Àsìkò Ọjọ́-iwájú àti Ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ Bárakú nínú Ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú àti Olórí Ẹ̀ka-èdè Yorùbá
Àsìkò Ọjọ́-iwájú àti Ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ Bárakú nínú Ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú àti Olórí Ẹ̀ka-èdè Yorùbá
Á[1]
ni atọ́ka àsìkò ọjọ́-iwájú nígbà tí má jẹ atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ bárakú nínú ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú. Ẹ̀dà
atọ́ka àsìkò ọjọ́-iwájú tí ó tún máa ń bá atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ bárakú jẹ yọ
ni máa. Àwọ̀n apẹẹrẹ gbólóhùn tí ó fi èyí hàn ni Títí á má lọ àti Títí máa má lọ.
Ní ibi tí
ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú tí n lo á àti ẹ̀dà rẹ̀ máa fún àsìkò ọjọ́ iwájú,
á, ó àti máa
ni olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá ń lò. Ní ti ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ bárakú, níbi tí ẹ̀ka-èdè
Ìjẹ̀bú tí ń lo má, olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá ń lo máa. Ìgbéṣẹ̀ ìpajẹ
ni ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú níláti lò láti ṣẹ̀dá má láti ara máa tí olórí
ẹ̀ka-èdè Yorùbá ń lò. Àwọn àpẹẹrẹ gbólóhùn tí ó ń fi gbólóhùn tí ó ní
àsìkò ọjọ́-iwájú àti ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ bárakú hàn nínú olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá ni Títí á máa lọ, Títí ó máa lọ àti Títí
máa máa lọ[2].
Nínú gbólóhùn ìyísódì
tí ó ní ibá-ìsẹ̀lè bárakú àti àsìkò ọjọ́-iwájú nínú, atọ́ka ìyísódì ì ni èkà-èdè Ìjẹ̀bú máa ń lò nígbà tí
níí jẹ́ atọ́ka àsìkò ọjọ́-iwájú tí máa sì jẹ́ atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀
bárakú nínú ẹ̀ka-èdè yìí.
Àpẹẹrẹ irú gbólóhùn yìí ni Títí ì níí máa lọ.
Yàtọ̀ sí kò
tí olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá ń lò fún atọ́ka ìyísódì ní ibi tí ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú ti
lo ì, atọ́ka kan náà ni àwọn ẹ̀ka-èdè méjèèjì ń lò fún ibá-ìṣẹ̀lẹ̀
bárakú àti àsìkò ọjọ́-iwájú; àwọn atọ́ka náà ni níí fún àsìkò ọjọ́-iwájú àti
máa fún ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ bárakú. Àpẹẹrẹ gbólóhùn tí ó fi èyí hàn nínú
olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá ni Títí kò níí máa lọ.
[1] Kujore,
O.I. ni ó kọ bébà yìí.
Comments
Post a Comment