Bí Yorùbá bá Ní Àtamọ́
Bí Yorùbá bá Ní Àtamọ́
Credit: Prof L. O. Adewole
Yoruba for academic purpose
Kí ni Àtamọ́?
Nínú
iṣẹ́ yìí, ọ̀rọ̀ nípa àtamọ́ ni a fẹ́ mẹ́nu bà. Klavan
(1980: 65) sọ pé àtamọ́ ni àwọn fọ́nrán kan tí ó jẹ́ pé
nínú ẹ̀ka fonọ́lọ́jì, wọ́n máa ń bá àwọn ọ̀rọ̀ kan ṣe
pọ̀ ṣùgbọ́n wọn lè máà bá wọn ṣe pọ̀ nínú ẹ̀ka
mọfọ́lọ́jì. Bí wọ́n bá sì bá àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣe pọ̀
nínú ẹ̀ka mọfọ́lọ́jì, wọ́n lè máà bá wọn ṣe pọ̀ nínú
ẹ̀ka fonọ́lọ́jì. Yàtọ̀ sí èyí, àwọn fọ́nrán yìí kìí ṣe
àfòmọ́ ìṣẹ̀dá tàbí ti ìlò[1]. Èyí fi hàn pé wọ́n ní àbùdá ọ̀rọ̀ wọ́n sì tún ni àbùdá àfòmọ́.
Kí
á tó máa tẹ̀ síwájú nínú àlàyé wa, ó yẹ kí á mẹ́nu ba bí àwọn onímọ̀
èdá-èdè ṣe ń lo àfòmọ́ nínú èdè Yorùbá. Nínú mofọ́lọ́jì, wọ́n máa ń
mẹ́nu ba mọ́fíìmù ìlò àti mọ́fíìmù ìṣẹ̀dá[2]. Àfòmọ́[3] ni àwọ̀n méjèèjì mọ́fíìmù àfarahẹ[4] ni wọ́n sì máa ń sábàá jẹ́.
Nínú tíọ́rì awòtéwògàba[5] àti ètò oníwọ̀nba èròjà[6],
àwọn onímọ̀ èdá-èdè máa ń mẹ́nu ba oríṣìí àfòmọ́ kan tí ó jẹ́ orí
fún àpólà àfòmọ́. Àpólà àfòmọ́ yìí ni a máa ń pè ní gbólóhùn nínú àwọn
gírámà kan. Nínú gírámà tí ó bá ń mú pele[7]
ni a ti máa ń sábàá fi àpólà àfòmọ́ dípò gbólóhùn. Ó yẹ kí á mẹ́nu bà
á pé kìí ṣe inú gbogbo èdè ni àfòmọ́ inú sítáàsì ti máa ń jẹ́
mọ́fíìmù àfarahẹ. Ó fi èyí yàtọ̀ sí àfòmọ́ inú mofọ́lọ́jì tí àfòmọ́ máa
ń sábàá jẹ́ mọ́fíìmù afarahẹ.
Arọ́pò-Orúkọ
Oyelaran (1987) àti Pulleyblank (1986) gbà pé oríṣi àtamọ́ kan ni arọ́pò-orúkọ[8]. Tí a bá wo gbólóhùn (1a), bí àpẹẹrẹ,
(1a) Olú rí i
(1b) Olú rí mi, Ó pè mí
tí a bá fi ojú fonọ́lọ́jì wò ó, AR inú rẹ̀ ní nǹkan-an ṣe pèlú fáwẹ́lì ọ̀rò-ìṣe[9]
tí ó tẹ̀ lé. Èyi fi hàn pé a kò lè fi gbogbo ara pè é ní
ọ̀rọ̀. Tí a bá fi ojú mọfọ́lọ́jì wò ó, a ó rí i pé kì í
ṣe àfòmọ́, yálà ti ìlò tàbí ti ìṣẹ̀dá[10] nítorí pé a kò lò ó láti ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ tuntun lára IṢ tí ó tẹ̀ lé.
Kì
í ṣe pé torí pé AR yìí tẹ̀ lé IṢ ni ó jẹ́ kí ohun tí ó
ṣẹ̀lẹ̀ sí i ṣẹ̀lẹ̀ o. Gẹ́gẹ́ bí Oyelaran (1987) ti ṣe
àkíyèsí, nínú àwọn ẹ̀ka-èdè kan, IṢ ni o máa ń sọ irú
fáwẹ́lì tí AR tí ó jẹ́ olùwà rẹ̀ máa ní. Ẹ wo gbólóhùn
(2-5):
(2) Mo mí jó
(3) Mọ mí lọ
(4) Mo ṣé
(5) Mọ gbà
Nínú
ẹ́ka-èdè yìí, a ó ṣe àkíyèsí pé ìbáṣepọ̀ wa láàrin
fáwẹ́lì IṢ àti AR tí a bá fi ojú fonọ́lọ́jì wò ó. Nínú
gbólóhùn (2-5), àjọṣepọ̀ àǹkóò fáwélì wà láàrin
fáwẹ̣́lì AR àti IṢ[11]. Pẹ̀lú àlàyé wọ̀nyí, ó tọ̀nà láti pe AR ní àtamọ́.
Sílébù Olóhùn Òkè
Sílébù olóhùn òkè[12]
ni wúnrẹn mìíràn tí a ó tùn yẹ̀ wò. Àbá méjì ni a ó yẹ̀
wò lórí SOO yìí. Bamgboṣe (1980) sọ pé SOO kò ní nǹkan
kan-an ṣe pẹ̀lú àpólà ìṣe[13] nínú gbólóhùn. Ó ní òpin àpólà orúkọ[14]
ni ó máa ń fi hàn. Iyẹn ni pé, ní (6-7), ohun tí SOO ń ṣe ni
pé ó ya ibi tí APOR ti parí sọ́tọ̀ sí ibi tí APIṢ ti bẹ̀rẹ̀.
(6) Òjò ó rọ̀
(7) Àwọn túlẹ̀ ẹ́ gba ìsinmi
Tí
a bá wo (6) àti (7) dáadáa, a ó rí i pé ohun tí alàyé
Bamgboṣe (1980) ń fi yé wa ni pé, lóòótọ́, SOO kò ṣẹ̀dá
ọ̀rọ̀ tuntun láti ara òjò tàbí àwọn túlẹ̀, síbẹ̀, APOR wọ̀nyí ni SOO ń bá ṣiṣẹ́ ó sì tún ní nǹkan-an ṣe pẹ̀lu fáwẹ́lì
tí ó gbẹ̀yìn APOR yìí tí a bá fi ojú fonọ́lọ́jì wò ó.
Lójú Awobuluyi (1975), atọ́ka afànámónìí ni SOO. Tí a bá fi
ojú eléyìí wò ó, APIṢ tàbí gbólóhùn ni SOO ń bá ṣiṣẹ́
ṣùgbọ́n tí a bá fi ojú fonọ́lọ́jì wò ó, fáwẹ́lì tí ó
gbẹ̀yìn APOR ni ó máa ń ràn mọ́. Iṣẹ́ tí SOO ń ṣe kọ́ ni ó jẹ
wá lógún nínú bébà yìí. Ohun tí ó jẹ wá lógún ni pé SOO yìí kìí ṣe
ọ̀rọ̀ kìí sìí ṣe àfòmọ́.yálà ti ìlò tàbí ti ìṣẹ̀dá.
Aṣáájú Ọ̀rọ̀-ìṣe Ọbọ̀rọ́
Nínú
Bámgbóṣé (1990: 145), díẹ̀ nínú àwọn gbólóhùn tí ó sọ
pé ó ní atọ́ka ọ̀rọ̀-ìṣe ọ̀bọ̀rọ́ nínú ni:
(8a) Ó fẹ́ẹ́[15] lọ
(b) Ó bẹ̀rẹ̀ sí í máa kọrin
(d) Omi náà tóó mu
Nínú àwọn àpẹẹrẹ (8a-d), àwọn atọ́ka ọ̀rọ̀-ìṣe ọ̀bọ̀rọ́ ni ẹ́, í àti ó tí a kọ yàtọ̀ yẹn. Bámgbóṣé (1990: 144) sọ pé í ni ìpìlẹ̀ atọ́ka ọ̀rọ̀-ìṣe ọ̀bọ̀rọ́. Àrànmọ́ ni ó sọ í yì di ẹ́ àti ó ní (8a àti d).
Atọ́ka Àpólà Orúkọ Oníbáàtan
Lójú
Bamgbose (1990: 119), atọ́ka yìí ni ó máa ń wà láàrin OR tí
ó bá ń yán OR. Ó pè é ní ẹ̀hun oníbàátan. A máa ń ṣe
àkíyèsí rẹ̀ dáadáa tí kọ́ńsónáǹtì[16] bá bẹ̀rẹ̀ ẹ̀yán ajórúkọ, bí àpẹẹrẹ, ‘tiwa’ nínú
(9) Owóo tiwa
A ó ṣe àkíyèsí pé o tí ó dúdú jù lara ‘Owóo
tiwa’ kò sí lára ‘owó’ tàbí ‘tiwa’ ní ìpìlẹ̀ bẹ́ẹ̀ rèé,
ó ràn mọ́ ‘owó’ láìjẹ́ pé ó ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ tuntun lára rẹ̀.
Gbogbo àkíyèsí yìí ni ó bá oríkì àtamọ́ tí Klavan (1980:
65) fi lélẹ̀ mu.
Alàyé Atàmọ́
Tí a bá fẹ́ ṣe àláyé àtamọ́, àwọn ohun márùn-ún ọ̀tọ̀tọ̀ ni a gbọ́dọ̀ ṣe àkíyèsí[17].
Lọ́nà kìíní, a gbọ́dọ̀ lè ṣe àlàyé orúkọ tí irú
àtamọ́ bẹ́ẹ̀ ń jẹ́ (clitic identity). A ó máa pe èyí ní P1.
Èkejì ni ẹ̀wọ́n tí ó gàba
lé irú àtamọ́ bẹ́ẹ̀ lórí (domain of cliticization). A o má ape
èyí ni P2. Ẹkẹ́ta ni àpólà tàbí ọ̀rọ̀ tí o gba irú
àtamọ́ bẹ́ẹ̀ lálejò bóyá ìró ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀[18]
bẹ́ẹ̀ ni o tàbí ìró tí ó wà ní ìparí (initial/final). A ó
máa pe eléyìí ni P3. Ẹ̀kẹ́rin ni pé ọ̀rọ̀ tàbí àpólà tí
ó gba àtamọ́ yìí ní àlejò, ṣé iwájú àtamọ́ yìí ni ó wà
ni tàbí ẹ̀yìn rẹ̀ (before/after)? A ó pe eléyìí ni P4.
Ẹkarùn-ún, tí ó jẹ́ ìparí, ni pé ṣé àtamọ́wájú ni
àtamọ́ yìí ni tàbí àtamẹ́yìn (proclitic/enclitic). Eléyìí ni
a pè ní P5.
Tí a bá fi ojú àlàyé tí a ṣe yìí wo AR, àláyé wa yóò lọ báyìí:
(10) Àtamọ́ Arọ́pò orúkọ
P1: AR
P2: AṢ[19].
P3: ìparí[20]/-
P4: iwájú àti ẹ̀yìn[21]
P5: àtamọ́wájú àti àtamẹ́yìn[22]
Ni (3), AR ni ‘mọ’(P1), oríṣi aṣàfihàn (P2) kan ni. Òpin (P3) ni àtamọ́ tí ó wáyé ti ṣẹ̀lẹ̀ sí i nínú ‘mọ
mí lọ’. Ẹ̀yìn (P4) ni fọ́nrán tí ó fa àtamọ́ wa ní (3)
nítorí ìdí èyí, àtamọwájú (P5) ni. Tí a bá wá wo (1a) níbi
tí a ti rí ‘Olú rí i’, àlàyé tí a rí ṣe ni pé AR ni ‘i’
(P1) oríṣi aṣàfihàn (P2) kan ni. Ní (P3), ó ṣòro láti sọ
bóyá ìbẹ̀rẹ̀ tàbí òpin ni àtamọ́ tí ó ṣẹlẹ̀ ti ṣẹlẹ̀
sí i nítorí ọ̀rọ̀ oníròó kan ni i yìí ṣùgbọ́n tí a bá wo (1b), a ó rí i pé òpin ni àtamọ́ tí ó ṣẹlẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí mi/mí
nítorí pé ohùn orí IṢ onísílébù kan ni ó máa ń sọ irú
ohùn tí AR tí ó jẹ́ àbọ̀ fún un máa ní. Òpin AR (1b) yìí
sì ni àyípadà ohùn yìí ti ṣẹlẹ̀ tí a fi rí mi tí ó ní ohùn àárin àti mí
tí ó ní ohùn òkè nítorí IṢ tí ó ṣaájú ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn.
Ni (P4), iwájú ni ohùn tí ó fa àrànmọ́ wa nìtorí ìdí èyí,
ní (P5), àtamẹ́yìn ni àtamọ́ tí ó ṣẹlẹ̀.
(11) Atamọ́ Oníbàátan
P1: atọ́ka oníbàátan
P2: AṢ
P3: -
P4: iwáju
P5: àtamẹ́yìn[23]
Ohun tí (11) ń ṣe àlàyé ni pé P1 sọ pé àtamọ́ oníbàátan ni
àtamọ́ yìí. P2 sọ pé aṣàfihàn ni. Ní (P3), ó ṣòro láti
sọ bóyá ìbẹ̀rẹ̀ tàbí òpin ni àrànmọ́ tí ó ṣẹlẹ̀ sí
àtamọ́ yìí ti ṣẹlẹ̀ sí i nítorí ọ̀rọ̀ oníròó kan ni
atọ́ka rẹ̀, ìyẹn ọ tí ó wà nínú aṣọọ Délé . Ni (P4), iwájú ni ìró tí ó fa àrànmọ́ wa nìtorí ìdí èyí, ní (P5), àtamẹ́yìn ni àtamọ́ yìí.
(12) Àtamọ́ SOO
P1: SOO
P2: WỌ
P3: -
P4: iwájú
P5: àtamẹ́yìn
Ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní (12) fara jọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ni (11). P1 sọ pé àtamọ́ SOO ni àtamọ́ yìí. P2 sọ pé aṣèrànwọ́ ìṣe[24]
ni. Ní (P3), ó ṣòro láti sọ bóyá ìbẹ̀rẹ̀ tàbí òpin ni
àrànmọ́ ti ó ṣẹlẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ oníròó kan ni
atọ́ka rẹ̀, bí àpẹẹrẹ, ìró kan ni ó tí ó dúdú jù nínú Òjòó rọ̀ ní. Ni (P4), iwájú ni ìró tí ó fa àrànmọ́ wa nìtorí ìdí èyí, ní (P5), àtamẹ́yìn ni àtamọ́ yìí.
(13) Atamọ́ àpólà ìṣe ọ̀bọ̀rọ́
P1: atọ́ka àpólà ìṣe ọ̀bọ́rọ́
P2: AF[25]
P3: -
P4: iwájú
P5: àtamẹ́yìn[26]
P1 sọ pé àtamọ́ àpólà ìṣe ọ̀bọ́rọ́ ni
àtamọ́ yìí. P2 sọ pé oríṣìí àfòmọ́ kan ni. Ní (P3), ó
ṣòro láti sọ bóyá ìbẹ̀rẹ̀ tàbí òpin ni àrànmọ́ tí ó
ṣẹlẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ oníròó kan ni atọ́ka rẹ̀. Ni (P4), iwájú ni ìró tí ó fa àrànmọ́ wa nìtorí ìdí èyí, ní (P5), àtamẹ́yìn ni àtamọ́ yìí[27].
Àbùdá Ọ̀rọ̀ àti Àpínpẹ̀kun
Kí
àlàyé wa lórí àtamọ́ lè kún tó bí ó ti yẹ, a nílò láti
wo àbá tí Cann (1984) dá lórí abùdá ọ̀rọ̀ àti àpínpẹ̀kun[28].
Lójú Cann (1984), a lè pín ìsọ̀ri sí oríṣi mẹ́rin. Èkíní
ni ìsọrí tí ó jẹ àpínpẹ̀kun tí ó sì tún jẹ́ àpólà. A ó
máa pe eléyìí ní APX[29].
Èkejì ni ìsọ̀rí tí kì í ṣe ọ̀rọ̀ tí kì í sì i ṣe
àpólà; ìyẹn ni pé ó ju ọ̀rọ̀ lọ kò sì tó àpólà. Ìsọrí
yìí kìí ṣe àpínpẹ̀kun, kìí ṣe ọ̀rọ̀ kì í sì i ṣe
àpólà. A ó máa pe eléyìí ní XB. Ìkẹ́ta ni ìsọ̀rí tí kìí
ṣe àpínpẹ̀kun tí ó sì jẹ́ ọ̀rọ̀. A ó pe èyí ní XD.
Ìkẹ́rin ni ìsọ̀rí tí ó jẹ́ àpínpẹ̀kun tí ó sì tún jẹ́
ọ̀rọ̀. Eléyìí ni XC. Bí àwọn ìpín mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ṣe rí nì
yí:
(14)
(i) {<APÍNPẸ̀KUN, +> <WÚNRẸN, ->} APX (ìsọ̀rí tí ó
jẹ́ àpínpẹ̀kun ṣùgbọ́n tí kìí ṣe wúnrẹ̀n kan soso, b.a.
‘bàtà Olú’).
(ii) {<APÍNPẸ̀KUN, -> < WÚNRẸN, ->} XB (ìsọ̀rí tí kì i ṣe àpínpẹ̀kun tí kìí ṣe wúnrẹ̀n kan soso, b.a. ‘e Déle’ nínú ‘Ilée Délé’).
(iii)
{<APÍNPẸ̀KUN, -> < WÚNRẸN, +>} XD (ìsọ̀rí tí kì i
ṣe àpínpẹ̀kun tí ó sì jẹ́ wúnrẹ̀n kan soso, b.a. ‘Dele’ nínú
‘Ilée Délé’).
(iv) {<APÍNPẸ̀KUN, +> < WÚNRẸN, +>} XC (ìsọ̀rí tí ó jẹ́ àpínpẹ̀kun tí ó sì jẹ́ wúnrẹ̀n kan soso, b.a. ‘Olú’ nínú ‘Olú lọ’).
Yàtọ̀ sí òfin ìsọ̀rí, Cann (1984) tún dábàá òfin fún àwọn ọ̀rọ̀. Òfin yìí ni ó wà ní (15):
(15) (i) [+Ọ̀RỌ̀, +ÌPÌLẸ̀] (Èyí ni ọ̀rọ̀ tí a kò ṣẹ̀dá, bí àpẹẹrẹ, ‘lọ’) [+Ọ, +I][30]
(ii) [-Ọ̀RỌ̀, +ÌPÌLẸ̀] (Èyí ni àfòmọ́, bí àpẹẹrẹ, ‘i’ nínú ‘ijó’) [-Ọ, +I]
(iii) [+Ọ̀RỌ̀, -ÌPÌLẸ̀] (Èyí ni ọ̀rọ̀ tí a ṣẹ̀dá, bí àpẹẹrẹ, ‘ijó’) [+Ọ, -I]
(iv) [-Ọ̀RỌ̀, -ÌPÌLẸ̀] (Èyí ni àtamọ́, bí àpẹẹre, SOO) [-Ọ, -I]
Lẹ́yìn
ìgbà tí a ti ṣe àlàyé oríkì ìsọrí àti òfin ọ̀rọ̀ tán, a
lè wá wo bí wọn ṣe ń jẹ yọ nínú àtẹ alákàámọ́.
(16) Olú fẹ́ẹ́ lọ
[IṢX[IṢD[+Ọ, +I] fẹ́ =[31] [IṢB[IṢD[-Ọ, -I] ẹ́[IṢD[+Ọ, +I] lọ]]]]]
Àwọn onígírámà kan gbà pé fẹ́ í lọ ni ìpìlẹ̀ àpólà yìí ṣùgbọ́n níwọ̀n ìgbà tí àrànmọ́ ti lè wáyé láàrin fáwẹ̀lì fẹ́ àti í láti fún wa ní fẹ́ẹ́ lọ, a kò jayò pa tí a bá sọ pé í yìí rọ̀gbọ̀kú lé fẹ́ lórí. Lójú àwọn onígírámà mìíràn, ìtumọ̀ kan náà ni Olú fẹ́ẹ́ lọ àti Olú fẹ́ ní àtilọ ní. Ohun tí a rí sọ sí èyí ni pé ìtùmọ̀ wọn ni ó bára mu, ìhun wọn yàtọ̀ sí ara wọn. Ọ̀rọ̀-atọ́kùn ni ní tí ó wà nínú ní àtilọ nígbà ti àtilọ jẹ́ ọ̀rọ̀ aṣẹ̀dá. Àlàyé lórí fẹ́ láti lọ (fẹ́ ní àtilọ) ni (17a)[32]
(17a) Olú fẹ́ ní àtilọ
[IṢX[IṢD[+Ọ, +I] fẹ́[ATX[ATD[+Ọ, +I] ní[ORC[+Ọ, -I] àtilọ]]]]]
Fún àwọn onímọ̀ gírámà tí ó gbà pé ìpìlẹ̀ Olú mọ ọkọ̀ọ́ wà ni Olú mọ ọkọ̀ wíwà, àlàyé rẹ̀ ni (17b).
(17b) Olú mọ ọ̀kọ̀ wíwà
[AṢX[AṢD[+Ọ, +I] ọkọ̀[AṢD[+Ọ, -I] wíwà]]]
(18) Mo rí Olú
[IṢX[IṢD[+Ọ, +I] rí[ASC[+O, +I] Olú]]]
(19) Mo rí i
[IṢX[IṢD[+Ọ, +I] rí = [ASC[+Ọ, +I] i]]
(20) Aṣọọ Délé
[AṢX[AṢD[+Ọ, +I] Aṣọ = [AṢB[AṢD[+Ọ, +I] ọ[AṢD[+Ọ, +I] Délé]]]]]
Àwọn onígírámà kan gbà pé Aṣọ Idélé ni ìpìlẹ̀ àpólà yìí yàtọ̀ sí Aṣọ i Délé tí àwọn tí ó gba i yìí gẹ́gẹ́ bí atọ́ka oníbàátan ṣe máa ń sọ. Lójú àwọn onígírámà tí o gba Aṣọ Idélé ní ìpìlẹ̀ Aṣọọ Délé, gbogbo OR Yorùbá ni fáwẹ̀lì bèrẹ̀ àti pé orúkọ tí a ń pè ni Délé nínú olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá, Idélé ni wọ́n máa ń pè é nínú àwọn èka-èdè Èkìtì kan. Bí èyí bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé àlàyé wà fún Aṣọọ Délé (Aṣọ Idélé) ni (21):
(21) Aṣọ Idélé
[AṢX[AṢC[+Ọ, +I] Aṣọ [AṢC[+Ọ, +I] Idélé]]]
Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ṣáájú, nínú gbólóhùn Òjòó rọ̀,
lójú àwọn onígírámà kan, iṣẹ́ sílébù olóhùn òkè yìí
ni láti jẹ́ atọ́ka fún oríṣìí ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ kan. Àwọn kan
sọ pé oríṣìí àsìkò kan ni ó jẹ́ atọ́ka fún nígbà tí
àwọn kan sọ pé iṣẹ́ atọ́ka ìbámu ni ó ń ṣe. Iṣẹ́ yòówù
tí ó ń ṣe, ó yìí rọ̀gbọ̀kú lé Òjò tí ó ṣaájú rẹ̀ púpọ̀. Bí wọn kò tilẹ̀ jọ sí nínú ìsọ̀rí kan náà, bí ìpìnlẹ̀ SOO yìí bá jẹ́ í, gẹ́gẹ́ bí àwọn onígírámà kan ti sọ, láàrin í yìí àti ò tí ó gbẹ̀yìn òjò ni àrànmọ́ ti ṣẹlẹ̀. Nítorí ìdí èyí, àlàyé wa fún Òjòó rọ̀ ni (22):
(22) Òjòó rọ̀
[AFX[AṢC[+Ọ, +I] Òjò =][AFD[-Ọ, -I] ó][IṢC[+Ọ, +I] rọ̀]]
Ìgúnlẹ̀
Nínú
iṣẹ́ yìi láti fi ìyàtọ̀ tí ó wà láàrin àpólà, ọ̀rọ̀
tí ó jẹ́ ìpìlẹ̀, ọ̀rọ tí a ṣẹ̀dá, fọ́nrán tí ó ju
ọ̀rọ̀ lọ ṣùgbọ́n tí kò tó àpólà, àfòmọ́ ìṣẹ́dá àti
atamọ́ hàn kedere. Yàtọ̀ sí èyí, àtúpalẹ̀ tí a ṣe nínú
iṣẹ́ yìí kò fi àyè gba pele bíi ti inú síńtáàsì onípele.
Pele nínú síńtáàsì onípele máa ń dá wàhálà sílẹ̀ nígbà
mìíràn nítorí àyọtúnyọ pele. Ohun tí a ní lọ́kàn ni pé,
lẹ́yìn pele méjì (XII) tí ó jẹ́ àpínpẹ̀kun, a lè rí àyọtúnyọ pele kan (XI) kí ó tó wá kan pele òfo (X0). Kò sí àyọtúnyọ yìí nínú ìlànà aláìnípele tí a mú lò nínú iṣẹ́ yìí.
Àkójọpọ̀ Orúkọ Ìwé
Adewọle, L.O. (1986), ‘the Yoruba High Tone Revisited’, Work in Progress 19: 81-94. Edinburgh: Departmenent of Linguistics, University of Edinburgh.
Adewọle,
L.O. (1988), ‘The Categorical Status and the Functions of the Yoruba
Auxiliary Verbs with Some Structural Analyses in GPSG.’, PhD
Dissertation, University of Edinburgh.
Adewọle, L.O. (1998), ‘Another Visit to the Yoruba High Tone Syllable’, AAP 53: 91-106.
Awobuluyi, O. (1975), ‘On “the Subject Concord Prefix” in Yoruba’, Studies in African Linguistics 6, 1: 215-238.
Awobuluyi, O. (2013), Ẹ̀kọ́ Gírámá Èdè Yorùbá. Osogbo: Atman Limited.
Bamgbose, A. (1966), A Grammar of Yoruba. Ibadan: OUP.
Bamgbose, A. (1980), ‘Pronouns, Concord, Pronominalization’, Afrika und Ubersee LXIII: 189-198.
Bamgbose, A. (1990), Fonoloji ati Girama Yoruba. Ibadan: UPL
Cann, R. (1984), ‘Heads without Bars: A Theory of Phrase Structure’, An Unpublished Paper.
Cann, R. (1986), ‘The Structure of Words’, Work in Progress 19: 107-121. Edinburgh: Department of Linguistics, University of Edinburgh.
Klavan, Judith L. (1980), ‘Approaches to a Universal Theory of Clitics.’, PhD Dissertation, University of London.
Owolabi, K. (1976), ‘Noun-Noun Construction in Yoruba: A Syntactic and
Semantic Analysis.’, PhD Dissertation, University of Ibadan, Ibadan,
Nigeria.
Oyelaran, O.O. (1987) ‘Ọ̀nà Kan Ò Wọjà: Mọfọ́lọ́jì Yorùbá’, Yoruba 1: 25-44.
Oyelaran, O.O. (1992), ‘The Category AUX in the Yoruba Phrase Structure’, Research in Yoruba Language and Literature 3: 59-86.
Pulleyblank, D. (1986), ‘Clitics in Yoruba’, Syntax and Semantics9: 43-64. New York: Academic Press.
[1] Inflectional affix ni a pè ní àfòmọ́ ìlò nígbà tí a pe derivational affix ní àfòmọ́ ìṣẹ̀dá.
[2] Inflectional morpheme ni a pè ní mọ́fíìmù ìlò nígbà tí a pe derivational morpheme ní mọ́fíìmù ìṣẹ̀dá.
[3] Affix ni a pè ní àfòmọ́.
[4] Bound morpheme ni a pè ní mọ́fíìmù àfarahẹ.
[5] Government and Binding theory ni a pè ní tíórì awòtéwògàba.
[6] Minimalist Program ni a pè ní Ètò Oníwọ̀nba Èròjà.
[7] X-Bar ni a pè ní pele.
[8]
Wo Awobuluyi (2008:206) fún ìdí tí a fi lo arọ́pò-orúkọ dípò
ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ. AR ni a ó máa lò fún arọ́pò-orúkọ
láti ìsìnyí lọ.
[9] IṢ láti ìsìnyi lọ.
[10]
Afòmọ́ ìṣẹ̀dá ni ‘i’ nínú ‘ijó’ nítorí pé a lò ó láti
ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ tuntun láti ara ‘jó’ ni. Àfòmọ́ ìlò ni ‘s’ ara
‘books’ nítorí pé ‘book’ tí a ṣẹ̀dá rẹ̀ lára rẹ̀ fi ìlò
yàtọ̀ sí i.
[11] Wo Adewọle (1996 àti 2011) fún àlayé kíkún lórí àǹkóò fáwẹ́lì yìí.
[12] SOO láti ìsìnyí lọ.
[13] APIṢ láti ìsìnyí lọ.
[14] APOR láti ìsìnyí lọ.
[15]
Lóju àwọn onígírámà kan, ọ̀rọ̀-orúkọ tí a fi àpètúnpè ẹlẹ́bẹ ṣẹ̀dá
ni ìpìlẹ̀ àpólà ọ̀rọ̀-ìṣe ọ̀bọ̀rọ́. Lójú àwọn onígírámà yìí, tí a bá
so. Pé Olú mọ ọkọ̀ọ́ wà, ìpìlẹ̀ rẹ̀ ni Olú mọ̣ ọkọ̀ wíwà.
Nínú iṣẹ́ yìí, ìpìlẹ̀ tàbí iṣẹ́ tí ọ̀rọ̀ ń ṣe kò jẹ wá lógún. Lára
ohun tí ó jẹ wá lógún ni pé bóyá wúnrẹ̀n kan jẹ́ ọ̀rọ̀ tí a ṣẹ̀dá,
ọ̀rọ̀ tí a kò ṣẹ̀dá, àfòmọ́ tàbí atamọ́. Ọ̀rọ̀ tí a ṣẹ̀dá ni a ó ka wíwà sí níní iṣẹ́ yìí.
[16]
Tí a bá rọra sọ̀rọ̀ náà o, a ó ṣàkíyèsí rẹ̀ bí ó tile jẹ́ pé fáwẹ̀lì
ní ó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ náà. Ẹ̀ wo ẹ̀yán ajórúkọ tí ó wà nínú ilée ayọ̀.
[17] Wo Klavan (1980: 126) fún ẹ̀kúnṛẹ́rẹ́ àlàyé.
[18] ọ̀rọ̀ tàbí àpólà
[19] Nínú gírámà ‘Minimalist’, oríṣìí aṣàfihàn (determiner) kan ni wọ́n ka AR si. Aṣàfihàn ni a gé kúrú sí AṢ.
[20] Tí a bá wo Mo lọ inú olóri ẹ̀ka-èdè Yorùbá tí ó di Mọ lọ nínú àwọn èka-èdè kan, a ó rí i pé òpin mo tí ó di mọ ni àyípadà ti wáyé. Èyí ni a lo ìparí fùn. Ṣùgbọ́n tí a bá wo AR inú Mo rí i,
ìró kan ni AR yìí. A kò lè sọ̀rọ̀ nípa iwájú tàbi ẹ̀yìn.
Èyí ni a lo ‘-‘ fún. Àkíyèsí kejì yìí ni a ó lò fún àwọn
àtamọ́ yòókù nítorí ìró kọ̀ọ̀kan ni wọ́n.
[21] Àrànmọ́wájú ni àrànmọ́ tí ó ṣẹlẹ̀ sí AR inú Mọ lọ. Àrànmẹ́yìn ni ó ṣẹlẹ̀ sí AR inú Mo rí i.
[22] Atamọ́wájú ni ni a ó pe AR inú Mọ lọ. Àtamẹ́yìn ni a ó pe AR inú Mo rí i.
[23] Àtamọ́ oníbàátan ni ọ tí ó dúdú jù nínú ‘Aṣọọ Délé’
[24]
Aṣèrànwọ́ ìṣe ni a ń pè ní àfòmọ́ nínú gírámà ‘GB’
àti ‘Minimalist’. Àfòmọ́ yìí ni orí fún àpólà àfòmọ́ nínú
àwọn gírámà méjèèjì yìí.
[25]
Nínú gírámà ‘GB’ àti ‘Minimalist’, oríṣìí àfòmọ́ kan ni
atọ́ka ọ̀rọ̀-ìṣe ọ̀bọ̀rọ́ tí àwọn onígíràmà kan máa ń
pè ní atọ́ka ìn-ìnfínítíìfù (infinitive marker).
[26] Atọ́ka àpólà ìṣe ọ̀bọ̀rọ́ ni ẹ́ àti ọ́ tí ó dúdú jù nínú gbólóhùn wọ̀nyí: ‘Ó fẹ́ẹ́ lọ’ àti ‘Ó mọ ọkọ̀ọ́ wà’.
[27]
Àlàyé lórí àtamọ́ ju eléyìí tí a ṣe yìí lọ o ṣùgbọ́
ìwọ̀nba àlàyé tí yóò jẹ wá lógún nípa àtamọ́ nínú
iṣẹ́ yìí nì yí. Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa àtamọ́ inú
èdè Yorùbá, wo Adewọle (1998).
[28] Cann 1984. pe eléyìí ní ‘lexical and maximal features’.
[29] ‘X’ dúró fún ìsọ̀rí ọ̀rọ̀, bí àpẹẹrẹ, OR, IṢ, àbbl.
[30] ‘I’ ni ó dúró fún ‘ìpìlẹ̀’, ‘Ọ’ sì dúró fún ‘ọ̀rọ̀’.
[31] Àmì yìí ‘=’ dúró fún pé ọ̀rọ̀ tí ó ṣáájú, bí apẹẹrẹ, ‘fẹ́’ nínú (16) ni àtamọ́ yìí gbara lé.
Comments
Post a Comment