Àgbéyẹ̀wò Iṣẹ́ Bámgbóṣé (1967) àti (1990) lórí Mofọ́lọ́jì
Àgbéyẹ̀wò Iṣẹ́ Bámgbóṣé (1967) àti (1990) lórí Mofọ́lọ́jì
Lábẹ́ orí tí Bámgbóṣé (1967) ti ṣàlàyé àpólà orúkọ ló ti
ya oríṣìí àwọn ọ̀rọ̀ méjì sọ́tọ̀[1].
Àkọ́kọ́ ni àwọn ọ̀rọ̀-orúkọ tó lè dá dúró[2] bíi ọmọ,
ìlú, ọ̀rọ̀, Olú, abbl. Oríṣìí ọ̀rọ̀ kejì ni àwọn tó pè ní ọ̀rọ̀-orúkọ ti
a ṣẹ̀dá nípa lílo àfòmọ́-ìbẹ̀rẹ̀ àti ọ̀rọ̀-ìṣe tàbí kíkàn ọ̀rọ̀-ìṣe pọ̀ mọ́ ọ̀rọ̀-orúkọ (ẹerb-nominal compound) àti lílo
àfòmọ́-ìbẹ̀rẹ̀ mọ́ ọ̀rọ̀-orúkọ tàbí ọ̀rọ̀-orúkọ àti ẹ̀yán rẹ̀. Ìlànà àpètúnpè
ni ìlànà mìíràn tó ṣàlàyé. Àwọn àfòmọ́-ìbẹ̀rẹ̀ tí à ń ta mọ́ ọ̀rọ̀-ìṣe tàbí
ìkànpọ̀ ọ̀rọ̀-ìṣe àti ọ̀rọ̀-orúkọ ni {à-}, {a-}, {ì-}, {àì-}, {àti-} gẹ́gẹ́
bí wọ́n ṣe hàn nínú àlọ (à-, lọ), akọrin (a-, kọ orin), ìdáwó
(ì-, da, owó), àìlówó (àì-, lówó), àtiṣiṣẹ́ (àti-, ṣiṣẹ́).
Àfòmọ́ tí Bámgbóṣé (1967) ní a máa ń kàn mọ́ ọ̀rọ̀-orúkọ ni {oní-}[3]. Èyí hàn nínú olówó
(oní-, owó), aláṣọ (oní-, aṣọ), ẹlẹ́ja (oní-, ẹja), ọlọ́mọ
(oní-, ọmọ), onílé (oní-, ilé). Bámgbóṣé (1967) gbà pé a lè ṣe
àpètúnpè sí kọ́ńsónáǹ̀tì àkọ́kọ́ ọ̀rọ̀-ìṣe, kí á wá kàn án mọ ọ̀rọ̀-aṣẹ̀dá, lẹ́yìn tí a ti fi fáwẹ́lì /i/ olóhùn òkè ya
kọ́ńsónáǹ̀tì méjì tó tẹ̀ lé ara wọn sọ́tọ̀, f.a. lọ → lílọ (l + í + lọ), ṣe
→ ṣíṣe (ṣ + í + ṣe), kọrin
→ kíkọrin (k + í + kọ +
orin). Bámgbóṣé (1967) ní a lè ṣe àpètúnpè sí ọ̀rọ̀-ìṣe àti àbọ rẹ̀, f.a. [wolé
(wo + ilé) → woléwolé];
[pana (pa + iná) → panápaná].
Ẹ̀yà àpètúnpè kan ni iṣẹ́kíṣẹ́ [iṣẹ́ (OR) + kí + iṣẹ́ (OR)] àti ẹnikẹ́ni
[ẹni OR) + kí + ẹni (ỌR)]. Bákan náà, ó ní a máa ń ṣe àpètúnpè sí
ọ̀rọ̀-orúkọ, b.a. ọdún → ọdọọdún[4]; ọ̀sẹ̀ → ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀.
Bámgbóṣé
(1990) ṣe àfikún sí àlàyé lórí ọ̀nà tí à ń gbà ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀-orúkọ. Nínú
iṣẹ́ yìí, ó ṣàfihàn àwọn àfòmọ́[5] mìíràn. Àwọn ni
{òǹ̀-}, {oni-}, {àbí-} àti {-kí-}, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe hàn nínú òǹ̀tẹ̀wé (òǹ̀-, tẹ̀wé), ẹlẹ̀gàn (oni-, ẹ̀gàn) àti
aboyún (abi-, oyún).
Bámgbóṣé(1990)
ṣe àfihàn oríṣìí {àti-}[6] méjì gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe jẹ yọ nínú àtòkè
(àti-, òkè), àtilọ (àti-, lọ). Bámgbóṣe (1990) ṣe àfihàn lílo àfòmọ́ méjì àti ọ̀rọ̀-ìṣe méjì láti ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀-orúkọ. Ọ̀kan nínú àfòmọ́
yìí yóò jẹ́ ti ìyísódì (jẹ; jẹ tán → àjẹàìjẹtán → ajẹìjẹtán → àjẹẹjẹtán)[7]. Bákan náà, iṣẹ́
rẹ̀ ṣàlàyé ìsọdorúkọ tó máa ń wáyé láti ara
gbólóhùn àti àwọn wúnrẹ̀n kan bíi Pé, Kí, abbl., (wọ́n lọ → pé wọ́n lọ). Ó ṣàlàyé
ìṣẹ̀dá àwọn ọ̀rọ̀ bíi àádùn[8] ni abẹ́ àpètúnpè.
Ó tún ṣàlàyé pé ọ̀rọ̀-ìṣe/àpólà ìṣe kan le gbà àfòmọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n á sì
fún wa ní ìtumọ̀ kan náà, f.a. ìmọ̀ràn/àmọ̀ràn.
Bí ó ti lẹ̀
jẹ́ pé àlàyé Bámgbóṣé (1990) ju ti Crowther (1852) lọ lórí àwọn
ọ̀rọ̀-aṣẹ̀dá tí a sì tún rí ẹ̀rí lórí àfikún àwọn ọ̀rọ̀-aṣẹ̀dá àti awọn
afòmọ́ (yálà ti ìbẹ̀rẹ̀ àti àwọn tó pè ní àfòmọ́-àárín – ki, ni, abbl.), iṣẹ́
rẹ̀ kò lo tíọ́rì kan láti ṣe àtúpalẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀-aṣẹ̀dá. Bákan náà, iṣẹ́
rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára iṣẹ́ tí ó jẹ́ kí àkíyèsí àti àlàyé àwọn onímọ̀ èdè Yorùbá
pé méjì lórí àwọn mọ́fíìmù bíi {oní-}/{oni-}, {àì-}. Ewú kan tí
àtúnpínsísọ̀rí (àfòyemọ̀, olùṣe, èlò, àyísódì, ìní, àkópọ̀, atọ́kùn,
àtẹnumọ́) rẹ̀ lè ṣe ni pé, a lè rí àwọn àfòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ abẹ́ ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bíi
ẹ̀dà fún ara wọn nítorí pé àgbéyọ ìtumọ̀ kan náà ni wọ́n ń ṣe, bákan náà, a
sì lè rí àwọn kan tí wọ́n jẹ yọ ju abẹ́ ìsọ̀rí kan lọ. Ó sì ṣeé ṣe kí àtúnpínsísọ̀rí tí a lo ìlànà ìtumọ̀ fún yìí máà ní òpin, bí a bá ṣe lè ronú sí ni a ó ṣe lè pín wọn. Bí àpẹẹrẹ, a lè fi ìjẹ (ohun tí a lè jẹ), ìmu (ohun tí
a lè mu), abbl., kún àtúnpínsísòrí yìí.
[3] Bámgbóṣé (1967) ṣàlàyé pé bí a bá fi {oní-} kún
ọ̀rọ̀-orúkọ tí ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ jẹ́
èyíkèyí nínú fáwẹ̀lì /a, e, ẹ, i, o, ọ/, /l/ yóò rópò /n/, nígbà tí /o/ inú
{oní-} yóò yíra padà sí èyíkéyìí nínú àwọn fáwẹ̀lì tó bẹ̀rẹ̀ OR.
[4]
Fáwẹ̀lì tó gbẹ̀yìn ọ̀rọ̀-orúkọ àkọ́kọ́ àti ìró ohùn orí rẹ̀ yóò ràn mọ́ fáwẹ̀lì
àkọ́kọ́ ọ̀rọ̀-orúkọ kejì
[6]
A máa ń lo oríṣìí kìn-ín-ní mọ́
ọ̀rọ̀-orúkọ. Irú ìsọdorúkọ yìí ló pè ní ìsọdorúkọ atọ́kùn àti èyí tí à ń
lò mọ́
ọ̀rọ̀-ìṣe/àpólà ìṣe
[8] dùn → dídùn →àdídùn
→àádùn. Ó ti ṣàlàyé ìṣẹ̀dá “dídùn” tẹ́lẹ̀, ìpajẹ àti
àrànmọ́ ló sọ ọ́ di àádùn. A óò rì àfòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀
nínú àádùn.
ÀKÓJỌPỌ̀ ORÚKỌ ÌWÉ
Adeṣọla,
O. (2008), “The Linguistic Forms of Olú Ọmọ”, in
A. Akinyemi àti T. Falọla (eds.) Emerging
Perspeciẹes on Akinwumi Iṣọla, pp. 189-204. Trenton: Africa
World Press Inc.
Adewọle,
L.O. (1986), “The Yorùbá High Tone Syllable Reẹisited”, Work in Progress 19:
81-94, Edinburgh: Department of Linguistics,
Uniẹersity of Edinburgh.
Adewọle,
L.O. (1987), The Yoruba Language: Published Works and Doctoral
Dissertations: 1843-1986. Hamburg: Helmut Buske Verlag.
Adewọle,
L.O. (1988), “The Categorial Status and the Functions of the Yoruba Auxiliary
Ẹerbs with Some Structural Analyses in GPSG.”, Ph.D. Dissertation, Unieversity of Edinburgh.
Adewọle,
L.O. (1991), “Heads Without Bars: A Solution to the Sentential Status of the
Yorùbá Focus and Relatiẹe Constructions”, Odu: A Journal of West African
Studies, 38:19-43.
Adewọle,
L.O. (2000a), “Negation in Ifẹ: A Yorùbá Dialect”, Journal
of Asian and African Studies (Tokyo, Japan).
Adewọle,
L.O. (2000b), “Heads in Yorùbá Derieved Words”, Calgary Working
Papers in Linguistics (Canada) 22:147-156.
Adewọle,
L.O. (2008), “Iṣọla on
Issues in Yorùbá Language”, in A. Akinyemi àti T. Falọla
(eds.) Emerging Perspecieves on Akinwumi Iṣọla, pp. 177-188. Trenton: African
World Press, Inc.
Adewọle,
L.O. (2015), “Àtamọ́”, yorubafracademicpurposeblogspot.com
(accessed on 26/08/2016).
Adewọle, L.O. (2015), “Dahl
(1985) and The Yorùbá Perfectieve”, yorubaforacademicpurposeblogspot.com
(accessed on 27/5/2017).
Adewọle, L.O. (2016), “Ìfi
àfòmọ́wájú Ṣẹ̀dá Ọ̀rọ̀-Orúkọ nínú Èdè Yorùbá (Derieving Nouns in Yorùbá with the Use of Prefix)”, yorubaforacademicpurposeblogspot.com
(accessed on 09/11/2016).
Adewọle, L.O. (2016),
“Ìṣẹ̀dá-ọ̀rọ̀ nínú Orin Ewúro (Ìpàjùbà)”, yorubaforacademicpurposeblogspot.com
(accessed on 09/11/2016).
Adewọle, L.O. (2016), “Sources
and Status of the Syllabic Nasal in Yorùbá”, yorubaforacademicpurposeblogspot.com
(accessed on 27/5/2017).
Adìgbòlùjà,
C.A. (1946), African Family Physicians. Lagos: Ola-Oluwa Press.
Aina,
F. B. (2003), “Fonọ́lọ́jì
Àti Mọfọ́lọ́jì Ẹ̀ka-Èdè
Òrò Ní Ilẹ̀ Ìgbómìnà.”, M.A. Dissertation, Yunifásítì Adó-Èkìtì.
Ajiboye,
O. (2004), “Genitieve Construction in Yoruba.”,
Conference Paper Presented at the 35th Annual Conference on African
Linguistics, Haẹard Uniẹersity, Cambridge, April 2-4.
Ajiboye, O. àti R.
Dechaine (2004), “The Syntax and Semantics of Yoruba Duplicatieve Constructions.”, Conference Paper
Presented at the 35th
Annual Conference on African Linguistics, Haẹard Uniẹersity, Cambridge, April
2-4.
Akiyẹmi, A. and T.
Falọla (eds.) (2008), Emerging Perspectiẹe on Akínwùmí Ìṣọ̀lá.
Trenton: World Press Inc.
Anderson,
S.R. (2000), A-morphous Morphology.
Cambridge: Cambridge Unieversity Press.
Anderson,
S.R. (2002), “Where’s Morphology?”, Linguistic Inọuiry
13:571-612.
Andrew,
C. (2001), Syntax. Uniẹersity of Ariṣona. Oxford: Blackwell Publishers Inc.
U.S.A.
Andrew,
M. (2002), An Introduction to English
Morphology: Words and Their Structure. Edinburgh: Edinburgh Unieversity Press Ltd.
Asiyanbola,
A.A. (2003), “Word Formation and Inflections in English”, in L. Oyeleye and M. Olateju (eds.) Reading in Language and Literature. Ife: Obafemi Awolowo Unieversity Press Limited, Nigeria, pp. 47-66.
Awobuluyi,
O. (1978), Essentials of Yoruba Grammar. Ibadan: Unieversity Press Limited, Nigeria.
Awobuluyi,
O. (1990), (ed) Yorùbá Metalanguage (Èdè-Ìperí Yorùbá), Volume II.
Ibadan: Uniẹersity Press Plc.
Awobuluyi,
O. (1992), “Aspect of Contemporary Yorùbá in Dialectology Perspectiẹe” in Ìṣọ̀lá,
A. (ed) J. F. Ọdunjọ Memorial Lecture, 3:1-82. Ibadan: Johnmof Printer.
Awobuluyi,
O. (2008a), “On the So-Called Genitieve Morpheme in Standard Yoruba”,
nínú Ẹ̀kọ́ Ìṣẹ̀dá-Ọ̀rọ̀
Yorùbá, pp.
241-260. Àkúrẹ́: Montem Paperbacks.
Awobuluyi,
O. (2008b), “Mọ́fíìmù Kan Ṣoṣo ni
“àì” àbí Méjì”, nínú Ẹ̀kọ́ Ìṣẹ̀dá-Ọ̀rọ̀
Yorùbá, pp.
213-222. Àkúrẹ́: Montem Paperbacks.
Awobuluyi,
O. (2008c), Ẹ̀kọ́ Ìṣẹ̀dá-Ọ̀rọ̀
Yorùbá.
Àkúrẹ́: Montem Paperbacks.
Awobuluyi,
O. (2013), Ẹ̀kọ́
Gírámà Èdè Yorùbá. Òṣogbo: Atman
Limited.
Awobuluyi,
O. (2015). “Àwọn Atọ́ka
Amúpé Inú Èdè Yorùbá”, Yorùbá: Journal of Yoruba Studies Association of
Nigeria 8,
1: 18-30.
Awoyale, Y. (1974),
“Studies in the Syntax and Semantics of Yoruba Nominaliṣations.”, Ph.D. Dissertation,
Unieversity of Illinois, Urbana-Champaign.
Awoyale,
Y. (1981), “Nominal Compound Formation in Yoruba Ideophones”, Journal of
African Languages and Linguistics 3: 139-157.
Awoyale,
Y. (1995), “The Role of Functional Categories in Syntax: The Yoruba Case”, in K. Owolabi (ed.), Language in Nigeria. Essays in Honour of Ayo Bamgbose, pp. 113-127. Ibadan: Group
Publishers.
Bamgboṣe, A.
(1967), A Short Grammar. Ibadan:
Heineman Educational Books Ltd.
Bamgboṣe, A.
(1971), “The Verb-Infinitieve Phrase in Yoruba”, Journal of West African Languages.
ẸIII, 1:37-52.
Bamgboṣe, A.
(1980), “Pronoun, Concord and Pronominaliṣation”, Afrika und Ubersee LXIII:37-52.
Bamgboṣe, A. (1986), Yoruba: A Language in Transition. Ibadan: Odunjo Memorial Lectures.
Bamgbose,
A. (1990), Fonoloji ati Girama Yoruba. Ibadan: Uniẹersity Press Plc.
Bamgbose,
A. (1992), (ed.), Yorùbá Metalanguage (Èdè-Ìperí Yorùbá), Volume I. Ibadan: University Press Plc.
Bolaji,
A. (2010), An Introduction to English Sentences. Ibadan: Scribo
Publications Limited.
Cann,
R. (1984), “Heads without Bars: A Theory of Phrase Structure”, An Unpublished
Paper.
Cann,
R. (1986), “The Structure of Words”, Work in Progress 19: 107-121,
Edinburgh: Department of
Linguistics, Uniẹersity of Edinburgh.
Chomsky, N. (1957),
Syntactic Structures. The Hague: Janua Linguam
Chomsky, N.
(1965), Aspects of Theory of Syntax.
Cambridge: MIT Press.
Chomsky, N. (1995),
The Minimalist Program. Cambridge: MIT Press.
Chomsky, N. (1981),
“Lecture on Goẹernment and Binding”, The Pisa Lecture, Foris:
Dordrecht.
Chomsky, N. (2006),
Language and Mind. Cambridge: Cambridge University Press.
Citation of
Professor Akinwumi Iṣọla, Nigerian National Order of Merit, Year 2000.
www.nnma.goẹ.ng
(accessed on 17/12/2016).
Cippolone, N., S.H. Keiser and S. Vasishth (1994), Language Files, Material for an Introduction to Language
and Linguistics. Columbus: Ohio State University Press.
Crystal, D. (2001), A Dictionary of Language. Chicago: University of Chicago Press.
Crowther, S.
(1852), Grammar of The Yoruba Language. London: Seeleys.
Cruttenden, A.
(2008), Gimson’s Pronunciation of English. UK: Hodder Education, Part of
Hachette Liẹre.
Ẹkundayọ, A.S.
(1975), “An Alternatiẹe to Lexical Insertion for Yorùbá Complex Noun”, Studies
in African Linguistics Supplement 1, 3:233-260.
Fabunmi, F.A.
(2006), “Àsìkò Àti Iba-Ìṣẹlẹ Nínú Èka-Èdè Yorùbá Mọfọlí.”, Ph.D.
Dissertation, Ọbafẹmi Awolọwọ University, Ile-Ifẹ.
Fágúnwà, D.O.
(1950), Ògbójú Ọdẹ Nínú Igbó Irúnmọlẹ̀. Ibadan: Nelson Publishers
Limited.
Federal Goẹernment
of Nigeria (FGN) (1990), Ọuadrilingua Dictionary of Legislatiẹe Terms.
Lagos: Nigeria
Gazdar, G., E. Klein, G. Pullum and I. Sag (1985), Generaliṣed Phrase Structure Grammar. Oxford: Basil
Blackwell Publisher Ltd.
Halliday, M.A.K. (1985a), Spoken and Written Language. Geelong, Ẹic.: Deakin University Press.
Halliday,
M.A.K. (1985b), “Systemic Background”, in J.D. Benson and W.S. Greaẹes (eds) Systemic Perspectives on Discourse, pp. 1–15. Reprinted in Halliday, M.A.K. (2003) On
Language and Linguistics, Ẹolume 3. New York: Continuum Press.
Halliday, M.A.K.
(2014), Halliday’s Introduction to Functional Grammar. Oxon: Routledge Milton Park Publication.
Horrocks, G.
(1987), Generatiẹe Grammar. London: Longman Publisher.
Ìṣọ̀lá,
A. (1983), Olú Ọmọ.
Ibadan: Onibọnoje Press and Books Industries.
Ìṣọ̀lá,
A. (1990), Ogún Ọmọdé.
Ibadan: University Press Plc.
Ìṣọ̀lá,
A. (1992), Ó Le
Kú. Ibadan: University Press Plc.
Ìṣọ̀lá,
A. (1994), Ikú
Olókùn Ẹṣin. Ibadan: Fountain Publications.
Ìṣọ̀lá,
A. (2001), Aké,
Ní Ìgbà Èwe. Ibadan: Bookcraft.
Ìṣọ̀lá,
A. (2008), Ṣaworoide. Ibadan: Uniẹersity Press Plc.
Katamba, F. (1993),
Morphology. New York: St Martin’s Press.
Katamba, F. àti J.
Stonham, (2006), Morphology. Hampshire: Palgrave Macmillan Publisher.
Klaẹan, J.L.
(1980), “Approaches to Uniẹersal Theory of Clitics.”, Ph.D. Dissertation, University of London.
Kyle, J. (2004), Introduction
to Transformational Grammar. Amherst: University of Massachusetts Press.
Lamidi, M.T. and
T.O. Ajongolo,
(2001), “The Head Parameter in Yorulish Morphology”, IHAFA: A Journal of African Studies IẸ, 1:84-92.
Leech, G. and M.
Short, (2007), Style in Fiction, A Linguistic
Introduction to English Fictional Prose. UK: Pearson Education Limited.
Lieber, R. (1981), On
the Organisation of Lexicon. Indiana: Indiana University Press.
Lieber, R. (1983),
“Argument Linking and Compounds in English”, Lingustics Inquiry,
14: 251-285.
Nida, A.E. (1949), Morphology,
The Descriptiẹe Anaylysis of Words. Ann Arbor: The University of Michigan Press.
Nigeria Educational
Research and Deẹelopment Council (NERDC) (1990), A Ẹocabulary of Primary
Science and Mathematics in Nine Nigerian Languages Ẹol. 1. Enugu: Fourth
Dimension Publishing Co. Ltd. for NERDC.
Ọdẹtayọ, J.A.
(1993), English-Yorùbá Dictionary of Engineering Physics, Ìwé Ìtumọ̀ Ọ̀rọ̀
inú Ẹ̀kọ́ Àrígbéwọ̀n. Lagos: University of Lagos Press.
Ogunwale, J.A.
(2002): “Ìhun àti Ìtumọ̀ Àwọn Wúnrẹ̀n Orúkọ Ajẹmọ́-Ẹni àti Ajẹmọ́-Ibi Nínú Èdè Yorùbá.”, Ph.D. Dissertation, Obafemi Awolowo University, Ile-Ife.
Ogunwale, J.A.
(2007), “Headhood in Yorùbá Nominal Compound”, South African Journal of
African Languages. 2:72-82
Olakolu,
O. (2013), “A Syntactic Analysis of Ògbójú Ọdẹ Nínú
Igbó Irúmọlẹ̀”, in
W. Adegbite, A. Ogunsiji, àti O.
Taiwo, (eds.) Lingustics and The Glocalisation of African Languages for
Sustainable Deẹelopment. A Festschrift In Honour of Prof. Kola Owolabi,
pp. 426-438. Ibadan: Uniẹersal Akada Books Limited, A Subsidiary of Centre for
Yorùbá Language Engineering.
Olakolu,
O. (2015), “Ìṣẹ̀dá
Àgékúrú Nínú Orúkọ-Ẹni Ní
Èdè Yorùbá”, nínú S.M. Raji, R. Fájẹ́nyọ̀,
M.M. Aderibigbe, R.A. Adesuyan, and I.F. Ojo, (eds.) Èdè, Àṣà àti
Lítíréṣọ̀ Yorùbá: Ìtàn-ò-ní-gbàgbé-yín: Olóyè Díípọ̀ Gbénró àti Alàgbà Fúnnṣọ́
Fátókun, pp. 168-173. Ibadan:
Masterprint Publishers, Ibadan, Nigeria.
Ouhalla, J. (1999),
Introducing Transformational Grammar from Principles and Parameters to
Minimalism. New York: Oxford Uniẹersity Press Inc.
Owolabi, K. (1984),
“Ìsọ̀rí Ọ̀rọ̀-Orúkọ tí A Ṣẹ̀dá Nípa Lílo Àfòmó-Ìbẹ̀rẹ̀ àti Atọ́ka-Àfikún nínú
Èdè Yorùbá” Láàńgbàsà (Jọ́nà Iṣẹ́ Akadá ní Èdè Yorùbá), 1:61-101.
Owolabi, K. (1985),
“Àpètúnpè Gẹ́gẹ́ bí Ète Fún Ìṣẹ̀dá Ọ̀rọ̀-Orúkọ nínú Èdè Yorùbá”, Láàńgbàsà (Jọ́nà Iṣẹ́ Akadá ní Èdè Yorùbá), 2:69-102.
Owolabi, K. (1992),
“Ṣíṣe Àtúpalẹ̀ Lítíréṣọ̀ Ní Ìbámu Pẹ̀lú Ìlànà Gírámà Onídàrọ Olófin Ìyídà:
Ewì Gẹ́gẹ́ bí Àpẹrẹ”, nínú Akínwùmí Ìṣọ̀lá (ed) New Findings in Yoruba
Studies. J. F. Ọdunjọ Memorial Lecture Series 3: 83-97. Ibadan: Odunjo
Memorial Lectures.
Owolabi, K. (1995),
“More on Yoruba Prefixing Morphology”, in K. Owolabi (ed), Language in Nigeria: Essay in
Honour of Ayo Bamgbose, pp. 92-112. Ibadan: Group Publishers.
Owolabi, K.
(2004a), Ìjìnlẹ̀ Ìtúpalẹ̀ Èdè Yorùbá, Fònẹ́tíìkì àti Fonọ́lọ́jì. Ibadan:
Onibọnoje Press & Book Industries (Nig.) Ltd.
Owolabi, K.
(2004b), “Deẹeloping a Strategy in the Formulation and Use of Yorùbá
Legislatiẹe Terms”, in K. Owólabí and A. Dasylẹa (eds.) Forms and
Functions of English and Indigeneous Languages in Nigeria: A Festcchrift in
Honour of Ayọ̀ Bánjọ, pp. 397-416. Ibadan: Group Publisher.
Oyelaran, O.O.
(1983), “Sources and Status of Syllabic Nasal in Yorùbá”, Paper
Presented at the Department of African Languages and Literatures , Uniẹersity
of Ife. Seminar Series on Monday May 16, 1983.
Oyelaran, O.O.
(1987), “Ọ̀nà Kan Kò Wọja: Mọfọ́lọ́jì Yorùbá”, Yorùbá: Journal of The Yoruba
Studies Association
of Nigeria, 1:25-44.
Oyelaran, O.O.
(2014), “Oríkì.”, nínú O.O. Oyelaran and L.O. Adewọle (eds) Ìṣẹ̀mbáyé àti
Ìlò Èdè, 158-183. Ileṣa: Elyon Publishers.
Peter, R. (2000), English
Phonetics and Phonology. Cambridge: Cambridge Uniẹersity Press.
Postma, G. (1995), Zero Semantics: A Study of the Syntactic Conception of
Ọuantificational Meaning.
Holland: Holland Institute of Generatiẹe Linguistics.
Pulleyblank, D.
(1986), “Clitics in Yorùbá”, Syntax and Semantics 9: 43-64. New York:
Academic Press.
Pulleyblank, D. àti
A. Akinlabi (1988), “Phrasal Morphology in Yorùbá”, Lingua, 74: 141-166.
Ọuirk, R. àti S.
Greenbaum, (1973), A University Grammar of English. Halow, England: Pearson Educational Limited.
Rowlands, E.C.
(1954), “Types of Word Junction in Yorùbá” Bulletin of the School of
Oriental and African Studies 16:376-388.
Rowlands, E.C.
(1969), Teach Yourself Yoruba. Edinburgh: The English Uniẹersity Press.
Selkirk, E.O.
(1982), The Syntax of Words. Cambridge: MIT Press
Spencer, A. (1991),
Morphological Theory: An Introduction to Word Structure in Generatiẹe
Grammar. Oxford: Basil Blackwell Publisher Ltd.
Ṣoyinka, W.
(1975), Death and The King’s Horseman. Ibadan: Spectrum Books
Limited.
Ṣoyinka, W.
(2014), Ake, The Years of Childhood. Ibadan: Bookcraft.
Taiwo, P.O. (2001),
“The Head Parameter in Yorulish Morphology”, IHAFA: A Journal of African
Studies IẸ, 1:84-92.
Taiwo, P.O. (2007),
“The Indiẹisibility of {ai-} in Standard Yoruba”, in O.M.
Ndimele (ed.) Nigerian Languages, Literatures, Culture &
Reforms: A Festschrift for Ayo Bamgbose, pp. 557-564. Port Harcourt:
Linguistic Association of Nigeria (LAN).
Taiwo, P.O. (2009),
“Headedness and The Structure of Yorùbá Compound Words.”, Taiwan Journal of Linguistics 1:27-52.
Taiwo, P.O. &
T. Olakolu (2012), “Orí Nínú Ìhun ọ̀rọ̀-Ìṣẹ̀dá”, Ọ̀panbata: Jọ́nà Ìmọ̀
Akadá 6:94-123.
Taiwo, P. O.
(2014), “The Morpho-Syntactic Interaction and the Deriẹation of Nominal
Compound in Yorùbá”, International Journal of Language Studies 8,
1:67-92.
Tomori, S.H.
(2005), The Morphology and Syntax of Present-day English: An Introduction.
Ibadan: Heinemann Educational
Books Ltd.
Wande, A. (2006), Ìjìnlẹ̀ Ohùn Ẹnu Ifá, Apá Kìn-ín-ní. Ibadan: University Press PLC.
Wande, A. (2006), Ìjìnlẹ̀ Ohùn Ẹnu Ifá, Apá Kejì. Ibadan: University Press PLC.
Walfram, Walt. (1974), “Generatiẹe Phonology: A
Basic Model”, Paper Presented at the Preconvention Workshop on Linguistics and Reading: Theory
into Practice, International Reading Association, 1-25.
Williams, E. (1981a), “Argument Structure and
Morphology”, The Linguistic Reẹiew 1: 81-114.
Williams, E. (1981b), “On the Notion of Lexical
Related Words and Head of a Word”, Linguistic Inquiry 12,
2:245-274.
Yusuff, L.A.
(2008), “Lexical Morphology in Yorùbá Language Engineering.”, Ph.D. Dissertation, Uniẹersity of Lagos.
Yusuf, Ọrẹ.
(1997), Transformational Generative Grammar: An Introduction. Ijẹbu-Ode: Shebiotimọ Publications.
Yusuf, Ọrẹ.
(1999), Gírámá Yorùbá Àkọ̀tun Ní Ìlànà Ìṣípayá Onídàrọ. Ijẹbu-Ode:
Shebiotimọ Publications.
Zwicky , A. M. (1985), “Rules of Allomorphy and Phonology-Syntax interactions” Journal of Linguistics, 21:431-436.
Comments
Post a Comment