WÚNRÈ̩N MO, O, Ó, A, Ẹ ÀTI WỌ́N LÉDÈ YORÙBÁ
WÚNRÈ̩N MO, O, Ó, A, Ẹ ÀTI WỌ́N LÉDÈ YORÙBÁ
Ọ̀jọ̀gbọ́n kan ní ọ̀rọ̀ gírámà
lásán ni àwọ́n ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ wọ̀nyí. Ó ní ìdí ni pé ọ̀rọ̀ gírámà ni ọ̀rọ̀
tí kò bá ní ìtumọ̀ gúnmọ́ kan à á finú rò tàbí tí a lè tọ́ka sí ju iṣẹ́ won
nínú GBOL lọ. Irú ọ̀rọ̀ béè máa ń níye wọ́n sì máa ń níṣẹ́ kan pàtó nínú
GBOL. Ó ní oríṣìí orúkọ ni àwon onímọ̀ èdè ti pe ‘emi, ìwọ, òun, abbl’. Àwon
tí wọ́n pè wón ní arópò-orúko (AR) pe ‘mo, o, ó abbl’ ní àgékù AR. Ó ní tí a bá
wò wón dáadáa, a ó rí i pé kò sí ojú abẹ̣ lára ‘mo, o, ó abbl’ àfi bóya ‘wọ́n’
nìkan tí a lè sọ pé ara ‘àwọn’ ló ti wá. Àwọn mììràn pe ‘èmi. Ìwọ, abbl’ ní
àdálò arọ́pò-orúkọ (independent pronoun) yàtọ̀ sí àwon aládaradé (dependent
pronoun) bíi ‘mo, o abbl’, bóya nítori pé ènìyàn kò lè fi àwon wònyí dáhùn
ìbéèrè bí i ‘ta ni yẹn?’ kí èniyàn wí pé ‘*mo’ béè ènìyàn lè dáhùn pé ‘èmi,
ìwọ, abbl’.
Ìwé Ìtó̩kasí
Oyèláràn .O(1982) Ò̩nà Kan Ò Wo̩jà :Mó̩fó̩ló̩jì. OAU Press, Ile-Ife
Comments
Post a Comment