Àgbéyèwo èrò Samuel Àjàyí Crowther lórí ọ̀rọ̀-Orúkọ lédè Yorùbá


Ta ni Rev Samuel Ajayi Crowther? 

Ọmọ bíbí ìlú Oṣoogun ní ìpínlè Ọ̀yọ́ ni Crowther. A bí Crowther ni ọdún 1809,Crowther sì di olóògbé ni ọdún 1891. Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ilẹ̀ Yorùbá tí àwọn Òyìnbó aláwọ̀ funfun kó lẹ́rú lásìkò òwò ẹrú ni Crowther. Onímọ̀ èdè Yorùbá ni Crowther. Ajayi Crowther ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ gbìyànjú láti kọ èdè Yorùbá sílẹ̀ ní ọdún 1843. Crowther ṣe àkọsílẹ̀ ìwé Lúùkù 1:36 ní èdè Yorùbá, ó sì kọ ọ́ ní ọdún náà báyìí: ohung ohwor tí aobih ní inoh reh li aomakpe li ọmọh Ọlọrung; èyí tí àkọtọ́ òde-òní gbé e kalẹ báyìí : ohun ọ̀wọ̀ tí a ó bí ní inú rẹ ni a ó máa pè ní ọmọ Ọlọ́run. 

Crowther ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ lórí èdè Yorùbá ṣùgbọ́n èyí tí a ó gbé yẹ̀ wò báyìí ni èrò rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀-Orúkọ lédè Yorùbá. Àgbéyèwo tí a ó ṣe lórí èrò rẹ̀ ni pé, ṣé èrò rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀-Orúkọ lédè Yorùbá tọ̀nà? Bí kò bá sì tọ̀nà, kín ni àwíjàre wá lórí àìtọ̀nà èrò rẹ̀.


Wàyí o, ẹ jẹ́ kí á bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà ni pẹrẹu. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èdè Gẹ̀ẹ́sì ni Crowther fi gbé iṣẹ́ rẹ̀ náà kalẹ̀ ní ọdún 1852 nínú ìwé tí ó pè ní Grammar of the Yoruba Language, ṣùgbọ́n èdè Yorùbá ni àwa yóò fi ṣe àlàyé tí wá.


Fún ẹ̀yín tí ẹ̀ ń bá wa bọ̀, Orúkọ mi ni Nurudeen Abass.


Ọ̀RỌ̀-ORÚKỌ NÍ ÌWÒYE CROWTHER

Ó yẹ láti jẹ́ kí á mọ̀ pé lára àwọn onímọ̀ Gírámà àtijọ́ èdè Yorùbá (Traditional Grammarian) ni Crowther nítorí pé èdè Gíríìkì, Látìn àti Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n lò gẹ́gẹ́ bí òṣùwọ̀n fún gbogbo èdè lágbàáyé,ìdí nìyí tí Crowther ṣe pe ọ̀rọ̀-Orúkọ ní Substantive nítorí pé orúkọ tí àwọn onímọ̀ Gírámà àtijọ́ ń pè ọ̀rọ̀-Orúkọ nìyẹn kì í ṣe Noun


Crowther pín ọ̀rọ̀-Orúkọ (substantive) sí méjì. Ó pe ọkàn ni Primitive (ọ̀rọ̀-Orúkọ àìsẹ̀dá), ó sì pe èkejì ni derivative(ọ̀rọ̀-Orúkọ asẹ̀dá). Lára àpẹẹrẹ tí ó fún primitive (ọ̀rọ̀-Orúkọ àìsẹ̀dá) ni 'omo', 'ina', iggi', enia. Lára àpẹẹrẹ tó fún Derivative(ọ̀rọ̀-Orúkọ asẹ̀dá) ni 'adé', 'ẹ̀bùn', pejapeja, gbẹ́nàgbẹ́nà abbl.


ÀKÍYÈSÍ WA LÓRÍ 'PRIMITIVE' : A lè jiyàn pẹ̀lú àpẹẹrẹ tí Crowther pín sí abẹ́ primitive nítorí bí a bá fi èrò Awobuluyi(2008) yẹ àwọn àpẹẹrẹ náà wò, a lè tún àwọn ọ̀rọ̀ náà pín. Nítorí pé lójú Awobuluyi, àwọn àpẹẹrẹ náà kì í ṣe mọ́fíìmù kọ̀ọ̀kan ni wọ́n.

Yàtọ̀ sí èyí èrò Crowther yìí tọ̀nà lórí pínpín ọ̀rọ̀-Orúkọ lédè Yorùbá sí aṣẹ̀dá àti àìṣẹ̀dá nítorí bí a ṣe ní àwọn ọ̀rọ̀-Orúkọ tí a ṣẹ̀dá, bẹ́ẹ̀ náà ni a ní èyí tí a kò ṣẹ̀dá.

ÀKÍYÈSÍ WA LÓRÍ 'DERIVATIVE' : Ní ti derivative substantive ( ọ̀rọ̀-Orúkọ aṣẹ̀dá), èrò Crowther tọ̀nà nítorí láti ara ọ̀rọ̀-ìṣe (verb) àti (verbal adjective) ni ati máa ń ṣẹ̀dá wọn. Ìdí ni pé púpọ̀ àwọn onímọ̀ Gírámà sẹ̀ṣẹ̀dé ni wọ́n kín èyí lẹ́yìn nínú ìwádìí wọn;bi Owolabi(1984).



ÌȘẸ̀DÁ Ọ̀RỌ̀-ORÚKỌ /ÌSỌDORÚKỌ (A)


A. Ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀-Orúkọ láti ara ọ̀rọ̀-ìṣe : Crowther wí pé ìgbésẹ̀ méjì ni a lè lò láti ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀-Orúkọ lédè Yorùbá láti ara ọ̀rọ̀-ìṣe.

1. Lílọ àfòmọ́-ìbẹ̀rẹ̀ (Prefixing)

2. Ṣíṣe àpètúnpè (Reduplication) 


Ní báyìí, a ó ṣe àlàyé àwọn ìgbésẹ̀ méjéèjì náà gẹ́gẹ́ bí Crowther ṣe ṣàlàyé, a ó sì gbé àlàyé rẹ̀ náà yẹ̀ wò.


LÍLỌ ÀFÒMỌ́-ÌBẸ̀RẸ̀

1. Ó ní a máa ń lo àfòmọ́-ìbẹ̀rẹ̀ {a-}. Bí àpẹẹrẹ:

{a- pẹja}= apẹja

{a- lágbẹ̀de} = alágbẹ̀de


ÀKÍYÈSÍ TIWA: Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a máa ń lo àfòmọ́-ìbẹ̀rẹ̀ {a-} láti ṣẹ̀dá ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀-Orúkọ lédè Yorùbá ṣùgbọ́n àpẹẹrẹ {a- lágbẹ̀de} = alágbẹ̀de tó mú wá kò tọ̀nà. Ìdí ni pé {oní-, àgbẹ̀dẹ} ni ó di alágbẹ̀dẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ ṣe sọ pàápàá Owolabi(1984) ṣùgbọ́n tí Awobuluyi ní tirẹ̀ wí pé {o-, ní, àgbẹ̀dẹ} ni. Ohun tí à ń gbìyànjú láti jẹ́ kí ó yé wa ni pé kì í {a-} ni a kàn mọ́ 'lágbẹ̀dẹ' tí ó fi di 'alágbẹ̀dẹ' bí kò ṣe {oní- / o-, ní,   àgbẹ̀dẹ} tí àrànmọ́ sì wáyé pẹ̀lú.


2. Nípa lílo àfòmọ́-ìbẹ̀rẹ̀ {àti-}: bí àpẹẹrẹ : 'àtilọ', 'àtisùn' abbl.

ÀKÍYÈSÍ TIWA: Ogunlọ́gọ́ àwọn Sẹ̀ṣẹ̀dé-Onímọ̀ Gírámà èdè Yorùbá ni wọ́n kí èrò yìí lẹ́yìn àyàfi Awobuluyi. Awobuluyi wí pé {àti-} kì í ṣe mọ́fíìmù kan ṣoṣo. Wọ́n wí pé {à-, ti} ni. Awobuluyi wí pé orísìí tí méjì ló lè jẹ yọ nínú irú àsìkò yìí. (1). ti---atọ́kùn, (2). ti---ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ aṣetán. Awobuluyi wí pé ti---atọ́kùn ni yóò gba ọ̀rọ̀-Orúkọ. Bí àpẹẹrẹ {à-, tí, àárọ̀}, wọ́n sì wí pé  ti---ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ aṣetán ni yóò gba ọ̀rọ̀-ìṣe. Bí àpẹẹrẹ {à-, ti, sùn}.


3. Lílọ àfòmọ́-ìbẹ̀rẹ̀ {e-}  àti {ẹ-}: bí àpẹẹrẹ; ' ègbè' àti 'ẹ̀sẹ̀'

ÀKÍYÈSÍ TIWA: èrò Crowther yìí tọ̀nà nítorí pé àǹkóò fáwẹ́lì ló máa ń darí ìjẹyọ wọn. Àtipé, {e-}  àti {ẹ-} jẹ́ ẹ̀dà-mọ́fíìmù kan náà.


4. Lilo àfòmọ́-ìbẹ̀rẹ̀ {i-}. Bí àpẹẹrẹ : ' ìkiri' , ' ìgbóná', 'ìlọra' abbl.

ÀKÍYÈSÍ TIWA: èrò Crowther yìí tọ̀nà ṣùgbọ́n Awobuluyi tún ṣàlàyé síwájú sí i pé, orísìírísìí ìrísí ni {ì-} lè ní nínú ìsọdorúkọ.


Ní àkótán abala yìí, àkíyèsí wa ni pé Crowther  ṣíṣẹ́ lórí lílọ àfòmọ́-ìbẹ̀rẹ̀ nípa ṣísẹ̀dá àwọn ọ̀rọ̀-Orúkọ lédè Yorùbá ṣùgbọ́n kò sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀yà-mọ́fíìmù tó jẹ́ afọmọ ìbẹ̀rẹ̀. 

ṢÍṢE ÀPÈTÚNPÈ (REDUPLICATION)


1. Ó wí pé a máa ń ṣe àpètúnpè kíkún sí àwọn ọ̀rọ̀-ìṣe. Bí àpẹẹrẹ

gbẹ́nà=  gbẹ́nàgbẹ́nà

pẹja=  pẹjapẹja


ÀKÍYÈSÍ TIWA: àwọn ọ̀rọ̀ tí Crowther pè ní ọ̀rọ̀-ìṣe yìí kì í ṣe ọ̀rọ̀-ìṣe, àpólà-ìṣe ni wọ́n.


2. Ó wí pé a lè ṣe àpètúnpè ẹlẹ́bẹ náà fún ọ̀rọ̀-ìṣe láti seda ọ̀rọ̀-Orúkọ. Bí àpẹẹrẹ :

lọ = lílọ

jẹ= jíjẹ


ÀKÍYÈSÍ TIWA: èrò rẹ̀ yìí tọ̀nà. Ṣùgbọ́n bí ó bá yá, a ó gbé èrò àwọn onímọ̀ yẹ̀ wò lẹ́kùn-ún lórí ṣíṣe àpètúnpè ẹlẹbẹ.


Lákòótán abala àpètúnpè yìí, Crowther wí pé àwọn ọ̀rọ̀ tí a bá ṣẹ̀dá nípasẹ̀ àpètúnpè lè jẹ́ ọ̀rọ̀-Orúkọ àti ọ̀rọ̀-àpèjúwe


ÀKÍYÈSÍ TIWA:èrò rẹ̀ tọ̀nà nítorí pé ìlò ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ nínú ìhun ni yó fi èyí hàn.



ÌȘẸ̀DÁ Ọ̀RỌ̀-ORÚKỌ/ÌSỌDORÚKỌ (B)


B.  Ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀-Orúkọ láti ara ọ̀rọ̀-Orúkọ gan-an.


Lẹ́yìn tí Crowther ti parí àlàyé rẹ̀ nípa pé a lè seda ọ̀rọ̀-orúkọ láti ara ọ̀rọ̀-ìṣe ní (A), Crowther tún jẹ́ kó yé wa pé a lè sedá ọ̀rọ̀-Orúkọ láti ara ọ̀rọ̀-Orúkọ náà. Ó wí pé lára ọ̀rọ̀-Orúkọ tí a sẹ̀dá lára ọ̀rọ̀-Orúkọ ni:

à- ìgbọ́= àìgbọ́

à- ìtọ́= àìtọ́


ÀKÍYÈSÍ TIWA: èrò Crowther yìí tọ̀nà pé mọ́fíìmù ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni {à-} àti  {ì-} wọn kì í ṣe ọ̀kan {àì-}, gẹ́gẹ́ bí Awobuluyi ṣe sọ. Ṣùgbọ́n àáyẹ tó wà nínú Ìṣẹ̀dá 'àígbọ́' àti 'àìtọ́' Crowther ni {à-, ì-, gbọ́} àti {à-, ì-, tọ́}.


Wàyí o, a ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìsọ̀rí- gírámà tó jẹ́ ti ọ̀rọ̀-Orúkọ gẹ́gẹ́ bí Crowther ṣe ṣàlàyé. Àwọn ìsọ̀rí- gírámà náà ni :


1. Jẹ́ńdà (Gender)

2. Iye (Number)

3. Ìlò (Case)


À sì ń tẹ́ síwájú. ẹ ṣeun fún ìfarabalẹ̀ yín.



ÀLÀYÉ ÌSÒRÍ-GÍRÁMÀ Ọ̀RỌ̀-ORÚKỌ NÍWÒYE CROWTHER


1. Jẹ́ńdà(Gender) : Bí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa jẹ́ńdà, jẹ́ńdà ní i ṣe pẹ̀lú Masculine, feminine àti neuter. Crowther wí pé jẹ́ńdà wà nínú èdè Yorùbá. Ó wí pé Yorùbá mí Masculine àti feminine. Bí àpẹẹrẹ :


akọ (Masculine)

abo(feminine)


Àkùkọ (Masculine)

Àgbébọ̀ (feminine)


ÀKÍYÈSÍ PÀTÀKÌ : èrò Crowther yìí kò tọ̀nà. Ìdí ni pé bí a bá fẹ́ fi jẹ́ńdà hàn gẹ́gẹ́ bí ìṣòrí-girama nínú èdè, mọ́fíìmù ìlò(inflectional morpheme) ni ó máa ń fi èyí hàn. Ṣùgbọ́n èdè Yorùbá kò níí mọ́fíìmù ìlò tí ó lè fi jẹ́ńdà hàn. Bí àpẹẹrẹ lédè Gẹ̀ẹ́sì:

hero---hero -ine

prince --- prince -ess.

Lákòótán abala jẹ́ńdà yìí, akọ, àkùkọ, àgbébọ̀ kì í ṣe jẹ́ńdà, ọ̀rọ̀-Orúkọ ni wọn.


2. IYE (NUMBER): ìṣòrí-girama iye ní i ṣe pẹ̀lú 'ẹyọ' àti 'ọ̀pọ̀'. Crowther náà gbà pé kò sí ètò iye nínú èdè Yorùbá. Ṣùgbọ́n ó wí pé àwọn wúnrẹ̀n kan wà tí a máa ń lò gẹ́gẹ́ bí iye. Àwọn ọ̀rọ̀ náà ni:


Ọmọdé (ẹyọ)

Màjèsín (ọ̀pọ̀)


ÀKÍYÈSÍ TIWA: ìbéèrè ni pé, ṣe bí a ṣe ń lo 'ọmọdé' àti 'Màjèsín' nínú èdè wa ni láti fi iye hàn nìyí? Bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé èrò Crowther yìí kò tọ̀nà. Ọ̀rọ̀-Orúkọ ni 'ọmọdé' àti 'majesin' lédè Yorùbá kì í ṣe Iye. 


👉Crowther tún wí pé Yorùbá a máa lo wúnrẹ̀n asònkà sẹ́yìn ọ̀rọ̀-Orúkọ láti fi iye hàn.

Bí àpẹẹrẹ:

obìnrin mẹ́fà,  ẹyin mẹ́rin, ọmọ kan.


ÀKÍYÈSÍ TIWA : èrò Crowther yìí kò tọ̀nà nítorí pé àpólà-orúkọ ni àwọn àpẹẹrẹ tí ó fún wa yìí, níbí tí a tí rí <ORÍ> àti ẹ̀yán asònkà. 


3. ÌLÒ (CASE): Bí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa case nínú èdè, case ní i ṣe pẹ̀lú NOMINATIVE, POSSESSIVE, ACCUSATIVE, GENETIVE, OBLIQUE, abbl.


Crowther wí pé ọ̀nà mẹ́ta ni a lè gbà lọ ọ̀rọ̀-Orúkọ lédè Yorùbá. (1.) Nominative, (2.) Possessive àti (3.) Objective.


👉 Nominative Case ni lílọ ọ̀rọ̀-Orúkọ ní ipò Olùwà. Bí àpẹẹrẹ :   babba 


👉 Possessive case ni lílọ ọ̀rọ̀-Orúkọ ní ipò ẹ̀yán. Ó wí pé àtọ́ka-atọ́kùn ti ni ó máa ń fi èyí hàn láàárín ọ̀rọ̀-Orúkọ méjì. Bí àpẹẹrẹ :

Illé ti babba

Ìyá ti èmi


👉 Objective case ni lílọ ọ̀rọ̀-Orúkọ ní ipò àbọ̀ nínú ìhùn. Bí àpẹẹrẹ :


William na aja

Mary ta sinkafa


ÀGBÁLỌGBÁBỌ̀

A ti gbìyànjú láti wo ohun tí Crowther pè ní ọ̀rọ̀-Orúkọ,ọ̀nà tí ó pín in sí, báwo ni a ṣe lè seda wọn àti pàápàá àwọn ìṣòrí-girama tí ó jé ti ọ̀rọ̀-Orúkọ.

Àkíyèsí kán gbòógì tí a ṣe nípa iṣẹ́ náà ni pé àkọtọ́ ayé àtijọ́ ni Crowther fi gbé iṣẹ́ rẹ̀ kalẹ̀.

Mo dánu dúró báyìí náà. Lẹ́ẹ̀kan sí i, Orúkọ mi ni Nurudeen Abass.

Ẹ ṣeun fún ìfarabalẹ̀ yín.

Comments

  1. Iṣẹ́ ńlá ni èyí. Ààyè sì wà fún ìbéèrè àti ìdáhùn

    ReplyDelete
  2. Iṣẹ́ ń là ni ẹ ṣe lórí èyí , ẹ kú ìgbìyànjú

    ReplyDelete
  3. Nínú ìmọ̀ bí èdè Yorùbá ṣe di kíkọ sílẹ̀ àkíyèsí wà pé Samuel Ajayi Crowther kọ́ ni ẹni àkọ́kọ́ tó kọ́kọ́ gbìyànjú láti kọ èdè Yorùbá sílẹ̀

    ReplyDelete
    Replies
    1. Bí ohunkóhun bá rú yín lójú nípa iṣẹ́ yìí, ẹ dara pọ̀ mọ́ wa ni orí Google classroom wa pẹ̀lú code 55fpdkf.

      Ẹ ṣeun

      Delete
  4. Ẹ kú ìgbìyànjú, Ọ̀gá mi sà.
    Iwájú, iwájú...

    ReplyDelete

Post a Comment

Popular posts from this blog

YORÙBÁ LITERATURE E-LIBRARY

SYNTAX AND GRAMMATICAL THEORIES E-LIBRARY SECTION

YORÙBÁ GRAMMAR E-LIBRARY SECTION