) pín náà sí ó sì fún wan ní
àpẹẹrẹ (26).
(26) Bàbá náà lówó ju ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ lọ
Dípò náà,
nì ni wọ́n máa ń lò nínú ẹ̀ka-èdè
Ifẹ̀. Ìyẹn ni pé dípò (25) àti (26), ohun tí wọn yóò sọ nínú ẹ̀ka-èdè ifẹ̀
ni (27) àti (28).
(27) ilú nì
(28) Bàbá nì lówó ju ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ lọ
Ohun tí a ó ṣe àkíyèsí ni pé dípò yẹn àti náà tí wọ́n ń lò ní olórí-ẹ̀ka-èdè Yorùbá, nì ni wọ́n máa ń lò nínú ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀. Bóyá nítorí pọ́nna tí
eléyìí lè dá sílè, dìpò ìlò nì fún náà, wọ́n tún máa ń lo ọ̀ún fún náà nínú ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀. Ìyẹn ni pé dípò (27) àti (28), a tún lè gbọ́
(29) àti (30).
(29) ilú ọ̀ún
(30) Bàbá ọ̀ún lówó ju ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ lọ
Abraham (1958: 434-435) pín náà sí abẹ́ ìsọ̀rí ọ̀rọ̀-àpèjúwe. Púpọ̀ nínú àwọn
àpẹẹrẹ tí ó fún wa ni ó jẹ́ pé dípò nì
tábí ọ̀ún, náà ni wọn yóò lò nínú ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀. Ẹ wo (31).
(31) (a) bákan náà[1] (Ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀: bákàn náà)
(b) èmi náà (Ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀: èmi náà)
(d) òkè yìí náà (Ẹka-edè Ifẹ̀: òkè
ghìn-ín náà)
Ohun tí èyí ń fi hàn ni pé ẹ̀ka-èdè
Ifẹ̀ ya àwọn wúnrẹ̀n tí ó ń lò dípò náà
sọ́tọ̀ nígbà tí ó bá dúró fún ohun
tí àwọn kan pè ní ẹ̀yàn aṣàfihàn sí ìgbà tí ó bá dúró fún ohun tí Abraham
(1958) pè ní ọ̀rọ̀-àpèjúwe.
Ìgúnlẹ̀
Ní ìkádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ lórí ẹ̀yán
aṣàfihàn, Awobuluyi (2013: 63) sọ pé ‘isẹ́ àti ìtumọ̀ ìyí/ìwọ̀nyí àti ìyẹn/ìwọ̀nyẹn,
gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yán aṣàfihàn, gba ìwádìí síwájú sí i’. Gẹ́gẹ́ bí àláyé tí a ti e
lókè yìí yóò ti fi hàn, àwọn wúnrẹ̀n tí
Awobuluyi (ib.) mẹ́nu bà wọ̀nyí nìkan kọ́ ni wọ́n nílò ìwádìí síwájú sí i. A
tún nílò láti ṣe ìwádìí sí i lórí àwọn wúnrẹ̀n tí Awoyale (1995) mẹ́nu bà, ní
pàtàkì, bí wọ́n ṣe ń jẹ yọ nínú àwọn ẹ̀ka-èdè wa gbogbo. Eléyìí kín ohun
tí Awobuluyi (2013:7) sọ lẹ́yìn pé ‘ìmọ̀ ẹ̀ka-èdè wúlò gan: ń ṣ e ni ó máa
ń la’ni lójú la’ni lọ́yẹ nípa ìhun Yorùbá àjùmọ̀lò’.
Àwọn
Ìwé Atọ́kasí
Abraham, R.C. (1958), Dictionary of Modern Yoruba. London:
Hodder and Stoughton.
Awobuluyi, Ọladele (2008), Ẹ̀kọ́ Ìṣẹ̀dá-Ọ̀rọ̀ Yorùbá.Akurẹ:
Moutem paperbacks
Awobuluyi, Ọladele (2013), Ẹ̀kọ́ Gírámà Èdè Yorùbá. Oṣogbo: Atman
Limited.
Awoyale, Yiwọla (1995), ‘The Role of
Functional Categories in Syntax: the Yoruba Case’, Essays in Honour of Ayọ Bamgbose, edited by Kọla Owolabi, pp. 113-127. Ibadan: Group Publishers.
Bamgboṣe, Ayọ (1990), Fonọ́lójì àti Gírámà Yorùbá. Ibadan:
University Press PLC.
[1] Àkọtọ́ yìí yàtọ̀ sí èyí tí Abraham (1958: 434-435) lò nínú ìwé rẹ̀.
Comments
Post a Comment