Àsìkò Afànámónìí àti Ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ Bárakú nínú Ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú àti Olórí Ẹ̀ka-èdè Yorùbá
Àsìkò Afànámónìí àti Ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ Bárakú nínú Ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú àti Olórí Ẹ̀ka-èdè Yorùbá
Máa ḿ[1] ni ó ń
fi ibá-ìs.ẹ̀lẹ̀ bárakú hàn tí ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ yìí bá bá àsìkò afànámónìí jẹ yọ nínú ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú. Àwọn
ẹ̀dà máa ḿ yìí ni a máa àti ḿ. Mọ́fíìmù òfo náà ni ó sì ń fi
àsìkò afànámónìí hàn. Àwọn gbólóhùn tí a lè fi ṣe àpẹẹrẹ ni Títí máa ḿ lọ, Títí a máa lọ àti Títí ḿ lọ.
Ní ibi tí
ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú ti ń lo mọ́fíìmù òfo fún atọ́ka àsìkò afànámónìí tí ó sì ń lo
máa ḿ àti àwọn ẹ̀dà rẹ, a má àti ḿ gẹ́gẹ́ bí atọ́ka
fún ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ bárakú, máa ń àti àwọn ẹ̀dà rẹ̀, a máa àti ń
ni olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá ń lò gẹ́gẹ́ bí atọ́ka fún ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ bárakú. Ní ti àsìkò
afànámónìí, mọ́fíìmù òfo tí ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú ń lò náà ni olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá ń lò. Àwọn gbólóhùn
tí a fi ṣe àpẹẹrẹ ní Títí máa ń lọ, Títí a máa lọ àti Títí ń lọ[2]
Nínú gbólóhùn àyísódì
tí ó ní ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ bárakú àti àsìkò afànámónìí nínú, kì ni atọ́ka ìyísódì
nígbà tí ì jẹ́ atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ bárakú tí mọ́fíìmù òfo sì jẹ́ atọ́ka
àsìkò afànámónìí nínú ẹ̀ka-èdè
Ìjẹ̀bú. Àpẹẹrẹ gbólóhùn irú èyí ni Títí kì í lọ.
Bákan náà ni
ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú àti olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá ṣe ń yí ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ bárakú àti àsìkò
afànámónìí sódì. Wọ́n ń lo kì gẹ́gẹ́ bí atọ́ka ìyísódì wọ́n sì ń lo mọ́fíìmù
òfo gẹ́gẹ́ bí atọ́ka àsìkò afànámónìí àti í gẹ́gẹ́ bí
atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ bárakú. Gbólóhùn tí ó fi èyí hàn ní
olórí-ẹ̀ka-èdè Yorùbá ni Títí kì í lọ.
[1] Kujore,
O.I. ni ó kọ bébà yìí.
Comments
Post a Comment