ÀLÀYÉ RÁŃPẸ́ LÓRÍ IṢẸ́ Ọ̀JỌ̀GBỌ́N SALAWU S. A (2002) TÍ WỌ́N PÈ NÍ : The Morphological source of ÀÌ- as a Negation nominalization form in Yoruba: A dialectological analysis.


  ÌFÁÀRÀ

Ohun tí a fẹ́ ṣe nínú iṣẹ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n S. A Salawu tí wọ́n pè ní _The Morphological source of ÀÌ- as a Negation nominalization form in Yoruba: A dialectological analysis._ni ọdún 2002 ni ṣíṣe àlàyé iṣẹ́ ni ṣókí pẹ̀lú èdè Yorùbá. 


👉 Àwọn ohùn tí ó ṣe kókó jù lọ nípa iṣẹ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n náà nìwọ̀nyí:👇

1. Ète iṣẹ́ akadá náà

2. Tíọ̀rì Gírámà tí Ọ̀jọ̀gbọ́n náà mú lò.

3. Ìgbésẹ̀ Mofoloji lédè Yorùbá

4. Mọ́fíìmù {àì-}

5. Ìwòye àwọn onímọ̀ gírámà èdè Yorùbá àtijọ́ lórí Mọ́fíìmù {àì-}

6. Ìwòye O. Awobuluyi (1978) lórí Mọ́fíìmù {àì-}.

7. Ìwòye S. Adewole (1992) lórí Mọ́fíìmù {àì-}

8. Ìwòye O. Solomon (1983) lórí Mọ́fíìmù {àì-}

8. Fífi ojú ẹ̀ka-èdè wo Mọ́fíìmù {àì-}


Àwọn kókó wọ̀nyí ni a ó fi ṣe àlàyé iṣẹ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n náà.


 Ní ìsonísókí

👉 Àwọn onímọ̀ àtijó bí Bámgbóṣé, Olowookere gbà pé mọ́fíìmù kàn ṣoṣo ni {àì-}.

Awobuluyi (1978) gbà pé mọ́fíìmù ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni {àì-} {à-, ì-} ní. Ṣùgbọ́n {ì-} ló ń ṣiṣẹ́ Ìyísódì. Bí àpẹẹrẹ : àlọ = àìlọ(Neg) 

Adewole(1992) gbà pé mọ́fíìmù ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àì- {à-, ì-} ní. Ṣùgbọ́n {à-} ló ń ṣiṣẹ́ Ìyísódì. Bí àpẹẹrẹ : ìlọ́nilọ́wọ́gbà =àìlọ́nilọ́wọ́gbà (Neg) .

Solomon(1983) gbà pé mọ́fíìmù ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àì- {à-, ì-} ní. Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá lo méjéèjì pọ̀, ní wọ́n tó ń ṣiṣẹ́ Ìyísódì. Bí àpẹẹrẹ : àlọ = ìlọ̀ =àìlọ́ (Neg) 

👉 Ní ti ìfojú-ẹ̀ka-ede-wò, Ọ̀jọ̀gbọ́n Salawu jẹ́ kí ó yé wa pé mọ́fíìmù kàn tí ò ṣeé pín ni {àì-}. Nítorí pé a rí àrì-nínú ẹ̀ka-èdè Èkìtì. Nínú àpẹẹrẹ bíi àrìjẹ, àrìmu tí ó ṣe kòńgẹ́ pẹ̀lú àìjẹ, àìmu. Pẹ̀lú èyí, a jẹ́ pé ìpàrójẹ /r/ ni ó wáyé tí àrì fi di àì nínú Yorùbá àjùmọ̀lò.




             

Comments

Popular posts from this blog

YORÙBÁ LITERATURE E-LIBRARY

SYNTAX AND GRAMMATICAL THEORIES E-LIBRARY SECTION

YORÙBÁ GRAMMAR E-LIBRARY SECTION