Ìjẹyọpọ̀ Arọ́pò-orúkọ àti Àsìkò Ọjọ́ Iwajú nínú Ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ (The Co-occurrence of Pronouns and Future Tense Marker in Ifẹ̀ Dialect)
Ìjẹyọpọ̀ Arọ́pò-orúkọ àti Àsìkò Ọjọ́ Iwajú nínú Ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ (The Co-occurrence of Pronouns and Future Tense Marker in Ifẹ̀ Dialect)
Credit: Prof L. O. Adewole
Yoruba for academic purpose
Nínú olórí-ẹ̀ka èdè Yorùbá ‘á’
kan wà tí wọ́n máa ń sọ pé ó ń tọ́ka àsìkò ọjọ́ iwájú. Ẹ̀dà méjì ni
ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ ní fún atọ́ka yìí. Lẹ́yìn arọ́pò-orúkọ ẹni kìíní àti ẹni kejì
ẹyọ àti ẹni kejì ọ̀pọ̀, ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ máa ń lo ‘a’. Fún àwọn yòókù,
ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ máa ń lo ‘á’. Olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá tún ń
lo ‘yóò/óò/ó’. Àwọn ẹ̀ka-èdè méjèèjì ni ó ń lo ‘máa’ fún àsi ọjọ́ iwájú.
Ẹ wo àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí:
Ifẹ̀ Olórí
ẹ̀ka-èdè Yorùbá
Mà a lọ/Mọ máa lọ (Mà á lọ/N ó lọ/Mo
máa lọ) ‘I will go’
Mà a jó/Mo máa jó (Mà á jó/Mo máa jó/N ó
jòó) ‘I will dance’
Wọ̀ a lọ/ Ọ̀ a lọ/Ọ máa lọ (Wọ̀ á lọ/O ó lọ/O máa lọ)
‘You will go’
Wọ̀ a jó/O máa jó (Wọ̀ á jó/O ó jòó/O
máa jó) ‘You will dance’
Á á lọ/Ọ́ máa lọ (Á á lọ/Ó máa
lọ/Yóò lọ) ‘He/she will go’
Á á jó/Ó máa jó (Á á jó/Ó máa
jó/Yóò jòó) ‘He will dance’
À á lọ/A máa lọ (À á lọ/ A
máa lọ/A óò lọ/A ó lọ) ‘We will go’
À á jó/ A máa jó (À
á jòó/A máa jó/A óò jòó/A ó jòó) ‘We will dance’
Ẹ̀ a lọ/Ẹ máa lọ (Ẹ̀ ẹ́ lọ/Ẹ
máa lọ/Ẹ óò lọ/Ẹ ó lọ) ‘You (pl.) will go’
Ẹ̀ a jó/Ẹ máa jó (Ẹ̀ óò jòó/Ẹ
máa jó/Ẹ ó jòó/Ẹ óò jòó) ‘You (pl.) will dance’
Ighán á lọ/Ighán máa lọ (Wọ́n
máa jó/Wọ́n á lọ/Wọn yóò lọ/ Wọn óò lọ/Wọ́n á lọ/Wọ́n ó lọ) ‘They will
go’
Ighán á jó/Ighán máa jó (Wọ́n máa jó/Wọ́n á jó/Wọn yóò jòó/ Wọn óò jòó/Wọ́n á jó/Wọ́n ó jòó) ‘They will dance’
Comments
Post a Comment