Àgbéyẹ̀wò Iṣẹ́ Awóbùlúyì (1978, 2004, 2005, 2008, 2015) lórí Mofọ́lọ́jì
Àgbéyẹ̀wò Iṣẹ́ Awóbùlúyì (1978, 2004, 2005, 2008, 2015) lórí Mofọ́lọ́jì
Awóbùlúyì (1978) ṣàlàyé lórí àwọn
ọ̀rọ̀-aṣẹ̀dá lábẹ́ orí tó pè ní atọ́nà (introducers)[1].
Èyí jẹ mọ́ ìyípadà tó máa ń bá ìsọ̀rí wúnrẹ̀n kan láti ìsọ̀rí rẹ̀ ìpìlẹ̀ sí
ìsọ̀rí mìíràn. Ó ní a lè lo àmì láti ṣe èyí, a sì lè má lo àmì. Àwọn àmì tí a
máa ń lò ló pè ní atọ́nà (introducers). Apá òsì wúnrẹ̀n tí wọn ń yí ìsọ̀rí
rẹ̀ padà ni wọ́n máa ń wà. Nínú àwọn atọ́nà tó mẹ́nu bà ni àwọn wúnrẹ̀n tí a
fi ń ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀-orúkọ. Àwọn ni:
4.
i. o-, e-, ẹ-, ọ-, a-,
ii. a-, ọ̀-, ò-, ì-,
i-, àpètúnpè kíkún
iẹ. Kí-, à-,
ẹ. ì-, o-, a-, ọ-, à-, è-
ẹi. kí, pé, pẹ́kí,
bi/ti
4(i) hàn nínú olówó (o- ní- owó), eléwé,
ẹlẹ́ja, ọlọ́kọ̀, alájá, onígi. 4(ii) hàn nínú adájọ́ (a- dá-
ẹjọ́), ọ̀lẹ (ọ̀- lẹ), òjíṣẹ́ (ò- jẹ́- iṣẹ́) ìmúnà (ì-
mú- iná), ipè (i-, pè), panápaná (pa iná pa iná). Awóbùlúyì
(1978) gbà pé èyíkéyìí àfòmó inú 4(i-ẹ) tó bá jẹ yọ nínú àwọn ọ̀rọ̀-aṣẹ̀dá ni yóò jẹ́ atọ́nà
nínú àwọn ọ̀rọ̀-aṣẹ̀dá bẹ́ẹ̀. Àlàyé Awóbùlúyì (1978) fi hàn pé wúnrẹ̀n tó jẹ́
àpètúnpè (yálà ẹlẹ́bẹ tàbí kíkún) nínú àwọn ọ̀rọ̀-aṣẹ̀dá alápètúnpè ni yóò
jẹ́ atọ́nà nínú irú àwọn ọ̀rọ̀-aṣẹ̀dá bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, [lílọ,
panápaná, ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀(ọ̀sẹ̀+ọ̀sẹ̀), ọmọkọ́mọ
(ọmọ+kí+ọmọ)][3]. Awóbùlúyì (1978) ṣàlàyé síwájú pé tí a bá rí irú ìsọdorúkọ tí a falà sí nínú
Pé wọ́n lọ dára, àwọn wúnrẹ̀n tó wà ní 4(ẹi) ni yóò jẹ́ atọ́nà fún irú àwọn ìsọdorúkọ bẹ́ẹ̀. Bí a bá wo àwọn ọ̀rọ̀-aṣẹ̀dá tí Awóbùlúyì (1978) ṣàlàyé àti àwọn wúnrẹn tí ó pè ní
atọ́nà (introducer), a ó rí i pé wọ́n jọ orí nínú àwọn ọ̀rọ̀-aṣẹ̀dá
bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n Awóbùlúyì (1978) kò pè àwọn atọ́nà yìí ní orí.
Àlàyé
Awóbùlúyì (2004) dá lórí mọ́fíìmù oníbàátan (genitive morpheme), “ti” ati “o” (èyí máa ń jẹ yọ
láàárín ọ̀rọ̀-orúkọ méjì). Ní àtakò sí èrò àwọn onímọ̀[4] kan pé “o”,
Olóhùn Àárín (Mid Tone Syllable – MTS) to máa ń jẹ yọ láàárín ọ̀rọ̀-orúkọ méjì yìí jẹ́ mọ́fíìmù ìbátan,
Awóbùlúyì (2004) ni “o” yìí kìí ṣe atọ́ka ìbátan nítorí “o” yìí kan náà máa ń
jẹ yọ nínù ẹ̀hun aṣẹ̀yán (appositive construction)[5]. Èyí kò fi hàn pé atọ́ka aṣẹ̀yán ni
bákan náà nítorí pé àwọn ẹ̀hun aṣẹ̀yán kan máa ń jẹ yọ láìsí “o” yìí.
5a. Owó Báyọ̀ (Owó o Báyọ̀) – ẹ̀hun
oníbàátan
b. Àna Jímọ́ọ̀ (Àná an
Jímọ́ọ̀) – ẹ̀hun aṣẹ̀yán
Awóbùlúyì (2004) gbà pé nínú àwọn àpólà orúkọ méjì tí ẹ̀hun
oníbàátan tàbí ẹ̀hun aṣẹ̀yán ti jẹ yọ, sàkání ìlò (context) ni yóò sọ bóyá
ẹ̀hun oníbàátan ni tàbí ẹ̀hun aṣẹ̀yán, nítorí pé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n lè jẹ yọ
láìsí “o” yìí. Awóbùlúyì (2004) gbà pé a ò lè fi ìpele ìtumọ̀ (semantics), síńtáàsì ati ìṣẹ̀dá-ọ̀rọ̀ (morphology) ṣàlàyé “o” yìí. Ìpele ìmọ̀ ẹ̀dá-èdè tí a lè fi ṣàlàyé rẹ̀ ni
ìpele fonọ́lọ́jì. Àlàyé rẹ̀ ni pé fáwẹ̀lì kan /i/[6] máa ń jẹ yọ ní
ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀[7] Yorùbá tí a rò pé
kọ́ńsónáàtì ló bẹ̀rẹ̀ wọn[8] (i-gómìnà
→ gómìnà; i-Délé → Délé; i-tẹ́lọ̀→ tẹ́lọ̀, abbl). Fáwẹ̀lì
/i/ yìí ni ó máa ń hàn tí ó sì lè yíra padà sí èyíkéyìí fáwẹ̀lì gẹ́gẹ́ bí ó ti
hàn ní (6). Ọ̀rọ̀-orúkọ nìkan ni fáwẹ̀lì yìí máa ń bá rìn.
6. owó i-Báyọ̀ → owó o-Báyọ̀
àná i-Jímọ́ọ̀ → àná an-Jímọ́ọ̀
èní i-sátidé → èní in-sátidé
òjó i-lọ́yà → ojo o-lọ́yà
ọjọ́ i-Jímọ̀ọ́ → ọjọ́
ọ-Jímọ́ọ̀
bùrọ̀dá i-Báyọ̀ → bùrọ̀dá
a-Báyọ̀
Bákan náà, iṣẹ́ Awóbùlúyì (2004) yìí ṣàlàyé lórí “ti” tó máa ń jẹ yọ
láàárín àpólà orúkọ méjì. Ó ní kìí ṣe
ọ̀rọ̀ atọ́kùn ló ń jẹ yọ láàárín ẹ̀hun oníbàátan fún ìtẹnumọ́ gẹ́gẹ́ bíi
àlàyé Ajíbóyè (2004) ṣe fi hàn. Ìṣesí “ti” yìí
jọ ti àwọn ọ̀rọ̀-orúkọ tó wà ní (6) nítorí pé òun náà lè ní irú fáwẹ̀lì tí
àwọn ọ̀rọ̀-orúkọ yìí ni (wo àpẹẹrẹ 7a), èyí sì jẹ́ kó ní àbùdá
ọ̀rọ̀-orúkọ (+OR). “Ti” yìí lè gba arọ́pò-orúkọ rẹ̀[9] ní ẹ̀yán nípò
olùwà tàbí àbọ̀ (àpẹẹrẹ 7b(i) àti 7b(ii) ló fi èyí hàn). “Ti” yìí kan náà
lè jẹ́ wúnrẹ̀n awẹ̀yìn – anaphor (àpẹẹrẹ 7d ló ń ṣàlàyé èyí).
7a. ajá ti Kúnlé (ajá a-ti Kúnlé)
bi. Ti
rẹ̀ wù mí (nípò olùwà)
ii. Mo
kọ ti rẹ̀ (nípò àbọ̀)
d. Mo
mú ìwé Ayọ̀, mo sì fi ti Tọ́pẹ́
sílẹ̀
Àbùdá ìwẹ̀yìn yìí ló yan àbùdá Ìtọ́ka Àṣọ̀-ṣaájú
(definiteness) (IA) fún un [+IA], f.a. “ti” nínú (7d) ń tọ́ka sí “ìwé” tí a ti
mọ̀ tí ó sì jẹ yọ ṣaájú “ti”. Awóbùlúyì (2004) gbà pé ọ̀rọ̀-orúkọ ló máa ń
ní irú àwọn àbùdá yìí, nítorí náà ọ̀rọ̀-orúkọ ni “ti”.
Awóbùlúyì
(2005) ṣàlàyé bí “àì”, “àti”, “oní” àti “oni” ṣe jẹ́ mọ́fíìmù méjì. Ó ní nínú àwọn
ọ̀rọ̀-aṣẹ̀dá bíi “ajẹẹ̀jẹtán”[10], “àgéègétán”,
“àbùùbùtán”, “àkúkúùbí”, “ì” ni wúnrẹ̀n kejì tó ṣaájú àwọn ọ̀rọ̀-ìṣe inú
ọ̀rọ̀-aṣẹ̀dá yìí kìí ṣe “àì”. Ó gbà pé kaní “àì” ni, tí ó sì jẹ́ àfòmọ́
onísílébù méjì, òun ni yóò yan ìsọ̀rí ọ̀rọ̀-orúkọ fún ọ̀rọ̀ tí a fi ṣẹ̀dá.
Àbùdá ara rẹ̀ tó jẹ́ ti ọ̀rọ̀-orúkọ ni yóò ṣàn sí ara ọ̀rọ̀ tí a fi ṣẹ̀dá bákan náà. Ó ní “kúkú” nínú “àkúkúùbí” jẹ́
aṣaájú ìṣe, kò sì ní ṣaájú ọ̀rọ̀ kan àyàfi kí ọ̀rọ̀ náà jẹ́ ọ̀rọ̀-ìṣe tàbí
aṣaájú-ìṣe. Ó fi bí (IṢ) wé àìbí (OR) láti fi hàn pé {àì-} tó
ní àbùdá ọ̀rọ̀-orúkọ kọ́ ni “kúkú” ṣaájú nínú “àkúkúùbí”, {ì} tó ní àbùdá ọ̀rọ̀-ìṣe ni. Awóbùlúyì (2005) lo àpẹẹrẹ
10(a) àti (b) láti tún fi hàn pé “àì” kìí ṣe mọ́fíìmù kan ṣoṣo. Nínú àlàyé
rẹ̀ lórí ìlànà-ìṣẹ̀dá[11] (10) yìí, ó ní
àpóla àtọ́kùn kò lè jẹ yọ lẹ́yìn ọ̀rọ̀ bí kúkú nínú èdè Yorùbá.
10a. a + gé + ní +
àì + gé + tán + ? àgéàìgétán → àgéìgétán +
àgéègétán
b. * a + kuku + ní + àìbí
Àwọn ẹ̀rí mìíràn tí àlàyé Awóbùlúyì
(2005) fi hàn pé “àì” kìí ṣe mọ́fíìmù kan ṣoṣo ni pé:
i.
oríṣìí mọ́fíìmù mìíràn lè jẹ yọ
ṣaájú “ì” tí Àwóbùlúyì (2005) gbà pé òhun ló ṣiṣẹ́ ìyísódì [Ó jìyà ní àìṣẹ̀ ({à-} ni ìtumọ̀ ohun): Má fìyà jẹ orí àìṣẹ̀ ({à-} ni ìtumọ̀ ẹni)]
ii. “rì” nínú
àwọn ọ̀rọ̀-aṣẹ̀dá bíi “àrìsùn” (àìsùn) àbírìkọ́ (àbíìkọ́) nínú àwọn ẹ̀ka-èdè
kan ń ṣiṣẹ́ ìyísódì ni gẹ́gẹ́ bíi “ì” ṣe n ṣe é nínú olórí ẹ̀ka-èdè [Ayọ́ rì á (Ayọ̀
kò wá) – Ọyẹ́: Ká ṣe é kò Olú rì gbe? (kí ló dé tí Olú kò fi gbé e?) –
Ìkọ̀lé].
Àlàyé rẹ̀ lórí “àti” ni pé oríṣìí “ti”[12] méjì ni a so {à-}
mọ́ láti fún wa ní “àti”. Ọ̀kọ̀ọ̀kan (“ti”, tí ó jẹ́ atọ́kùn: “ti”, tí ó jẹ́ àpọ́nlé aṣáájú-ìṣe) wọn ń ṣe pàṣípàrọ̀ ara wọn lẹ́yìn {à-} ni.
11.
i. àtòkè (à- ti òkè) – atọ́kùn
ii. àtilọ (à- ti lọ) - àpọ́nlé aṣáájú-ìṣe
Àwóbùlúyì (2005) ṣe àlàyé pé mọ́fíìmù méjì ni “oní”. Ìdí
ni pé:
ii.
àwọn àfòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ lè ṣe pàṣípàrọ̀
ara wọn ní iwájú rẹ̀, èyí fi hàn pé ó ṣeé tú palẹ̀
12a. aníkúlápó = a + ní + ikú + ní + apó
b. oníkúlápó = o
+ ní + ikú + ní + apó
d. òníkulápó = ò
+ ní + ikú + ní + apó
Bí a bá wo àwọn
àpẹẹrẹ tó wà ní 12, èyí ń gbé àwọn ẹ̀rí mèjì òkè yìí lẹ́sẹ̀ ni.
pé ìtumọ̀[14] kan náà ni {a-},
{o-}, {ò-} ni, wọ́n sì lè ṣe pàṣípàrọ̀ ara wọn níwájú “ní” tó jẹ́ ọ̀rọ̀-ìṣe.
Awóbùlúyì (2005) tẹ̀ síwájú lórí àlàyé rẹ̀ pé mọ́fíìmù méjì ni “oni” nípa pé:
i.
“ni” àti “ní” lè ṣe pàṣípàrọ̀ ara wọn níwájú {o-}, la óò fi rí ẹlẹ́yẹ → o + ní + ẹyẹ : ẹlẹyẹ → o + ni + ẹyẹ
ii.
{ò-} àti {o-} lè ṣe pàṣípàrọ̀ ara
ṣaájú “ni” ni a fi rí : onilẹ̀ → o + ní + ilẹ̀: ònilẹ̀ → ò + ni + ilẹ̀.
Ẹ̀rí kìn-ín-ní àti èkejì fi hàn pé
“oni” ṣeé tú palẹ̀ bíi “oní”. Iṣẹ́ rẹ̀ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé àfòmọ́-ìbẹ̀rẹ̀ nínú
èdè Yorùbá kìí gùn ju ẹyọ ìró kan lọ.
Odidi ìwé lórí mọfọ́lọ́jì Yorùbá ni
iṣẹ́ Awóbùlúyì (2008). Orí kìn-ín-ní ṣàlàyé lórí mọ́fíìmù àti oríṣìí àfòmọ́
tó wà. Àwòrán[15] ìsàlẹ̀ yìí
ṣàfihàn oríṣìí mọ́fíìmù àti àfòmọ́.
Bí a bá wo àwòrán òkè yìí, Awóbùlúyì
(2008) ṣe àfihàn oríṣìí mọ́fíìmù mèjì. Àkọ́kọ́ ni mọ́fíìmù adádúró (f.a., ọ̀rọ̀-ìṣe;
rí, gbé, kí, abbl.; ọ̀rọ̀-orúkọ; ilé, epo, oko, abbl.) nígbà tí
èkejì j̣ẹ́ mọ́fíìmù àfarahẹ̀. Òríṣìí mọ́fíìmù àfarahẹ̀ méjì ni Awóbùlúyì (2008) ṣàlàyé. Àwọn ni òpó àfarahẹ – {-ji}, {-je}, {-ta}, {-jẹ}, abbl., àti àfòmọ́. Méjì ni oríṣìí àfòmọ́ tí Awóbùlúyì (2008) ṣàlàyé. Àwọn ni àfòmọ́wájú (èyí lè jẹ́ àfòmọ́wájú aṣe-fáwẹ̀lì tàbí àfòmọ́wájú aṣe-kọ́nsónàntì) àti àfòmọ́-àsopọ̀. Oríṣìí àfòmọ́wájú mẹ́sàn-án ni Awóbùlúyì ni ó wà (aṣe-fáwẹ̀lì jẹ́ mẹ́jọ
nígbà tí aṣe-kọ́ńsónáǹ̀tì jẹ ẹyọ kan). Ó gbà pé èyíkéyìí fáwẹ̀lì
àìránmúpè yàtọ̀ sí /u/ ni àfòmọ́wájú aṣe-fáwẹ̀lì lè jẹ́, wọ́n sì lè gba
àmì ohùn ìsàlẹ̀ tàbí tàárín. Bákan náà, ó ṣàlàyé pé àwọn àfòmọ́wájú aṣe-fáwẹ̀lì yìí máa ń ní ẹ̀yà àti ẹ̀dà. Èyíkéyìí
kọ́ńsónáǹ̀tì {K-} èdè Yorùbá ni àfòmọ́wájú aṣe-kọ́ńsónáǹ̀tì lè jẹ. Àwọn
ni wọ́n máa ń jẹ yọ nínú ọ̀rọ̀ bí (jíjẹ ¬ j-í-jẹ, sísùn ¬ s-í-sùn, abbl.). Fáwẹ̀lì àfibọ̀
ni ó pe /i/ tó máa ń jẹ yọ nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi àfòmọ́wájú
aṣe-kọ́ńsónáǹ̀tì ṣẹ̀dá. Awóbùlúyì (2008) ṣàlàyé[16] lórí àwọn
wúnrẹ̀n bíi “àì”, “àti”, “oní” àti “oni”.
Ní orí kejì
sí orí kẹta ìwé yìí ni Awóbùlúyì (2008) ti ṣàlàyé àwọn ète mìíràn tó jẹ mọ́
ìṣẹ̀dá-ọ̀rọ̀. Ó ní a lè lo àfòmọ́wájú méjì (àfòmọ́wájú aṣe-fáwẹ̀lì àti
aṣe-kọ́ńsónáǹ̀tì) pọ̀ fún ìṣẹ̀dá-ọ̀rọ̀ (aaka ¬ a-ki-ka)[17]. Àwọn
àfòmọ́-àsopọ̀ tí Awóbùlúyì (2008) tọ́ka sí fún ìṣẹ̀dá-ọ̀rọ̀ ni: {-bá-} nínú ayébáyé;
{-bí-} nínú iyebíye; {-dé-} nínú ìgbàdégbà, {-mọ́-} nínú ọdúnmọ́dún;
{-rè-} nínú ayérayé, {-jọ-} nínú irọ̀jirọ̀, {-ní-} nínú àgbàlagbà,
{-ni-} ọpẹ́lọpẹ́, {-kí-}[18] nínú iṣẹ́kíṣẹ́.
Awóbùlúyì (2008) ṣàlàyé lórí àpètúnpè, ìkànpọ̀, títa atọ́kùn/amúpé mọ́
gbólóhùn fún ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀; fífi ìlò sọ ìpèdè di ọ̀rọ̀-orúkọ àti yíya ọ̀rọ̀
àjèjì lò. Awóbùlúyì (2008) ṣàfihàn àwọn oríṣìíoríṣìí àpètúnpè. Àwọn ìlànà
àpètúnpè yìí ni àwọn ọ̀rọ̀-aṣẹ̀dá wònyí jẹ mọ́: ọdọọdún (ọdún → ọdún ọdún → ọdọ-ọdún → ọdọọdún; ọ̀tun-ọ̀tun (ọ̀tun → ọ̀tun-ọ̀tun); lọ́balọ́ba (ní ọ-ba, ní ọ-ba); ìbíîbí
(ibi-ibi → ìbíîbí); irúurú
(nínú onírúurú ¬ o-ní-irúurú)[19]; gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ;
jàù-jàù; gbẹẹrẹ-gbẹ (gbẹẹrẹ-gbẹẹrẹ); kẹ́kẹ́
(kẹ́→kẹ́kẹ́); tìfẹ́-tìfẹ́
(¬ ti ìfẹ́ ti ìfẹ́).
Awóbùlúyì (2008) ṣàfihàn oríṣìí àwọn ọ̀rọ̀-aṣẹ̀dá alákànpọ̀[20].
Àwọn ni ìkànpọ̀ pọ́ńbélé (àlàfo ¬ àlà òfo); ìkànpọ̀
alápètúnpè I (ọmọlọmọ ¬ ọmọ ọlọ́mọ); ìkànpọ̀
alápètúnpè II (kátà-kárà ¬ kí á tà, kí á rà); ìkànpọ̀
alápètúnpè (onílélọ́nà ¬ onílé ọlọ́nà); ìkànpọ̀
oníkànpọ̀ (ọ̀dọ́mọkùnrin ¬ ọkọ ọmọkùnrin[21]); ìkànpọ̀
alátọ́kùn (baálé ¬ ba ní ilé); ìkànpọ̀ aláàpólà-àṣẹ (ẹlẹ́yà-mẹ̀yà
¬ o-ní-ẹ̀yà-mọ-ẹ̀yà). Awóbùlúyì (2008)
fi kún àlàyé rẹ̀ pé a lè ta èyíkéyìí
amúpé (kí, pé, àti bí/ti… bá) mọ gbólóhùn fún ìṣẹ̀dá-ọ̀rọ̀ [irú àlàyé
báyìí ní iṣẹ́ Awóbùlúyì (2015) dá lé lórí], f.a., kí Dàdá lọ ¬ Dáda lọ, Mo lọ → pé mo lọ, abbl. Ní àfikún,
Awóbùlúyì (2008) ní a lè fi ìlò sọ àpólà ìṣe tàbí gbólóhùn di ọ̀rọ̀-orúkọ.
i.
fífi ìlò sọ àpólà ìṣe di
ọ̀rọ̀-orúkọ:
13a. Mo
roko roko; mo da bi oko
Mo yẹ̀nà yẹ̀nà; mo dà bí ọ̀nà
b. Rokoroko
ni mi,
mo sì jẹ́ yẹ̀nàyẹ̀nà
Ní 13(a), àpólà ìṣe ni àwọn wúnrẹ̀n tí a fàlà sí, nígbà
tí àwọn tó jẹ́ ọ̀rọ̀-orúkọ wà ní 13(b)
ii.
fífi ìlò sọ gbólóhùn di ọ̀rọ̀ orúkọ:
èyí lè jẹ́
a.
gbólóhùn àṣẹ; panumọ́ (¬ pa ẹnu mọ́)
b.
gbólóhùn àyísódì; kòrí-kòsùn (¬ (Bi) ko rí ọ̀rẹ́
rẹ̀ Kọ́lá kò sùn)
d.
gbólóhùn àlàyé; orísún-n-báre
(orí sún mi bá ire)
e.
gbólóhùn alátẹnumọ́; ẹni-mo-rí-mo-bá-lọ
(¬ ẹni tí mo rí ni
mo bá lọ)
Bákan náà, Awóbùlúyì (2005) ṣàlàyé ète
yíya-ọ̀rọ̀-àjèjì-lò fún ìṣẹ̀dá-ọ̀rọ̀. Ó ni a lè yá ìtumọ̀ nìkan lò (f.a. holy → mímọ), a lè yá ìrísí lò (f.a. ọuarters → pẹ̀tẹ́sì), a sì lè yá ìtumọ̀ àti ìrísí/pípé lò (f.a. bricks → bíríkì).
Àlàyé
Awóbùlúyì (2008:73-77) lórí ìsọ̀rí tó pín àwọn ọ̀rọ̀ àyálò sí kù díẹ̀ káàtó. Ó
gbà pé ìtumọ̀ lafi yá holy láti inú èdè Gẹ̀ẹ́sì tó di mímọ́ nínú
èdè Yorùbá, religion tó di ẹ̀sìn, abbl. Ewu pàtàkì kan tó rọ̀ mọ́
irú àlàyé yìí ni pé iru àlàyé yìí lè gbà pé Yorùbá kò dá ní àwọn ọ̀rọ̀ tirẹ̀
àti pé ọ̀rọ̀ àyálò ni gbogbo ọ̀rọ̀ Yorùbá nítorí àlàyé yìí lè gbà pé Yorùbá yá
ìtumọ̀ igi láti ara tree, omi láti ara water, abbl.
Èyí kò rí bẹ́ẹ̀, nítorí ṣaájú kí ìbáṣepọ̀ tóó wà láàárín èdè Yorùbá àti àwọn
èdè mìíràn (bí Gẹ̀ẹ́sì) ni Yorùba ti ni àwọn ọ̀rọ̀ (mímọ́, ẹ̀sìn, igi, omi,
abbl.) wọ̀nyí. Àfijọ ni Yorùbá ń ṣe nígbà tí ìbáṣepọ̀ wáyé láàárín èdè Yorùbá àti àwọn èdè mìíràn (bí
Gẹ̀ẹ́sì). Bákan náà, àlàyé Awóbùlúyì
(2008) kùnà lórí yíyá ọ̀rọ̀ lo láti ara ìrísí nítorí pé ìlànà yìí kò ṣàlàyé
ọ̀nà tí ọuarters gbà di pẹ̀tẹ́ẹ́sì lábẹ́ ìsọ̀rí
(ìtumọ̀). Irú àlàyé tó ṣe lórí bí brake[22] ṣe di búréèkì kò
ṣe é fún ọ̀rọ̀ bíi pẹ̀tẹ́ẹ́sì.
Irú àtúpalẹ́
tí Awóbùlúyì (2008:56-57 àti 65) ṣe lórí pé ọ̀rọ̀-aṣẹ̀dá ni ọ̀rọ̀ bíi baba,
ọba, abbl. lè fẹ́ẹ́ mú ká gbà pé àwọn ọ̀rọ̀ bíi iṣu, ẹja, ilé,
abbl ṣeé tú palẹ̀ ní ọ́jọ́
iwájú.
Ní orí kẹrin ni Awóbùlúyì (2008) ti
ṣàlàyé lórí àtúpalẹ̀ arọ́pò-orúkọ (atọ́ka sẹ́ni, atọ́ka-sóhun àti
atọ́ka-si-ìní). Àtúpalẹ̀ òǹ̀kà ni orí karùn-ún jẹ mọ́ nígbà tí o fi orí kẹfà
ṣàlàyé àpọ́nlé aṣaájú-ìṣe àti ọ̀rọ̀-ìṣe[23] àti àpólà ìṣe.
Orí tó gbẹ̀yìn nínú iṣẹ́ yìí ló fi ṣàlàyé ìlànà àmúlò fún ìṣẹ̀dá àwọn èdè
ìperí nínú èdè Yorùbá.
Awóbùlúyì
(2015) ṣàlàyé lórí àwọn atọ́ka àmúpé (irú àlàyé bẹ́ẹ̀ hàn nínú Awóbùlúyì
(2005). Àwọn atọ́ka amúpé márùn-ún (ní, tí, bi, pé àti kí) hàn fún
ìṣẹ̀dá-ọ̀rọ̀ nínú iṣẹ́ yìí.
Iṣẹ́ wa jẹ
mọ́ àwọn ìlànà ìṣẹ̀dá-ọ̀rọ̀ (lílo àfòmọ́, ṣíṣe àpètúnpè àti kíkan ọ̀rọ̀ pọ̀
fún ìṣẹ́dá-ọ̀rọ̀) tí Awóbùlúyì (1978,
2004, 2005, 2008, 2015) gbé yẹ̀ wò ṣùgbọ́n àwa a tún ṣàlàyé orí nínú
àwọn ọ̀rọ̀-aṣẹ̀dá bẹ́ẹ̀.
ÀKÓJỌPỌ̀ ORÚKỌ ÌWÉ
Adeṣọla,
O. (2008), “The Linguistic Forms of Olú Ọmọ”, in
A. Akinyemi àti T. Falọla (eds.) Emerging
Perspeciẹes on Akinwumi Iṣọla, pp. 189-204. Trenton: Africa
World Press Inc.
Adewọle,
L.O. (1986), “The Yorùbá High Tone Syllable Reẹisited”, Work in Progress 19:
81-94, Edinburgh: Department of Linguistics,
Uniẹersity of Edinburgh.
Adewọle,
L.O. (1987), The Yoruba Language: Published Works and Doctoral
Dissertations: 1843-1986. Hamburg: Helmut Buske Verlag.
Adewọle,
L.O. (1988), “The Categorial Status and the Functions of the Yoruba Auxiliary
Ẹerbs with Some Structural Analyses in GPSG.”, Ph.D. Dissertation, Unieversity of Edinburgh.
Adewọle,
L.O. (1991), “Heads Without Bars: A Solution to the Sentential Status of the
Yorùbá Focus and Relatiẹe Constructions”, Odu: A Journal of West African
Studies, 38:19-43.
Adewọle,
L.O. (2000a), “Negation in Ifẹ: A Yorùbá Dialect”, Journal
of Asian and African Studies (Tokyo, Japan).
Adewọle,
L.O. (2000b), “Heads in Yorùbá Derieved Words”, Calgary Working
Papers in Linguistics (Canada) 22:147-156.
Adewọle,
L.O. (2008), “Iṣọla on
Issues in Yorùbá Language”, in A. Akinyemi àti T. Falọla
(eds.) Emerging Perspecieves on Akinwumi Iṣọla, pp. 177-188. Trenton: African
World Press, Inc.
Adewọle,
L.O. (2015), “Àtamọ́”, yorubafracademicpurposeblogspot.com
(accessed on 26/08/2016).
Adewọle, L.O. (2015), “Dahl
(1985) and The Yorùbá Perfectieve”, yorubaforacademicpurposeblogspot.com
(accessed on 27/5/2017).
Adewọle, L.O. (2016), “Ìfi
àfòmọ́wájú Ṣẹ̀dá Ọ̀rọ̀-Orúkọ nínú Èdè Yorùbá (Derieving Nouns in Yorùbá with the Use of Prefix)”, yorubaforacademicpurposeblogspot.com
(accessed on 09/11/2016).
Adewọle, L.O. (2016),
“Ìṣẹ̀dá-ọ̀rọ̀ nínú Orin Ewúro (Ìpàjùbà)”, yorubaforacademicpurposeblogspot.com
(accessed on 09/11/2016).
Adewọle, L.O. (2016), “Sources
and Status of the Syllabic Nasal in Yorùbá”, yorubaforacademicpurposeblogspot.com
(accessed on 27/5/2017).
Adìgbòlùjà,
C.A. (1946), African Family Physicians. Lagos: Ola-Oluwa Press.
Aina,
F. B. (2003), “Fonọ́lọ́jì
Àti Mọfọ́lọ́jì Ẹ̀ka-Èdè
Òrò Ní Ilẹ̀ Ìgbómìnà.”, M.A. Dissertation, Yunifásítì Adó-Èkìtì.
Ajiboye,
O. (2004), “Genitieve Construction in Yoruba.”,
Conference Paper Presented at the 35th Annual Conference on African
Linguistics, Haẹard Uniẹersity, Cambridge, April 2-4.
Ajiboye, O. àti R.
Dechaine (2004), “The Syntax and Semantics of Yoruba Duplicatieve Constructions.”, Conference Paper
Presented at the 35th
Annual Conference on African Linguistics, Haẹard Uniẹersity, Cambridge, April
2-4.
Akiyẹmi, A. and T.
Falọla (eds.) (2008), Emerging Perspectiẹe on Akínwùmí Ìṣọ̀lá.
Trenton: World Press Inc.
Anderson,
S.R. (2000), A-morphous Morphology.
Cambridge: Cambridge Unieversity Press.
Anderson,
S.R. (2002), “Where’s Morphology?”, Linguistic Inọuiry
13:571-612.
Andrew,
C. (2001), Syntax. Uniẹersity of Ariṣona. Oxford: Blackwell Publishers Inc.
U.S.A.
Andrew,
M. (2002), An Introduction to English
Morphology: Words and Their Structure. Edinburgh: Edinburgh Unieversity Press Ltd.
Asiyanbola,
A.A. (2003), “Word Formation and Inflections in English”, in L. Oyeleye and M. Olateju (eds.) Reading in Language and Literature. Ife: Obafemi Awolowo Unieversity Press Limited, Nigeria, pp. 47-66.
Awobuluyi,
O. (1978), Essentials of Yoruba Grammar. Ibadan: Unieversity Press Limited, Nigeria.
Awobuluyi,
O. (1990), (ed) Yorùbá Metalanguage (Èdè-Ìperí Yorùbá), Volume II.
Ibadan: Uniẹersity Press Plc.
Awobuluyi,
O. (1992), “Aspect of Contemporary Yorùbá in Dialectology Perspectiẹe” in Ìṣọ̀lá,
A. (ed) J. F. Ọdunjọ Memorial Lecture, 3:1-82. Ibadan: Johnmof Printer.
Awobuluyi,
O. (2008a), “On the So-Called Genitieve Morpheme in Standard Yoruba”,
nínú Ẹ̀kọ́ Ìṣẹ̀dá-Ọ̀rọ̀
Yorùbá, pp.
241-260. Àkúrẹ́: Montem Paperbacks.
Awobuluyi,
O. (2008b), “Mọ́fíìmù Kan Ṣoṣo ni
“àì” àbí Méjì”, nínú Ẹ̀kọ́ Ìṣẹ̀dá-Ọ̀rọ̀
Yorùbá, pp.
213-222. Àkúrẹ́: Montem Paperbacks.
Awobuluyi,
O. (2008c), Ẹ̀kọ́ Ìṣẹ̀dá-Ọ̀rọ̀
Yorùbá.
Àkúrẹ́: Montem Paperbacks.
Awobuluyi,
O. (2013), Ẹ̀kọ́
Gírámà Èdè Yorùbá. Òṣogbo: Atman
Limited.
Awobuluyi,
O. (2015). “Àwọn Atọ́ka
Amúpé Inú Èdè Yorùbá”, Yorùbá: Journal of Yoruba Studies Association of
Nigeria 8,
1: 18-30.
Awoyale, Y. (1974),
“Studies in the Syntax and Semantics of Yoruba Nominaliṣations.”, Ph.D. Dissertation,
Unieversity of Illinois, Urbana-Champaign.
Awoyale,
Y. (1981), “Nominal Compound Formation in Yoruba Ideophones”, Journal of
African Languages and Linguistics 3: 139-157.
Awoyale,
Y. (1995), “The Role of Functional Categories in Syntax: The Yoruba Case”, in K. Owolabi (ed.), Language in Nigeria. Essays in Honour of Ayo Bamgbose, pp. 113-127. Ibadan: Group
Publishers.
Bamgboṣe, A.
(1967), A Short Grammar. Ibadan:
Heineman Educational Books Ltd.
Bamgboṣe, A.
(1971), “The Verb-Infinitieve Phrase in Yoruba”, Journal of West African Languages.
ẸIII, 1:37-52.
Bamgboṣe, A.
(1980), “Pronoun, Concord and Pronominaliṣation”, Afrika und Ubersee LXIII:37-52.
Bamgboṣe, A. (1986), Yoruba: A Language in Transition. Ibadan: Odunjo Memorial
Lectures.
Bamgbose,
A. (1990), Fonoloji ati Girama Yoruba. Ibadan: Uniẹersity Press Plc.
Bamgbose,
A. (1992), (ed.), Yorùbá Metalanguage (Èdè-Ìperí Yorùbá), Volume I. Ibadan: University Press Plc.
Bolaji,
A. (2010), An Introduction to English Sentences. Ibadan: Scribo
Publications Limited.
Cann,
R. (1984), “Heads without Bars: A Theory of Phrase Structure”, An Unpublished
Paper.
Cann,
R. (1986), “The Structure of Words”, Work in Progress 19: 107-121,
Edinburgh: Department of
Linguistics, Uniẹersity of Edinburgh.
Chomsky, N. (1957),
Syntactic Structures. The Hague: Janua Linguam
Chomsky, N.
(1965), Aspects of Theory of Syntax.
Cambridge: MIT Press.
Chomsky, N. (1995),
The Minimalist Program. Cambridge: MIT Press.
Chomsky, N. (1981),
“Lecture on Goẹernment and Binding”, The Pisa Lecture, Foris:
Dordrecht.
Chomsky, N. (2006),
Language and Mind. Cambridge: Cambridge University Press.
Citation of
Professor Akinwumi Iṣọla, Nigerian National Order of Merit, Year 2000.
www.nnma.goẹ.ng
(accessed on 17/12/2016).
Cippolone, N., S.H. Keiser and S. Vasishth (1994), Language Files, Material for an Introduction to Language
and Linguistics. Columbus: Ohio State University Press.
Crystal, D. (2001), A Dictionary of Language. Chicago: University of Chicago Press.
Crowther, S.
(1852), Grammar of The Yoruba Language. London: Seeleys.
Cruttenden, A.
(2008), Gimson’s Pronunciation of English. UK: Hodder Education, Part of
Hachette Liẹre.
Ẹkundayọ, A.S.
(1975), “An Alternatiẹe to Lexical Insertion for Yorùbá Complex Noun”, Studies
in African Linguistics Supplement 1, 3:233-260.
Fabunmi, F.A.
(2006), “Àsìkò Àti Iba-Ìṣẹlẹ Nínú Èka-Èdè Yorùbá Mọfọlí.”, Ph.D.
Dissertation, Ọbafẹmi Awolọwọ University, Ile-Ifẹ.
Fágúnwà, D.O.
(1950), Ògbójú Ọdẹ Nínú Igbó Irúnmọlẹ̀. Ibadan: Nelson Publishers
Limited.
Federal Goẹernment
of Nigeria (FGN) (1990), Ọuadrilingua Dictionary of Legislatiẹe Terms.
Lagos: Nigeria
Gazdar, G., E. Klein, G. Pullum and I. Sag (1985), Generaliṣed Phrase Structure Grammar. Oxford: Basil
Blackwell Publisher Ltd.
Halliday, M.A.K. (1985a), Spoken and Written Language. Geelong, Ẹic.: Deakin University Press.
Halliday,
M.A.K. (1985b), “Systemic Background”, in J.D. Benson and W.S. Greaẹes (eds) Systemic Perspectives on Discourse, pp. 1–15. Reprinted in Halliday, M.A.K. (2003) On
Language and Linguistics, Ẹolume 3. New York: Continuum Press.
Halliday, M.A.K.
(2014), Halliday’s Introduction to Functional Grammar. Oxon: Routledge Milton Park Publication.
Horrocks, G.
(1987), Generatiẹe Grammar. London: Longman Publisher.
Ìṣọ̀lá,
A. (1983), Olú Ọmọ.
Ibadan: Onibọnoje Press and Books Industries.
Ìṣọ̀lá,
A. (1990), Ogún Ọmọdé.
Ibadan: University Press Plc.
Ìṣọ̀lá,
A. (1992), Ó Le
Kú. Ibadan: University Press Plc.
Ìṣọ̀lá,
A. (1994), Ikú
Olókùn Ẹṣin. Ibadan: Fountain Publications.
Ìṣọ̀lá,
A. (2001), Aké,
Ní Ìgbà Èwe. Ibadan: Bookcraft.
Ìṣọ̀lá,
A. (2008), Ṣaworoide. Ibadan: Uniẹersity Press Plc.
Katamba, F. (1993),
Morphology. New York: St Martin’s Press.
Katamba, F. àti J.
Stonham, (2006), Morphology. Hampshire: Palgrave Macmillan Publisher.
Klaẹan, J.L.
(1980), “Approaches to Uniẹersal Theory of Clitics.”, Ph.D. Dissertation, University of London.
Kyle, J. (2004), Introduction
to Transformational Grammar. Amherst: University of Massachusetts Press.
Lamidi, M.T. and
T.O. Ajongolo,
(2001), “The Head Parameter in Yorulish Morphology”, IHAFA: A Journal of African Studies IẸ, 1:84-92.
Leech, G. and M.
Short, (2007), Style in Fiction, A Linguistic
Introduction to English Fictional Prose. UK: Pearson Education Limited.
Lieber, R. (1981), On
the Organisation of Lexicon. Indiana: Indiana University Press.
Lieber, R. (1983),
“Argument Linking and Compounds in English”, Lingustics Inquiry,
14: 251-285.
Nida, A.E. (1949), Morphology,
The Descriptiẹe Anaylysis of Words. Ann Arbor: The University of Michigan Press.
Nigeria Educational
Research and Deẹelopment Council (NERDC) (1990), A Ẹocabulary of Primary
Science and Mathematics in Nine Nigerian Languages Ẹol. 1. Enugu: Fourth
Dimension Publishing Co. Ltd. for NERDC.
Ọdẹtayọ, J.A.
(1993), English-Yorùbá Dictionary of Engineering Physics, Ìwé Ìtumọ̀ Ọ̀rọ̀
inú Ẹ̀kọ́ Àrígbéwọ̀n. Lagos: University of Lagos Press.
Ogunwale, J.A.
(2002): “Ìhun àti Ìtumọ̀ Àwọn Wúnrẹ̀n Orúkọ Ajẹmọ́-Ẹni àti Ajẹmọ́-Ibi Nínú Èdè Yorùbá.”, Ph.D. Dissertation, Obafemi Awolowo University, Ile-Ife.
Ogunwale, J.A.
(2007), “Headhood in Yorùbá Nominal Compound”, South African Journal of
African Languages. 2:72-82
Olakolu,
O. (2013), “A Syntactic Analysis of Ògbójú Ọdẹ Nínú
Igbó Irúmọlẹ̀”, in
W. Adegbite, A. Ogunsiji, àti O.
Taiwo, (eds.) Lingustics and The Glocalisation of African Languages for
Sustainable Deẹelopment. A Festschrift In Honour of Prof. Kola Owolabi,
pp. 426-438. Ibadan: Uniẹersal Akada Books Limited, A Subsidiary of Centre for
Yorùbá Language Engineering.
Olakolu,
O. (2015), “Ìṣẹ̀dá
Àgékúrú Nínú Orúkọ-Ẹni Ní
Èdè Yorùbá”, nínú S.M. Raji, R. Fájẹ́nyọ̀,
M.M. Aderibigbe, R.A. Adesuyan, and I.F. Ojo, (eds.) Èdè, Àṣà àti
Lítíréṣọ̀ Yorùbá: Ìtàn-ò-ní-gbàgbé-yín: Olóyè Díípọ̀ Gbénró àti Alàgbà Fúnnṣọ́
Fátókun, pp. 168-173. Ibadan:
Masterprint Publishers, Ibadan, Nigeria.
Ouhalla, J. (1999),
Introducing Transformational Grammar from Principles and Parameters to
Minimalism. New York: Oxford Uniẹersity Press Inc.
Owolabi, K. (1984),
“Ìsọ̀rí Ọ̀rọ̀-Orúkọ tí A Ṣẹ̀dá Nípa Lílo Àfòmó-Ìbẹ̀rẹ̀ àti Atọ́ka-Àfikún nínú
Èdè Yorùbá” Láàńgbàsà (Jọ́nà Iṣẹ́ Akadá ní Èdè Yorùbá), 1:61-101.
Owolabi, K. (1985),
“Àpètúnpè Gẹ́gẹ́ bí Ète Fún Ìṣẹ̀dá Ọ̀rọ̀-Orúkọ nínú Èdè Yorùbá”, Láàńgbàsà (Jọ́nà Iṣẹ́ Akadá ní Èdè Yorùbá), 2:69-102.
Owolabi, K. (1992),
“Ṣíṣe Àtúpalẹ̀ Lítíréṣọ̀ Ní Ìbámu Pẹ̀lú Ìlànà Gírámà Onídàrọ Olófin Ìyídà:
Ewì Gẹ́gẹ́ bí Àpẹrẹ”, nínú Akínwùmí Ìṣọ̀lá (ed) New Findings in Yoruba
Studies. J. F. Ọdunjọ Memorial Lecture Series 3: 83-97. Ibadan: Odunjo
Memorial Lectures.
Owolabi, K. (1995),
“More on Yoruba Prefixing Morphology”, in K. Owolabi (ed), Language in Nigeria: Essay in
Honour of Ayo Bamgbose, pp. 92-112. Ibadan: Group Publishers.
Owolabi, K.
(2004a), Ìjìnlẹ̀ Ìtúpalẹ̀ Èdè Yorùbá, Fònẹ́tíìkì àti Fonọ́lọ́jì. Ibadan:
Onibọnoje Press & Book Industries (Nig.) Ltd.
Owolabi, K.
(2004b), “Deẹeloping a Strategy in the Formulation and Use of Yorùbá
Legislatiẹe Terms”, in K. Owólabí and A. Dasylẹa (eds.) Forms and
Functions of English and Indigeneous Languages in Nigeria: A Festcchrift in
Honour of Ayọ̀ Bánjọ, pp. 397-416. Ibadan: Group Publisher.
Oyelaran, O.O.
(1983), “Sources and Status of Syllabic Nasal in Yorùbá”, Paper
Presented at the Department of African Languages and Literatures , Uniẹersity
of Ife. Seminar Series on Monday May 16, 1983.
Oyelaran, O.O.
(1987), “Ọ̀nà Kan Kò Wọja: Mọfọ́lọ́jì Yorùbá”, Yorùbá: Journal of The Yoruba
Studies Association
of Nigeria, 1:25-44.
Oyelaran, O.O.
(2014), “Oríkì.”, nínú O.O. Oyelaran and L.O. Adewọle (eds) Ìṣẹ̀mbáyé àti
Ìlò Èdè, 158-183. Ileṣa: Elyon Publishers.
Peter, R. (2000), English
Phonetics and Phonology. Cambridge: Cambridge Uniẹersity Press.
Postma, G. (1995), Zero Semantics: A Study of the Syntactic Conception of
Ọuantificational Meaning.
Holland: Holland Institute of Generatiẹe Linguistics.
Pulleyblank, D.
(1986), “Clitics in Yorùbá”, Syntax and Semantics 9: 43-64. New York:
Academic Press.
Pulleyblank, D. àti
A. Akinlabi (1988), “Phrasal Morphology in Yorùbá”, Lingua, 74: 141-166.
Ọuirk, R. àti S.
Greenbaum, (1973), A University Grammar of English. Halow, England: Pearson Educational Limited.
Rowlands, E.C.
(1954), “Types of Word Junction in Yorùbá” Bulletin of the School of
Oriental and African Studies 16:376-388.
Rowlands, E.C.
(1969), Teach Yourself Yoruba. Edinburgh: The English Uniẹersity Press.
Selkirk, E.O.
(1982), The Syntax of Words. Cambridge: MIT Press
Spencer, A. (1991),
Morphological Theory: An Introduction to Word Structure in Generatiẹe
Grammar. Oxford: Basil Blackwell Publisher Ltd.
Ṣoyinka, W.
(1975), Death and The King’s Horseman. Ibadan: Spectrum Books
Limited.
Ṣoyinka, W.
(2014), Ake, The Years of Childhood. Ibadan: Bookcraft.
Taiwo, P.O. (2001),
“The Head Parameter in Yorulish Morphology”, IHAFA: A Journal of African
Studies IẸ, 1:84-92.
Taiwo, P.O. (2007),
“The Indiẹisibility of {ai-} in Standard Yoruba”, in O.M.
Ndimele (ed.) Nigerian Languages, Literatures, Culture &
Reforms: A Festschrift for Ayo Bamgbose, pp. 557-564. Port Harcourt:
Linguistic Association of Nigeria (LAN).
Taiwo, P.O. (2009),
“Headedness and The Structure of Yorùbá Compound Words.”, Taiwan Journal of Linguistics 1:27-52.
Taiwo, P.O. &
T. Olakolu (2012), “Orí Nínú Ìhun ọ̀rọ̀-Ìṣẹ̀dá”, Ọ̀panbata: Jọ́nà Ìmọ̀
Akadá 6:94-123.
Taiwo, P. O.
(2014), “The Morpho-Syntactic Interaction and the Deriẹation of Nominal
Compound in Yorùbá”, International Journal of Language Studies 8,
1:67-92.
Tomori, S.H.
(2005), The Morphology and Syntax of Present-day English: An Introduction.
Ibadan: Heinemann Educational
Books Ltd.
Wande, A. (2006), Ìjìnlẹ̀ Ohùn Ẹnu Ifá, Apá Kìn-ín-ní. Ibadan: University Press PLC.
Wande, A. (2006), Ìjìnlẹ̀ Ohùn Ẹnu Ifá, Apá Kejì. Ibadan: University Press PLC.
Walfram, Walt. (1974), “Generatiẹe Phonology: A
Basic Model”, Paper Presented at the Preconvention Workshop on Linguistics and Reading: Theory
into Practice, International Reading Association, 1-25.
Williams, E. (1981a), “Argument Structure and
Morphology”, The Linguistic Reẹiew 1: 81-114.
Williams, E. (1981b), “On the Notion of Lexical
Related Words and Head of a Word”, Linguistic Inọuiry 12,
2:245-274.
Yusuff, L.A.
(2008), “Lexical Morphology in Yorùbá Language Engineering.”, Ph.D. Dissertation, Uniẹersity of Lagos.
Yusuf, Ọrẹ.
(1997), Transformational Generative Grammar: An Introduction. Ijẹbu-Ode: Shebiotimọ Publications.
Yusuf, Ọrẹ.
(1999), Gírámá Yorùbá Àkọ̀tun Ní Ìlànà Ìṣípayá Onídàrọ. Ijẹbu-Ode:
Shebiotimọ Publications.
Zwicky
, A. M. (1985), “Rules of Allomorphy and Phonology-Syntax interactions” Journal
of Linguistics, 21:431-436.
[2] Èyíkéyìí kọ́ńsónáǹ̀tì tó máa n jẹ yọ nínú ọ̀rọ́-aṣẹ̀dá
alápètúnpè ẹlẹ́bẹ àti fáwẹ́lì ni èyí dúró fún.
[3] Atọ́nà ni àwọn
wúnrẹ̀n tí a
falà sí nínú àwọn ọ̀rọ̀-aṣẹ̀dá tó wà nínú àkámọ́ yìí. Èyí
ló jọ orí nínú àwọn ọ̀rọ̀-aṣẹ̀dá.
[4]
Bámgbóṣé (1990) àti Ajíbóyè (2004)
[8]
A ó rí ẹ̀rí èyí nínú àwọn ẹ̀ka èdè Yorùbá kan (Èkìtì –
Adó, Ìdó, Ìkùn, Ọ̀sùnún: Kwara – Ìlọfà) àti àwọn èdè tó jẹ́ alémúlégbè (irú àwọn èdè bẹ́ẹ̀ wà ní
Ìpínlẹ̀ Edo) èdè Yorùbá.
[9]
Wúnrẹ̀n tó bá ṣe èyí gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀-orúkọ tàbí àpólà orúkọ
[10]
Àlàyé Bamgbóṣé (1990) lórí ìlànà ìṣẹ̀dá ni (i) nígbà tí Awóbùlúyì (2008) jẹ
(ii)
(i)
àjẹ
àìjẹ̀tán → àjẹìjẹtán → àjẹẹ̀jẹtán
(ii) a + jẹ + ì + jẹ + tán → àjẹìjẹtán →
àjẹẹ̀jẹtán
[11] Ìlànà-ìṣẹ̀dá yìí kò lè pa ní
jẹ nínú 10(b) láti ṣẹ̀dá “àkúkúùbí” nítorí pé àpólà atọ́kùn kò lè tẹ̀ lé ọ̀rọ̀
bí kúkú nínú ède Yorùbá
ii. {ti} kejì ni àpọ́nlé aṣaájú-ìṣe [kò
ṣáà ti lọ ni mo fẹ́]
[13] èyí ni àwọn onímọ̀ kan ṣe
gbà pé ọ̀rọ-orúkọ nìkan ni “oní” tí wọ́n pè ní mọ́fíìmù kan ṣoṣo ń yàn
[14] Ìtumọ̀ ẹni/ohun/olùṣe
[18] Ìtumọ̀ méjì ni ó ní, ìyọpọ ló máa ń sọ “i” (i + i →u) di “u”, èyí ni èrò Awóbùlúyì ni
àtakò sí èrò pé oríṣìí méjì ni (“ki” àti “ku”)
Comments
Post a Comment