Àgbéyẹ̀wò Iṣẹ́ Owólabí (1984, 1985, 1995) lórí Mofọ́lọ́jì
Àgbéyẹ̀wò Iṣẹ́ Owólabí (1984, 1985, 1995) lórí Mofọ́lọ́jì
Credit: Prof L. O. Adewole
Yoruba for academic purpose
Iṣẹ́ Owólabí (1984) ṣàlàyé ọ̀nà tí Yorùbá ń gbà ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ tuntun láti ara
àfòmọ́-ìbẹ̀rẹ̀ àti atọ́ka àfikún. Ó pín àwọn àfòmọ́-ìbẹ̀rẹ̀ sí oríṣìí méjì.
Àwọn tí wọ́n lè bá ọ̀rọ̀-ìṣe tàbí àpólà ìṣe rìn àti àwọn tí wọ́n ń bá
ọ̀rọ̀-orúkọ tàbí àpólà orúkọ rìn. Àwọn tí a lè so mọ́ àpólà ìṣe láti ṣẹ̀dá
ọ̀rọ̀ tuntun ní èyíkéyìí fáwẹ̀lì àìránmúpè[1] tí ó ní yálà àmì
ohùn ìsàlẹ̀ tàbí ti àárín,
bí àpẹẹrẹ {ẹẹ-},
{àì-}, {òǹ̀-}, {àti-}, {olù}.
Yàtọ̀
sí àwọn àfòmọ́-ìbẹ̀rẹ̀, àwọn atọ́ka àfikún tí Owólabí (1984) ṣàlàyé pé a fi ń ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ ni: kí,
pé, bí àti tí. Gbólóhùn ní a máa ń so wọ́n mọ́, f.a.
i. Ṣadé ga (GB) → Pé Ṣadé ga (OR) [Pé Ṣadé ga dára]
ii. Olú ní owó (GB) → kí Olú ní owó (OR) [Mo fẹ́ kí Olú ní owó]
iii. Bọ́lá ṣe oríire (GB) → ti Bọ́lá ṣe oríire (OR) [Ó dára ti Bọ́lá ṣe oríire]
Iṣẹ́ rẹ̀ yìí ṣe àfihàn ìtumọ̀ àwọn àfòmọ́-ìbẹ̀rẹ̀
wọ̀nyí. Bákan náà, ó tún pín àwọn ọ̀rọ̀-aṣẹ̀dá sí ìsọ̀rí ọ̀rọ̀-orúkọ
àfòyemọ̀, àrídìmú, èlò, òǹ̀kà, abbl.
Owólabí
(1985) ṣàlàyé lórí àpètúnpè gẹ́gẹ́ bíi ète fún ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀-orúkọ inú èdè
Yorùbá. Oríṣìí ìlànà àpètúnpè méjì ló mẹ́nu bà. Àwọn ni àpètúnpè ẹlẹ́bẹ àti àpètúnpè
kíkún. A lè ṣe àpètúnpè ẹlẹ́bẹ síwájú (ilé ńlá → ilé ńlá ńlá[2]) tàbí sẹ̀yìn (lọ
→ lílọ[3]). Àpètúnpè kíkún
lè jẹ́ èyí tí a ṣe sí:
i. àpólà ìṣe, f.a.
ii. àpólà
orúkọ, kí a to wá fi ẹ̀rún tàbí mọ́fíìmù kan bọ àárín àwọn ọ̀rọ̀-orúkọ
méjèèjì tí àpètúnpè ti bá, f.a.
(b) i. {-kí-}; bàtàkíbàtà, ilékílé, ayakáya,
adékádé, ọ̀rọ̀kọrọ̀
ii. {-kú-};
ìsọkúsọ
i.
{-dé-};
kòtòdékòtò, ẹ̀yàdẹ́yà, okodóko
ii.
{-ní-};
ọ̀pọ̀lọpọ̀, ògbólògbó, àgbàlagbà
iii.
{-bí-};
iyebíye, àràbarà, owóbówó
iv.
{-mọ́-};
bàtàmọ́bàtà, owómówó, ọlámọ́lá
v.
{-oní-};
kọkọrọ-oníkọ́kọ́rọ́, ilé-onílé, aṣọ-aláṣọ, ẹmu-ẹlẹ́mu, abbl.
iii. àpólà orúkọ láìfi ẹ̀rún, tàbí mọ́fíìmù kan
bọ̀ ọ́ láàárín. Ìsọ̀rí méjì ni àwọn ọ̀rọ̀-aṣẹ̀dá báyìí ní.
Oríṣìí àpẹẹrẹ méjì tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí àkọ́kọ́.
(a) Ọ̀rọ̀-orúkọ
onísílébù méjì tí àpètúnpè bá a: fáwẹ́lì tó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀-orúkọ kejì àti ohùn
rẹ̀ gbọ́dọ̀ ràn mọ́ fáwẹ̀lì tó gbẹ̀yìn ọ̀rọ̀-orúkọ kìn-ín-ní; àti ohùn rẹ̀,
b.a (ọdún → ọdún ọdún → ọdọọdún).
(b)
Ọ̀rọ̀-orúkọ tí àpètúnpè bá ju sílébù méjì lọ: a óò dín ọ̀rọ̀-orúkọ àkọ́kọ́ kù sí sílébù méjì, lẹ́yìn náà
fáwẹ̀lì tó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀-orúkọ kejì àti ohùn rẹ̀ yóò ràn mọ́ fáwẹ̀lì tó gbẹ̀yìn
ọ̀rọ̀-orúkọ kìn-ín-ní (tí ìdínkù bá) àti ohùn rẹ̀ nínú àpètúnpè, b.a.
(ojúmọ́
→ ojúmọ́ ojúmọ́ →
ojú ojúmọ́ →
ojoojúmọ́)
Ìsọ̀rí kejì àwọn ọ̀rọ̀-orúkọ tí Owólabí ní a fi ète àpètúnpè ṣẹ̀dá
wọn láìfi mọ́fíìmù tàbí ẹ̀rún kan bọ̀ wọ́n láàárín ni:
a. kọ́bọ̀-kọ́bọ̀ (→kọ́bọ̀),
mélòó-mélòó (→mélòó)
Bákan náà, Owólabí (1985) ṣàlàyé pé a
le ṣe àpètúnpè sí ọ̀rọ̀-asopọ̀ fún ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, f.a.
b. ṣùgbọ́n → ṣùgbọ́n-ṣùgbọ́n
tàbí
→ tàbí-tàbí, abbl.
Owólabí (1995) ṣàlàyé àwọn àfòmọ́-ìbẹ̀rẹ̀ fún ìṣẹ̀dá-ọ̀rọ̀ àti ìpín-sí-ìsọ̀rí wọn. Owólabí
(1995) fi kún àwọn àfọ̀mọ́-ìbẹ̀rẹ̀ ti (1984). Àwọn tó fi kún wọn ni {ù-}[5], {oń-}, àti
{oní-}. Owólabí pín àwọn àfòmọ́-ìbẹ̀rẹ̀ yí sí ìsọ̀rí méjì. Bí a bá wo àlàyé
Owólabí (1995), ò jọ pé ó gbà wí pé {ẹẹ-} àti {olù-} kìí ṣe àfòmọ́-ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe fi hàn ni
(1984).
Ó
ṣàlàyé pé àwọn tó wà ní kan máa ń bá ọ̀rọ̀-ìṣe, àpólà ìṣe àti ídíófóònù ajẹmọ́-àpèjúwe rìn. Àwọn kan[6] máa ń bá
ọ̀rọ̀-orúkọ àti àpólà orúkọ rìn nígbà tí àwọn mìíràn lè bá ọ̀rọ̀-orúkọ tàbí àpólà orúkọ
rìn.
b alágbára (¬ oní-agbára)
olòṣì (¬ oni-òṣì)
Nínú
‘àlọ’, lọ ni IṢ tí {à-} bá
rìn láti ṣẹ̀dá àlọ, APIṢ ṣe
iṣẹ́ àti {ò-} ni a fi ṣẹ̀dá òṣìṣẹ́ nígbà tí a ṣẹ̀dá ọ̀pẹ́lẹ́ńgẹ́ láti ara
ídíófóònù ajẹmọ́-àpèjúwe pẹ́lẹ́ńgẹ́ àti {ọ̀-}. Gẹ́gẹ́ bí àlàyé
Owólabí pé a lè so àwọn àfòmọ́-ìbẹ̀rẹ̀ kan mọ́ ọ̀rọ̀-orúkọ
tàbí àpólà orúkọ láti ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ tuntun, àpẹẹrẹ irú ọ̀rọ̀-aṣẹ̀dá bẹ́ẹ̀ ni àkíké → àáké.
Owólabí
(1995) fi àwòrán-atọ́ka igi ṣàlàyé àìlerìnpọ̀ àwọn àfòmọ́-ìbẹ̀rẹ̀ kan àti ọ̀rọ̀-orúkọ/àpólà orúkọ, ó sì tún ṣàlàyé
àìlèrìnpọ̀ àwọn ti àwọn mìíràn àti ọ̀rọ̀-ìṣe,
àpólà-ìṣe tàbí ídíófóònù ajẹmọ́-àpèjúwe. Bákan náà, ó ní àwọn kan máa ń yí ìsọ̀rí
ọ̀rọ̀ padà nígbà tí àwọn ti mìíràn kìí ṣe bẹ́ẹ̀.
Àwọn tí kan lè bá ara rìn.
ÀKÓJỌPỌ̀ ORÚKỌ ÌWÉ
Adeṣọla,
O. (2008), “The Linguistic Forms of Olú Ọmọ”, in
A. Akinyemi àti T. Falọla (eds.) Emerging
Perspeciẹes on Akinwumi Iṣọla, pp. 189-204. Trenton: Africa
World Press Inc.
Adewọle,
L.O. (1986), “The Yorùbá High Tone Syllable Reẹisited”, Work in Progress 19:
81-94, Edinburgh: Department of
Linguistics, Uniẹersity of Edinburgh.
Adewọle,
L.O. (1987), The Yoruba Language: Published Works and Doctoral
Dissertations: 1843-1986. Hamburg: Helmut Buske Verlag.
Adewọle,
L.O. (1988), “The Categorial Status and the Functions of the Yoruba Auxiliary
Ẹerbs with Some Structural Analyses in GPSG.”, Ph.D. Dissertation, Unieversity of Edinburgh.
Adewọle,
L.O. (1991), “Heads Without Bars: A Solution to the Sentential Status of the
Yorùbá Focus and Relatiẹe Constructions”, Odu: A Journal of West African
Studies, 38:19-43.
Adewọle,
L.O. (2000a), “Negation in Ifẹ: A Yorùbá Dialect”, Journal
of Asian and African Studies (Tokyo, Japan).
Adewọle,
L.O. (2000b), “Heads in Yorùbá Derieved Words”, Calgary Working
Papers in Linguistics (Canada) 22:147-156.
Adewọle,
L.O. (2008), “Iṣọla on
Issues in Yorùbá Language”, in A. Akinyemi àti T. Falọla
(eds.) Emerging Perspecieves on Akinwumi Iṣọla, pp. 177-188. Trenton: African
World Press, Inc.
Adewọle,
L.O. (2015), “Àtamọ́”, yorubafracademicpurposeblogspot.com
(accessed on 26/08/2016).
Adewọle, L.O. (2015), “Dahl
(1985) and The Yorùbá Perfectieve”, yorubaforacademicpurposeblogspot.com
(accessed on 27/5/2017).
Adewọle, L.O. (2016), “Ìfi
àfòmọ́wájú Ṣẹ̀dá Ọ̀rọ̀-Orúkọ nínú Èdè Yorùbá (Derieving Nouns in Yorùbá with the Use of Prefix)”, yorubaforacademicpurposeblogspot.com
(accessed on 09/11/2016).
Adewọle, L.O. (2016),
“Ìṣẹ̀dá-ọ̀rọ̀ nínú Orin Ewúro (Ìpàjùbà)”, yorubaforacademicpurposeblogspot.com
(accessed on 09/11/2016).
Adewọle, L.O. (2016), “Sources
and Status of the Syllabic Nasal in Yorùbá”, yorubaforacademicpurposeblogspot.com
(accessed on 27/5/2017).
Adìgbòlùjà,
C.A. (1946), African Family Physicians. Lagos: Ola-Oluwa Press.
Aina,
F. B. (2003), “Fonọ́lọ́jì
Àti Mọfọ́lọ́jì Ẹ̀ka-Èdè
Òrò Ní Ilẹ̀ Ìgbómìnà.”, M.A. Dissertation, Yunifásítì Adó-Èkìtì.
Ajiboye,
O. (2004), “Genitieve Construction in Yoruba.”,
Conference Paper Presented at the 35th Annual Conference on African
Linguistics, Haẹard Uniẹersity, Cambridge, April 2-4.
Ajiboye, O. àti R.
Dechaine (2004), “The Syntax and Semantics of Yoruba Duplicatieve Constructions.”, Conference Paper
Presented at the 35th
Annual Conference on African Linguistics, Haẹard Uniẹersity, Cambridge, April
2-4.
Akiyẹmi, A. and T.
Falọla (eds.) (2008), Emerging Perspectiẹe on Akínwùmí Ìṣọ̀lá.
Trenton: World Press Inc.
Anderson,
S.R. (2000), A-morphous Morphology.
Cambridge: Cambridge Unieversity Press.
Anderson,
S.R. (2002), “Where’s Morphology?”, Linguistic Inọuiry
13:571-612.
Andrew,
C. (2001), Syntax. Uniẹersity of Ariṣona. Oxford: Blackwell Publishers Inc.
U.S.A.
Andrew,
M. (2002), An Introduction to English
Morphology: Words and Their Structure. Edinburgh: Edinburgh Unieversity Press Ltd.
Asiyanbola,
A.A. (2003), “Word Formation and Inflections in English”, in L. Oyeleye and M. Olateju (eds.) Reading in Language and Literature. Ife: Obafemi Awolowo Unieversity Press Limited, Nigeria, pp. 47-66.
Awobuluyi,
O. (1978), Essentials of Yoruba Grammar. Ibadan: Unieversity Press Limited, Nigeria.
Awobuluyi,
O. (1990), (ed) Yorùbá Metalanguage (Èdè-Ìperí Yorùbá), Volume II.
Ibadan: Uniẹersity Press Plc.
Awobuluyi,
O. (1992), “Aspect of Contemporary Yorùbá in Dialectology Perspectiẹe” in Ìṣọ̀lá,
A. (ed) J. F. Ọdunjọ Memorial Lecture, 3:1-82. Ibadan: Johnmof Printer.
Awobuluyi,
O. (2008a), “On the So-Called Genitieve Morpheme in Standard Yoruba”,
nínú Ẹ̀kọ́ Ìṣẹ̀dá-Ọ̀rọ̀
Yorùbá, pp.
241-260. Àkúrẹ́: Montem Paperbacks.
Awobuluyi,
O. (2008b), “Mọ́fíìmù Kan Ṣoṣo ni
“àì” àbí Méjì”, nínú Ẹ̀kọ́ Ìṣẹ̀dá-Ọ̀rọ̀
Yorùbá, pp.
213-222. Àkúrẹ́: Montem Paperbacks.
Awobuluyi,
O. (2008c), Ẹ̀kọ́ Ìṣẹ̀dá-Ọ̀rọ̀
Yorùbá.
Àkúrẹ́: Montem Paperbacks.
Awobuluyi,
O. (2013), Ẹ̀kọ́
Gírámà Èdè Yorùbá. Òṣogbo: Atman
Limited.
Awobuluyi,
O. (2015). “Àwọn Atọ́ka
Amúpé Inú Èdè Yorùbá”, Yorùbá: Journal of Yoruba Studies Association of
Nigeria 8,
1: 18-30.
Awoyale, Y. (1974),
“Studies in the Syntax and Semantics of Yoruba Nominaliṣations.”, Ph.D. Dissertation,
Unieversity of Illinois, Urbana-Champaign.
Awoyale,
Y. (1981), “Nominal Compound Formation in Yoruba Ideophones”, Journal of
African Languages and Linguistics 3: 139-157.
Awoyale,
Y. (1995), “The Role of Functional Categories in Syntax: The Yoruba Case”, in K. Owolabi (ed.), Language in Nigeria. Essays in Honour of Ayo Bamgbose, pp. 113-127. Ibadan: Group
Publishers.
Bamgboṣe, A.
(1967), A Short Grammar. Ibadan:
Heineman Educational Books Ltd.
Bamgboṣe, A.
(1971), “The Verb-Infinitieve Phrase in Yoruba”, Journal of West African Languages.
ẸIII, 1:37-52.
Bamgboṣe, A.
(1980), “Pronoun, Concord and Pronominaliṣation”, Afrika und Ubersee LXIII:37-52.
Bamgboṣe, A. (1986), Yoruba: A Language in Transition. Ibadan: Odunjo Memorial
Lectures.
Bamgbose,
A. (1990), Fonoloji ati Girama Yoruba. Ibadan: Uniẹersity Press Plc.
Bamgbose,
A. (1992), (ed.), Yorùbá Metalanguage (Èdè-Ìperí Yorùbá), Volume I. Ibadan: University Press Plc.
Bolaji,
A. (2010), An Introduction to English Sentences. Ibadan: Scribo
Publications Limited.
Cann,
R. (1984), “Heads without Bars: A Theory of Phrase Structure”, An Unpublished
Paper.
Cann,
R. (1986), “The Structure of Words”, Work in Progress 19: 107-121,
Edinburgh: Department of
Linguistics, Uniẹersity of Edinburgh.
Chomsky, N. (1957),
Syntactic Structures. The Hague: Janua Linguam
Chomsky, N.
(1965), Aspects of Theory of Syntax.
Cambridge: MIT Press.
Chomsky, N. (1995),
The Minimalist Program. Cambridge: MIT Press.
Chomsky, N. (1981),
“Lecture on Goẹernment and Binding”, The Pisa Lecture, Foris:
Dordrecht.
Chomsky, N. (2006),
Language and Mind. Cambridge: Cambridge University Press.
Citation of
Professor Akinwumi Iṣọla, Nigerian National Order of Merit, Year 2000.
www.nnma.goẹ.ng
(accessed on 17/12/2016).
Cippolone, N., S.H. Keiser and S. Vasishth (1994), Language Files, Material for an Introduction to Language
and Linguistics. Columbus: Ohio State University Press.
Crystal, D. (2001), A Dictionary of Language. Chicago: University of Chicago Press.
Crowther, S.
(1852), Grammar of The Yoruba Language. London: Seeleys.
Cruttenden, A.
(2008), Gimson’s Pronunciation of English. UK: Hodder Education, Part of
Hachette Liẹre.
Ẹkundayọ, A.S.
(1975), “An Alternatiẹe to Lexical Insertion for Yorùbá Complex Noun”, Studies
in African Linguistics Supplement 1, 3:233-260.
Fabunmi, F.A.
(2006), “Àsìkò Àti Iba-Ìṣẹlẹ Nínú Èka-Èdè Yorùbá Mọfọlí.”, Ph.D.
Dissertation, Ọbafẹmi Awolọwọ University, Ile-Ifẹ.
Fágúnwà, D.O.
(1950), Ògbójú Ọdẹ Nínú Igbó Irúnmọlẹ̀. Ibadan: Nelson Publishers
Limited.
Federal Goẹernment
of Nigeria (FGN) (1990), Ọuadrilingua Dictionary of Legislatiẹe Terms.
Lagos: Nigeria
Gazdar, G., E. Klein, G. Pullum and I. Sag (1985), Generaliṣed Phrase Structure Grammar. Oxford: Basil
Blackwell Publisher Ltd.
Halliday, M.A.K. (1985a), Spoken and Written Language. Geelong, Ẹic.: Deakin University Press.
Halliday,
M.A.K. (1985b), “Systemic Background”, in J.D. Benson and W.S. Greaẹes (eds) Systemic Perspectives on Discourse, pp. 1–15. Reprinted in Halliday, M.A.K. (2003) On
Language and Linguistics, Ẹolume 3. New York: Continuum Press.
Halliday, M.A.K.
(2014), Halliday’s Introduction to Functional Grammar. Oxon: Routledge Milton Park Publication.
Horrocks, G.
(1987), Generatiẹe Grammar. London: Longman Publisher.
Ìṣọ̀lá,
A. (1983), Olú Ọmọ.
Ibadan: Onibọnoje Press and Books Industries.
Ìṣọ̀lá,
A. (1990), Ogún Ọmọdé.
Ibadan: University Press Plc.
Ìṣọ̀lá,
A. (1992), Ó Le
Kú. Ibadan: University Press Plc.
Ìṣọ̀lá,
A. (1994), Ikú
Olókùn Ẹṣin. Ibadan: Fountain Publications.
Ìṣọ̀lá,
A. (2001), Aké,
Ní Ìgbà Èwe. Ibadan: Bookcraft.
Ìṣọ̀lá,
A. (2008), Ṣaworoide. Ibadan: Uniẹersity Press Plc.
Katamba, F. (1993),
Morphology. New York: St Martin’s Press.
Katamba, F. àti J.
Stonham, (2006), Morphology. Hampshire: Palgrave Macmillan Publisher.
Klaẹan, J.L.
(1980), “Approaches to Uniẹersal Theory of Clitics.”, Ph.D. Dissertation, University of London.
Kyle, J. (2004), Introduction
to Transformational Grammar. Amherst: University of Massachusetts Press.
Lamidi, M.T. and
T.O. Ajongolo,
(2001), “The Head Parameter in Yorulish Morphology”, IHAFA: A Journal of African Studies IẸ, 1:84-92.
Leech, G. and M.
Short, (2007), Style in Fiction, A Linguistic
Introduction to English Fictional Prose. UK: Pearson Education Limited.
Lieber, R. (1981), On
the Organisation of Lexicon. Indiana: Indiana University Press.
Lieber, R. (1983),
“Argument Linking and Compounds in English”, Lingustics Inquiry,
14: 251-285.
Nida, A.E. (1949), Morphology,
The Descriptiẹe Anaylysis of Words. Ann Arbor: The University of Michigan Press.
Nigeria Educational
Research and Deẹelopment Council (NERDC) (1990), A Ẹocabulary of Primary
Science and Mathematics in Nine Nigerian Languages Ẹol. 1. Enugu: Fourth
Dimension Publishing Co. Ltd. for NERDC.
Ọdẹtayọ, J.A.
(1993), English-Yorùbá Dictionary of Engineering Physics, Ìwé Ìtumọ̀ Ọ̀rọ̀
inú Ẹ̀kọ́ Àrígbéwọ̀n. Lagos: University of Lagos Press.
Ogunwale, J.A.
(2002): “Ìhun àti Ìtumọ̀ Àwọn Wúnrẹ̀n Orúkọ Ajẹmọ́-Ẹni àti Ajẹmọ́-Ibi Nínú Èdè Yorùbá.”, Ph.D. Dissertation, Obafemi Awolowo University, Ile-Ife.
Ogunwale, J.A.
(2007), “Headhood in Yorùbá Nominal Compound”, South African Journal of
African Languages. 2:72-82
Olakolu,
O. (2013), “A Syntactic Analysis of Ògbójú Ọdẹ Nínú
Igbó Irúmọlẹ̀”, in
W. Adegbite, A. Ogunsiji, àti O.
Taiwo, (eds.) Lingustics and The Glocalisation of African Languages for
Sustainable Deẹelopment. A Festschrift In Honour of Prof. Kola Owolabi,
pp. 426-438. Ibadan: Uniẹersal Akada Books Limited, A Subsidiary of Centre for
Yorùbá Language Engineering.
Olakolu,
O. (2015), “Ìṣẹ̀dá
Àgékúrú Nínú Orúkọ-Ẹni Ní
Èdè Yorùbá”, nínú S.M. Raji, R. Fájẹ́nyọ̀,
M.M. Aderibigbe, R.A. Adesuyan, and I.F. Ojo, (eds.) Èdè, Àṣà àti
Lítíréṣọ̀ Yorùbá: Ìtàn-ò-ní-gbàgbé-yín: Olóyè Díípọ̀ Gbénró àti Alàgbà Fúnnṣọ́
Fátókun, pp. 168-173. Ibadan:
Masterprint Publishers, Ibadan, Nigeria.
Ouhalla, J. (1999),
Introducing Transformational Grammar from Principles and Parameters to
Minimalism. New York: Oxford Uniẹersity Press Inc.
Owolabi, K. (1984),
“Ìsọ̀rí Ọ̀rọ̀-Orúkọ tí A Ṣẹ̀dá Nípa Lílo Àfòmó-Ìbẹ̀rẹ̀ àti Atọ́ka-Àfikún nínú
Èdè Yorùbá” Láàńgbàsà (Jọ́nà Iṣẹ́ Akadá ní Èdè Yorùbá), 1:61-101.
Owolabi, K. (1985),
“Àpètúnpè Gẹ́gẹ́ bí Ète Fún Ìṣẹ̀dá Ọ̀rọ̀-Orúkọ nínú Èdè Yorùbá”, Láàńgbàsà (Jọ́nà Iṣẹ́ Akadá ní Èdè Yorùbá), 2:69-102.
Owolabi, K. (1992),
“Ṣíṣe Àtúpalẹ̀ Lítíréṣọ̀ Ní Ìbámu Pẹ̀lú Ìlànà Gírámà Onídàrọ Olófin Ìyídà:
Ewì Gẹ́gẹ́ bí Àpẹrẹ”, nínú Akínwùmí Ìṣọ̀lá (ed) New Findings in Yoruba
Studies. J. F. Ọdunjọ Memorial Lecture Series 3: 83-97. Ibadan: Odunjo
Memorial Lectures.
Owolabi, K. (1995),
“More on Yoruba Prefixing Morphology”, in K. Owolabi (ed), Language in Nigeria: Essay in
Honour of Ayo Bamgbose, pp. 92-112. Ibadan: Group Publishers.
Owolabi, K.
(2004a), Ìjìnlẹ̀ Ìtúpalẹ̀ Èdè Yorùbá, Fònẹ́tíìkì àti Fonọ́lọ́jì. Ibadan:
Onibọnoje Press & Book Industries (Nig.) Ltd.
Owolabi, K.
(2004b), “Deẹeloping a Strategy in the Formulation and Use of Yorùbá
Legislatiẹe Terms”, in K. Owólabí and A. Dasylẹa (eds.) Forms and
Functions of English and Indigeneous Languages in Nigeria: A Festcchrift in
Honour of Ayọ̀ Bánjọ, pp. 397-416. Ibadan: Group Publisher.
Oyelaran, O.O.
(1983), “Sources and Status of Syllabic Nasal in Yorùbá”, Paper
Presented at the Department of African Languages and Literatures , Uniẹersity
of Ife. Seminar Series on Monday May 16, 1983.
Oyelaran, O.O.
(1987), “Ọ̀nà Kan Kò Wọja: Mọfọ́lọ́jì Yorùbá”, Yorùbá: Journal of The Yoruba
Studies Association
of Nigeria, 1:25-44.
Oyelaran, O.O.
(2014), “Oríkì.”, nínú O.O. Oyelaran and L.O. Adewọle (eds) Ìṣẹ̀mbáyé àti
Ìlò Èdè, 158-183. Ileṣa: Elyon Publishers.
Peter, R. (2000), English
Phonetics and Phonology. Cambridge: Cambridge Uniẹersity Press.
Postma, G. (1995), Zero Semantics: A Study of the Syntactic Conception of
Ọuantificational Meaning.
Holland: Holland Institute of Generatiẹe Linguistics.
Pulleyblank, D.
(1986), “Clitics in Yorùbá”, Syntax and Semantics 9: 43-64. New York:
Academic Press.
Pulleyblank, D. àti
A. Akinlabi (1988), “Phrasal Morphology in Yorùbá”, Lingua, 74: 141-166.
Ọuirk, R. àti S.
Greenbaum, (1973), A University Grammar of English. Halow, England: Pearson Educational Limited.
Rowlands, E.C.
(1954), “Types of Word Junction in Yorùbá” Bulletin of the School of
Oriental and African Studies 16:376-388.
Rowlands, E.C.
(1969), Teach Yourself Yoruba. Edinburgh: The English Uniẹersity Press.
Selkirk, E.O.
(1982), The Syntax of Words. Cambridge: MIT Press
Spencer, A. (1991),
Morphological Theory: An Introduction to Word Structure in Generatiẹe
Grammar. Oxford: Basil Blackwell Publisher Ltd.
Ṣoyinka, W.
(1975), Death and The King’s Horseman. Ibadan: Spectrum Books
Limited.
Ṣoyinka, W.
(2014), Ake, The Years of Childhood. Ibadan: Bookcraft.
Taiwo, P.O. (2001),
“The Head Parameter in Yorulish Morphology”, IHAFA: A Journal of African
Studies IẸ, 1:84-92.
Taiwo, P.O. (2007),
“The Indiẹisibility of {ai-} in Standard Yoruba”, in O.M.
Ndimele (ed.) Nigerian Languages, Literatures, Culture &
Reforms: A Festschrift for Ayo Bamgbose, pp. 557-564. Port Harcourt:
Linguistic Association of Nigeria (LAN).
Taiwo, P.O. (2009),
“Headedness and The Structure of Yorùbá Compound Words.”, Taiwan Journal of Linguistics 1:27-52.
Taiwo, P.O. &
T. Olakolu (2012), “Orí Nínú Ìhun ọ̀rọ̀-Ìṣẹ̀dá”, Ọ̀panbata: Jọ́nà Ìmọ̀
Akadá 6:94-123.
Taiwo, P. O.
(2014), “The Morpho-Syntactic Interaction and the Deriẹation of Nominal
Compound in Yorùbá”, International Journal of Language Studies 8,
1:67-92.
Tomori, S.H.
(2005), The Morphology and Syntax of Present-day English: An Introduction.
Ibadan: Heinemann Educational
Books Ltd.
Wande, A. (2006), Ìjìnlẹ̀ Ohùn Ẹnu Ifá, Apá Kìn-ín-ní. Ibadan: University Press PLC.
Wande, A. (2006), Ìjìnlẹ̀ Ohùn Ẹnu Ifá, Apá Kejì. Ibadan: University Press PLC.
Walfram, Walt. (1974), “Generatiẹe Phonology: A
Basic Model”, Paper Presented at the Preconvention Workshop on Linguistics and Reading: Theory
into Practice, International Reading Association, 1-25.
Williams, E. (1981a), “Argument Structure and
Morphology”, The Linguistic Reẹiew 1: 81-114.
Williams, E. (1981b), “On the Notion of Lexical
Related Words and Head of a Word”, Linguistic Inọuiry 12,
2:245-274.
[2] Ńlá
la ṣe àpètúnpè rẹ̀ síwájú
[4] Àkíyèsí ni pé kìí ṣe àpètúnpè nìkan ló sọ́ jagunjagun di ọ̀rọ̀-aṣẹ̀dá tuntun, mọ́fíìmù òfo (ṣero morpheme) náà ń ṣiṣẹ́ nínú
irù ọ̀rọ̀ aṣẹ̀dá
báyìí.
[5]
Ìjẹyọ {ù-} jẹ mọ́ àwọn ẹ̀ka-èdè Yorùbá kan ṣùgbọ́n wọn máa ń jẹ yọ
nínú ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀-orúkọ aṣẹ̀dá nínú olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá gẹ́gẹ́ bí àfòmọ́-ìbẹ̀rẹ̀. Èyí ni yóò jẹ́ kí á
gba àbá Bámgbóṣe (1986:28) pé ó yẹ ká gbà á ní àfòmọ́ fún ìṣẹ̀dá-ọ̀rọ̀ nínú olórí
ẹ̀ka-èdè Yorùbá.
Comments
Post a Comment