Arọ́pò-orúkọ Ẹni Kẹ́ta Ẹyọ nínú Ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀
Arọ́pò-orúkọ Ẹni Kẹ́ta Ẹyọ nínú Ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀
Tí a bá wo àwọn gbólóhùn bíi kì í lọ
tàbí kò lọ nínú olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá, a ó rí í pé olùwà wọn tí ó jẹ́
arọ́pò-orúkọ ẹni kẹ́ta ẹyọ kò
hànde[1].
Tí a bá wo àwọn gbólóhùn méjèèjì wọ̀nyí nínú ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀, ohun tí a ó sọ ni
pé òfin àìsí arọ́pò-orúkọ ẹni kẹ́ta ẹyọ aṣolùwà yìí kò sí nínú ẹ̀ka-èdè
Ifẹ̀. A sọ èyí nítorí pé dípò kì í lọ, ohun tí wọn yóò sọ nínú ẹ̀ka-èdè ifẹ̀ ni Ẹ́ ẹ̀ẹ́ lọ ní ibi tí ẹ́ àkọ́kọ́ ti jé olùwà tí ẹ́ẹ̀
sì jẹ́ atọ́ka ìyísódì. Tí a bá sì tún wo kò lọ tí olórí ẹ̀ka-èdè
Yorùbá máa sọ, ohun tí ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ máa sọ ni Ẹ́ ẹ̀ lọ tí ẹ́ àkọ́kọ́ jé olùwà tí ẹ̀
kejì sì jẹ́ atọ́ka ìyísódì.
Tí ó bá
tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí arọ́pò-orúkọ ẹyọ aṣolùwà ni, ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ kí bá tilẹ̀
yọ ara rẹ̀ lẹ́nu láti ní ọ̀kan. Ohun tí ó jẹ́ kí á sọ eléyìí ni pé gbólóhùn
tí ó bá ní arọ́pò-orúkọ ẹni kẹ́ta ẹyọ gẹ́gẹ́ bí olùwà àti eléyìí tí ó bá ní
ẹni kejì ọ̀pọ̀ gẹ́gẹ́ bí olùwà máa ń ní pọ́nna tí ó jẹ́ pé sàkáni ibi tí a ti
lò wọ́n ló máa ń yanjú pọ́nna yìí nínú ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀. Ẹ wo àwọn gbólóhùn wọ̀nyí, Ẹ́ ẹ̀ lọ (kò lọ). A lè túmọ̀
olùwà, ẹ́ sí ẹni kẹ́ta ẹyọ tàbí
ẹni kéjì ọ̀pọ̀. Tí ó bá jẹ́ pé kò sí arọ́pò-orúkọ ẹni kẹ́ta aṣolùwà
ni, kò yẹ kí ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ ní nínú gbólóhùn àyísódì. Eléyìí ni ẹ̀ka-èdè náà
ìbá fi yanjú pọ́nna tí ó wà láàrin arọ́pò-orúkọ ẹni kẹ́ta ẹyọ aṣolùwà àti
arọ́pò-orúkọ ẹni kejì ọ̀pọ̀ aṣolùwà nínú gbólóhùn àyísódì, Ẹ́
ẹ̀ lọ tí ó ní pọ́nna yìí.
Kì í ṣe
pé ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ kò gbìyànjú láti yanjú pọ́nna yìí náà; ó kàn jẹ́ pé kò ṣe é
délẹ̀ ni. Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ni pé àǹkóò fáwẹ̀lì wà fún arọ́pò-orúkọ ẹni kẹ́ta ẹyọ aṣolùwà
eléyìí tí kò sí fún ẹni kejì ọ̀pọ̀ aṣolùwà. Ẹ wo àwọn gbólóhùn wọ̀nyí, É
è sé. Eléyìí ni ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ máa ń lò níbí tí olórí ẹ̀ka-èdè ti máa lo Kò ṣe é ní ibi tí gbólóhùn olórí
ẹ̀ka-èdè kò ti ní olùwà ṣùgbọ́n tí ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ ní. Ní ibi tí olórí-èka-èdè ti sọ pé Ẹ kò ṣe é, èka-èdè Ifẹ̀ yóò sọ pé Ẹ́ ẹ̀ sé
ní ibi tí aǹkóò fáwẹ̀lì kò ti níí wáyé.
Ìgbà
mìíràn tilẹ̀ wà nínú ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ tí ó jẹ́ pé ẹ̀ka-èdè yìí lè pa arọ́pò-orúkọ
ẹni kẹ́ta jẹ ní
wọ̀fún ní ibi tí olórí ẹ̀ka-èdè kò ti lè pa á jẹ. Ẹ wo àwọn gbólóhùn wọ̀nyí: (i) Ó ní òun mọ̀ ọ́n (ii) Kò ní òun mọ̀ ọ́n. Ó nínú gbólóhùn (i) ni àwọn onígírámà kan pè ní
sílébù olóhùn òkè tí àwa pè ní olùwà. Tí a bá wo (ii), á ó rí i pé wúnrẹ̀n tí a pè ní
olùwà tí àwọn kan pè ní
sílébù olóhùn òkè yìí kò jẹ yọ ṣááju kò. Àìjẹyọ wúnrẹ̀n yìí ṣáájú kò
jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìdí tí wọ́n fi sọ pé kò sí arọ́pò-orúkọ ẹni kẹ́ta aṣolùwà nínú olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá.
Tí a bá
wo ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀, ọ̀nà mẹ́ta ni a lè gbà sọ Ó ní òun mọ̀ ọ́n. Àwọn
ọ̀nà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni: (i) Ó wí òun
mọ̀ ọ́n (ii) Ó ghí
òun mọ̀ ọ́ (iii) Ghí òun
mọ̀ ọ́.
A ó ṣe àkíyèsí
pé gbólóhùn (iii) kò ní ó tí àwa pè ní olùwà. Tí a bá wá wo kò ní òun
mọ̀ ọ́n tí ó
jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn irú gbólóhùn ti wọ́n máa ń lò láti sọ pé kò sí arọ́pò-orúkọ ẹni
kẹ́ta aṣolùwà nínú olorí ẹ̀ka-èdè Yorùbá, ọ̀nà méjì tí a ti lè tún gbólóhùn yìí sọ nínú
ẹ̀ka-èdè Ìfẹ̀ ni ó gbọ́dọ̀ ní olùwà tàbí wúnrẹ̀n tí wọ́n pè ní sílébù
olóhùn òkè. Ẹ wo àwọn gbólóhùn wọ̀nyí: (i) É è wí òun mọ̀ ọ́n (ii) É è ghí òun mọ̀ ọ́n (iii) *È ghí òun mọ̀
ọ́n. Gbólóhùn
(iii) tí kò ní olùwà bíi ti olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá tí è jẹ́
atọ́ka ìyísódì kóbofinmu.
Nínú gbólóhùn oní-kò sí pàápàá tí olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá
kìí tií lo arọ́pò-orúkọ ẹni kẹ́ta ẹyọ, ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ máa ń lò ó. Ẹ wo àwọn
gbólóhùn wọ̀nyí: Olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá: Kò sí owó; Ẹ̀ka-èdè
Ifẹ̀: É è sí owó ní ibi tí É ti jẹ́ arọ́pò-orúkọ nínú ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀.
[1] Wo A. Bamgbose (1990) Fonọ́lọ́jì àti Gírámà Èdè Yorùbá. Ibadan, Nigeria: University Press PLC àti O Awobuluyi (2013), Ẹ̀kọ́ Gírámà Èdè Yorùbá. Osogbo, Nigeria: Atman Limited.
[2] OSUBA NLA FUN PROF L.O ADEWOLE
Comments
Post a Comment