IBÁ-ISELE ATẸRẸRẸ ÈDÈ YORÙBÁ
IBÁ-ISELE ATẸRẸRẸ ÈDÈ YORÙBÁ Credit: Prof L. O. Adewole Yoruba for academic purpose 1. ÌFÁ Á RÀ (1) Imperfective tí a lè pín sí habitual àti continuous tí a tún lè tún continuous yìí pín sí non-progressive àti progressive (2) Imperfective tí a lè pín si habitual àti progressive nìkan. 2.1 IBÁ ATẸ́RẸRẸ Lójú Freed (1979: 14) àti Dahl (1985: 91), ọ̀nà tí ibá atẹ́rẹrẹ máa ń gbé ìṣẹ̀lẹ̀ jáde kì í ṣe ọ̀nà ti pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà gba àkókò nìkan (durative and continuous) bí kò ṣe pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà ń lọ lọ́wọ́ (ongoing). Tí a bá fi ojú àbùdá tí àwọn méjì yìí ṣe àkíyèsí nípa ibá yìí wò ó, a lè sọ pé ọ̀rọ̀ gírámà ti ó ń ṣe irú iṣẹ́ yìí ní èdè Yorùbá ni n. Ọ̀rọ̀ yìí ní àdàpè máa tí a máa ń lò dípò rẹ̀ lẹ́yìn ọ̀rọ̀ tí ó ń fi múùdù han (modal verbs) àti nínú gbólóhùn àṣẹ (imperative constructions). Àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ méjèèjì yìí nínú gb...