Fónẹ́tíìkì àti Fonọ́lọ́jì Yorùbá

 

Fónẹ́tíìkì àti Fonọ́lọ́jì Yorùbá

O.O. Oyelaran[1]

Credit: Prof L. O. Adewole
Yoruba for academic purpose



Ìró
Ìró yàtọ̀ sí lẹ́tà.
Ìró ni ègé ọ̀rọ̀ tí a kò lè tún fọ́ sí wẹ́wẹ́ mọ́, tí ègé kọ̀ọ̀kan kò sì ní ìtumọ̀ à á fi inú rò tàbí tí à á tọ́ka sí. Lẹ́tà jẹ́ ẹyọ àmì tí a máa ṣábà í lò láti kọ ọ̀rọ̀ sílẹ̀ fún tawo tọ̀gbẹ̀rì kà. Ìgbà mìíràn, lẹ́tà nínú àkọsílẹ̀ lè jẹ́ àmì ìrọ́ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Èyí kò wọ́pọ̀ nínú àkọsílẹ̀ Yorùbá. Ẹ wo Gẹ̀ésì:
                        A nínú  bat, gate, call
Lẹ́tà sì lè máà rí ìró kan tọ́ka sí, bí ó ṣe wà nínú àkọsílẹ̀ àtijọ́ fún Yorùbá.
ẹi nínú ẹiyẹ; n nínú ẹnyin; g nínú ng
Ìró kọ̀ọ̀kan ni ó ní bí a ṣe ń ṣe ẹnu pè é. Òmíràn jọ ara wọn, tí àwọn mìíràn sì jìnà sí ara gédégédé. Ní kókó sá, a lè fi bí a ṣe ń ṣe ẹnu pe àwọn ìró Yorùbá, kí á fi pín wọn sí ọ̀nà méjì.: A ó pe ìsọ̀rí kìíní ní kọ́ńsónáǹtì, èkejì ní fáwẹ̀lì.
Kóńsónáǹtì: Kóńsónáǹtì ni gbogbo ìró tí ó jẹ́ pé nígbà tí a bá ń pè wọ́n, ìdíwọ́ a máa wà fún afẹ́fẹ́ tí ó lọ sínú, tàbí tí ó bá ń ti ẹ̀dọ̀ fóló jade. Nítorí ìdí èyí ni ó fi jẹ́ pé tí a bá fẹ́ẹ́ ṣe àpèjúwe kọ́ńsónáǹtì dáadáa, ó di dandan kí a mẹ́nu ba ibi tí ìdíwọ́ afẹ́fẹ́ yẹn ti ṣe pàtàkì jù, irú ìdíwọ́ yẹn gan-an (yálà a kuku sé afẹ́fẹ́ mọ́ inú ni o, tàbí bámííràn), àti irú àrà tí a ń fi tán-ánná ọ̀fun dá lásìkò náà.
Fáwẹ̀lì: Gbogbo ìró tí a fọ̀, tí kò sí ìdíwọ́ olóòkan fún afẹ́fẹ́ ni a ń pè ní fáwẹ̀lì. Èdè tí tán-ánná òfun kìí dún bí a bá ń pe fáwẹ̀lì rẹ̀ sì ṣọ̀wọ́n gidigidi. Àkíyèsí mẹ́rin ni ó wúlò fún ṣíṣe àpèjúwe fáwẹ̀lì Yorùbá. Àwọn náà ni: (i) gíga ahọ́n sí àjà ẹnu (ii) àyè (iwá/ẹ̀yìn) tí gíga yẹn wà (iii) dídún (ti tán-ánná ọ̀fun) (iv) ìránmú
Ẹ̀ya Ara tí Ènìyàn ń Lò  fún Ọ̀rọ̀ Sísọ[2]: Ihò imú, ètè, eyín èrìgì, àjà ẹnu, èdídí, ahọ́n, kele, òlélé, gògóńgò, tán-ánná, kòmóòkun, ọ̀nà ọ̀fun. Yàtọ̀ sí àwọn wọ̀nyí, ẹ̀dọ̀ fóló àti ẹfọ́nhà tún ṣe pàtàkì fún ọ̀rọ̀ sísọ, nítorí àwọn ni wọ́n máa ń gba afẹ́fẹ́ tí a ń lò fún ohùn.
Fóníìmù:A lè pe fóníìmù ní ìró tí ó jẹ́ pé ọ̀wọ́ ìyàtọ̀ tí ó wà láàrin ìró tí ó bá ba mu àti ìró yòówù-ó-jẹ́ nínú èdè kan náà ni a rí tọ́ka sí bí ohun tí ó yà àwọ́n ọ̀rọ̀ méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ sọ́tọ̀ fún àwọn elédè. Kò sì gbọdọ̀ jẹ́ pé ipò tí ìró náà wà nínú ọ̀rọ̀ (tàbí nínú gbólóhùn) tàbí ìró mìíràn nítòsí rẹ̀ ni ó fa ìyàtọ̀ tí a ń perí yìí. Àp̣ẹẹ̀rẹ;
            A                     B
            tà                     dà
            gbà                  gbá
            dà                    dá
            rí                      rì

Ìyàtọ̀ bíńtín tí ó wà láàrin (A) àti (B) ni Yorùbá fi í mọ ọ̀kan sí èkejì. Nítórí náà àwọn ọ̀rọ̀ báyìí yóò fi hàn wá pé fóníímù ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni /t, d, à, á, l, r/ ní èdè Yorùbá. Ṣùgbón o, ẹ ó ṣàkíyèsí pé ‘mo ń lọ’ yàtọ̀ sí ‘ mo ḿ bọ̀’ ní etí. Síbẹ̀ ‘ń’ kò ní ìtùmọ̀ kan yàtọ̀ sí ‘ḿ’ nínú gbólóhùn kejì. ‘l’ àti ‘b’ inú gbólóhùn yìí ni ó fa ìyàtọ̀. Nítorí ìdí èyí, àdàpè (allophone) fóníìmù kan náà ni a ó pe [n,  m].

Sílébù: Sílébù Yorùbá pín sí oríṣi méjì tàbí mẹ́ta: (i) ògédé fáwẹ̀lì bí àpẹẹrẹ [é] (ii) àkànpò kóńsónáǹtì kan àti fáwẹ̀lì kan bí àpẹẹrẹ [dé] (iii) ìró tí kò ju àránmúpè àti dídún lọ bí àpẹẹrẹ [ń].

Hámónì Fáwẹ̀lì: Tí a bá wo irú ìró tí a máa ń sábà    bá nínú ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan nínú èdè Yorùbá, pàápàá jù lọ, àwọn ọ̀rọ̀ tí a lè pè ní ti ìṣẹ̀ǹbáyé, tí a kò lè sọ pé a ṣẹ̀dá, ó lójú fáwẹ̀lì tíí bá ara wọn kẹ́gbẹ́ Ọ̀rọ̀ náà wá dàbí ‘ìwá jọ̀wà tíí jẹ́ ọ̀rẹ́ jọ̀rẹ́’. Ìlànà tí ó de gbogbo ọ̀rọ̀ Yorùbá ni pé a kìí bá fáwẹ̀lì ẹ̀bákè àti ti ẹ̀bádò nínú ọ̀rọ̀ kan náà. ‘Ejò, ẹ̀rọ̀ àti ọ̀rẹ́’ wà ṣùgbọ́n kò sí ‘*òjọ́, *ẹ̀ré àti *ètó’. Bẹ́ẹ̀ sì ni fáwèlì odò, ‘a’, kìí wà nínú ọ̀rọ̀, pàápàá ju lọ, àwọn ọ̀rọ̀ oní-ìró mẹ́ta, kí fáwẹ̀lì ẹ̀báké ṣáájú rẹ̀. Ìdí nì yí tí àwọn ọ̀rọ̀ bíi ‘aró, àgbo àti ajé’ fi wà ṣùgbọ́n kò dájú pé a ní àwọn ọ̀rọ̀ bíi ‘*era àti *oda’ nínú èdè Yorùbá. Irú ìbákẹ́gbẹ́ báyìí láàrin àwọn fáwẹ̀lì èdè, tí ó jẹ́ wí pé àwọn àmi kan níláti wà tí ó pa wọ́n pọ̀ ni a ń pè ní hámónì, bí ó ti wà fún àwọn olórin (bíi olólele) tí ó jẹ́ pé ó lójú ohùn tí a lè kàn pọ̀ tí orin náà yóò fi dùn mọ̀ràn-ìn.

Ìró Pápajẹ: (i) Dídún:  Bí a bá pa fáwẹ̀lì kan jẹ níbi tí méjì ti kan ara wọn tẹ́lẹ̀, bí ọ̀kan nínú wọn bá jẹ́ ti òkè, òun ni yóò kù; àkàṣe bí ọ̀kan kan kìí báá ṣe ti òkè, tí ọ̀kan jẹ́ ti ìsàlẹ̀, ti ìsàlẹ̀ yẹn ni yóò kù. (ii) Ẹnu kò tíì kò lórí ìlànà tí Yorùbá ń tẹ̀lé fún pípa ìró jẹ bí ọ̀rọ̀ méjì bá kan ara tí fáwẹ̀lì méjì sì kángún sí ara. Lójú tèmi sá o, ó dàbí ẹni pé ọ̀pọ̀ àkànpọ̀ ọ̀rọ̀ ṣúa (ọ̀rọ̀-ìṣè àti ọ̀rò-orúkọ) ló tọ́ka sí ìlànà bí a bá ṣe fẹ́ẹ́ lo àkànpọ̀ kan nínú gbólóhùn níí sọ fáwẹ̀lì tí yóò kù.

           



[1] This is a modified version of Oyelaran, O.O. (1976), ‘Ìwé ìléwọ́ lórí Fonẹ́tíìkì àti Fonọ́lójì Yorùbá’, A Paper Presented at Ẹgbẹ́ Onímọ̀-Èdè-Yorùbá: Ìdánilẹ̣́ọ́ fún Àwọn Túlẹ̀ Oníwèé Méjìlá, University of Lagos, 16-21 August, 1976
[2] Àwòrán ni Oyelaran fi ṣe àlàyé níbí. Ó tún ya àtẹ̣ńsónáǹtì àti fáwẹ̀lì tí àwa kò yà sí ibí.

Comments

Popular posts from this blog

YORÙBÁ LITERATURE E-LIBRARY

SYNTAX AND GRAMMATICAL THEORIES E-LIBRARY SECTION

YORÙBÁ GRAMMAR E-LIBRARY SECTION