Àsìkò Afànámónìí àti Ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ Àṣetán nínú Ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú àti Olórí Ẹ̀ka-èdè Yorùbá

 

Àsìkò Afànámónìí àti Ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ Àṣetán nínú Ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú àti Olórí Ẹ̀ka-èdè Yorùbá


Atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àṣetán[1] nínú ẹ̀ka-èdè ìjẹ̀bú nígbà tí ó bá àsìkò afànámónìí jẹ yọ nínú gbólóhùn ni ti. Mọ́fíìmù òfo ni atọ́ka àsìkò afànámónìí nínú ẹ̀ka-èdè yìí. Gbólóhùn tí a fi ṣe àpẹẹrẹ ni Títí ti lọ[2].   

 

Irú mọ́fíìmù kan náà ni ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú àti olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá ń lò láti tọ́ka àsìkò afànámónìí àti ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àṣetán. Mọ́fíìmù òfo ni wọ́n ń lò láti tọ́ka àsìkò afànámónìí tí wọ́n sì ń lo ti láti tọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àṣetán. Gbólóhùn tí ó fi èyí hàn nínú olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá ní Títí ti lọ.

 

Nínú gbólóhùn àyísódì tí ó ní ibá ìṣẹ̀lẹ̀ àṣetán àti àsìkò afànámónìí nínú, ì ni atọ́ka ìyísódì tí ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú máa ń lò nígbà tí atọ́ka àsìkò afànámónìí àti ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àṣetán jẹ́ òfo. Àpẹẹrẹ irú gbólóhùn yìí ni Títí ì lọ. Atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àṣetán tí ó jẹ́ òfo yìí, ẹ̀dà ni ó jẹ́ fún tíì tí ó jẹ́ atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àṣetán nínú ẹ̀ka-èdè yìí. Èyí ni a rí ní gbólóhùn yìí: Títí ì tíì lọ. Ẹ̀dà mìíràn tí atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àṣetán yìí ní ninú ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú ni máì bí ó ṣe hàn nínú gbólóhùn Títí ì máì lọ.

 

Ní ibi ti ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú ti ń lo ì fún atọ́ka ìyísódì tí ẹ̀ka-èdè yìí sì ń lo tíì, máì àti mófíìmù òfo fún atọ́ka fún ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àṣetán, ko ò àti òì ni olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá ń lò fún atọ́ka ìyísódì. Tíì àti mófíìmù òfo ni olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá ń lò fún atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àṣetán. Àwọn ẹ̀ka-èdè méjèèjì yìí ni ó ń lo mófíìmù òfo fún àsìkò afànámónìí. Àwọn gbólóhùn tí ó fi èyí hàn nínú olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá ni Títí kò tíì lọ, Títí ò tíì lọ, Títí òì tíì lọ àti Títí òì lọ.

Comments

Popular posts from this blog

YORÙBÁ LITERATURE E-LIBRARY

SYNTAX AND GRAMMATICAL THEORIES E-LIBRARY SECTION

YORÙBÁ GRAMMAR E-LIBRARY SECTION