Arọ́pò-Orúkọ Ẹni Kìíní Ẹyọ ní Ipò Olùwà nínú Ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ (First Person Singular Pronoun in Subject Position in Ifẹ Dialect)

 

Arọ́pò-Orúkọ Ẹni Kìíní Ẹyọ ní Ipò Olùwà nínú Ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ (First Person Singular Pronoun in Subject Position in Ifẹ Dialect)

Credit: Prof L. O. Adewole
Yoruba for academic purpose



Ní ipò olùwà, ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ ní àwọn arọ́pò-orúkọ wọ̀nyí: mo/mọ, o/ọ, ó/ọ́, a, ẹ, ighán.

Mo jó (Mo jó) 'I danced'
Mọ lọ (Mo lọ) 'I went'
 O jó (O jó) 'You danced'
Ọ lọ (O lọ) 'You went'
Ó jó (Ó jó) 'He danced'
Ọ́ lọ (Ó lọ) 'He went'
A jó (A jó) 'We danced'
A lọ (A lọ) 'We went'
Ẹ jó (Ẹ jó) 'You (pl.) danced'
Ẹ lọ (Ẹ lọ) 'You (pl.) went'
Ighán jó (Wọ́n jó) 'They danced'
Ighán lọ (Wọ́n lọ) 'They went'

Hámònì fáwẹ̀lì ni ó máa ń sọ irú ẹ̀dà arọ́pò-orúkọ tí a máa lò ṣáájú ọ̀rò-ìṣe. Bí ọ̀rọ̀-ìṣe (ní pàtàkì, ọ̀rò-ìṣe onísílébù kan)[1] bá ni fáwẹ̀lì a/ẹ/ọ, arọ́pò-orúkọ  mọ/ọ/ọ́ ni a ó lò gẹ́gẹ́ bi olùwà rẹ̀.

Mọ rà á (Mo rà á) 'I bought it'
Mọ lọ (Mo lọ) 'I went'
Mọ jẹ́ (Mo jẹ́) 'I ate it'

Bí ọ̀rò-ìṣe bá ní fáwẹ̀lì e/i/o/u, arọ́pò-orúkọ mo/o/ó ni a ó lò ní ipò olùwà rẹ̀.

Mo sé (Mo ṣé é) 'I did it'
Mo ki (Mo kí i) 'I greeted him/her'
Mo fò ó (Mo fò ó) 'I jumped it'
Mo bu (Mo bú u) 'I abused him/her/it'

A ó ṣe àkíyèsí pé a kò lè fi àbùdá gígùn àti kúkurú ya arọ́pò-orúkọ ẹka-èdè Ifẹ̀ sọ́tọ̀ sí arọ́pò afarjorúkọ ẹ̀ka-èdè náà gégẹ́ bí ó ṣe máa ń wáyé nínú olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá. Àwọ̀n tí ó máa ń fi àbùdá kúkúrú àti gígùn ya arọ́pò-orúkọ sọ́tọ̀ sí arọ́pò afarajorúkọ máa ń sọ pé gbogbo arọ́pò-orúkọ ni ó ní sílébù kan nígbà tí arọ́pò afarajorúkọ ní sílébù méjì. Ní èkà-èdè Ifẹ̀, a rí arọ́pò-orúkọ, ‘ighán’, tí ó ní sílébù méjì bíi ti àwọn arọ́pò afarajorúkọ èmi/ìwọ̀/òun/ìghà/ẹ̀ghin/ìghàn.

Èmí lọ (Èmí lọ) 'I went'
Ìwọ́ lọ (Ìwọ́ lọ) 'You went'
Ìghá lọ (Àwá lọ) 'We went'
Ẹ̀ghín lọ (Ẹ̀yín lọ) 'You (pl.) went'
Ìghán lọ (Àwọ́n lọ) 'They went'
Ighán lọ (Wọ́n lọ) 'They went'.




[1] Bí ọ̀rò-ìṣe bá ní ju sílébù kan lọ, orí fáwẹ̀lì tó ṣaájú gbogbo fáwẹ̀lì tí ọ̀rọ̀-ìṣe yìí ní ni hámónì fáwẹ̀lì yóò ti ṣiṣẹ́.

Comments

Popular posts from this blog

YORÙBÁ LITERATURE E-LIBRARY

SYNTAX AND GRAMMATICAL THEORIES E-LIBRARY SECTION

YORÙBÁ GRAMMAR E-LIBRARY SECTION